FG Survival Fund: Ènìyàn 174,574 ló ti forúkọ sílẹ̀ fún ètò ìrànwọ́ ìjọba fáwọ̀n olókoòwò kéékèé

Ìjọba ti kéde àwọn tó kàn láti gba owó ìrànwọ́ ìjọba MSME láti 25/09/2020 lọ
Mínísítà fún ilé iṣẹ́, káràkátà àti ìdókoòwò Mariam Katagum ní láàrín ọjọ́ méjì péré ènìyàn ẹgbẹrún lanà àádọ́sàn o lé díẹ̀ ló ti fi orúkọ sílẹ̀ fún ètò náà.
Àwọn ènìyàn wọ̀nyi fi orúkọ sílẹ̀ láì sí kọ́nukọ́họ nínú fún owó ẹgbẹ̀rún márùndílagọ́rin bílíọ̀nù náírà, owó ìràwọ ìjọba fún àwọn tó n ṣe oko-òwò ara wọn.
Owó yìí ni yóò ràn àwọn ti àjàkálẹ̀ ààrùn Coronavirus ti mú okòwò wọ́n dénu kọlẹ̀ tí wọ́n kò si lágbára láti ṣe ojúṣe wọn bótitọ́ àti bóti yẹ mọ́.
- Ẹ gbó òhun tí àwọn olùdíjé sípò gómìnà nípínlẹ̀ Ondo sọ nípa bàbá ìsàlẹ̀...
- Oluwo kọ̀ láti sọ̀rọ̀ lórí àwọn afọbajẹ tó fẹ́ yọ ọ́ nípò, aráàlú fọ́n síta láti fẹ̀hónú hàn
- APC Ekiti pàṣẹ lọ rọ́ọ́kún nílẹ̀ fún àna Tinubu àti Babafemi Ojudu
- Neo n fọ pátá Vee nílé ẹlẹ́gbọ́n àgbà BB Naija, wo ohun táwọn olólùfẹ́ ètò náà n sọ
Aago mọ́kànlá alẹ́ ọjọ́ Ajé ni ìjọba ṣi ojú òpó ìforúkọ sílẹ̀ náà ti wọ́n pe ni MSME.
Mínísítà tó ń mójú tó ọ̀rọ̀ náà Mariam Katagum ni àwọn ìpínlẹ̀ tó fi orúkọ sílẹ̀ jùlọ ni Kano, Kaduna , Lagos, Katsina ati Abuja, sùgbọ́n Kano Kaduna àti Lagos ló n léwájú.
Katagum ni, àwọn to wà ni ẹ̀ka olókoòwò tó n rí si ìlé itura àti ìgbàlejò ni yóò kan ni ìfórukọsílẹ̀ tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní òní, ọjọ́karùnlélógún oṣù kẹsán, ọdún 2020, nígbà ti yóò kan ẹ̀ka àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ àti àwọn oníṣẹ́ ètò ìrìnà.
- Daniel ń bọ̀ wá wò mí nítori mo ṣàìsàn ló dàwátì- Baba Daniel
- Akọ̀wé-owó wọ gàù ní iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé ó jí N500,000 lọ́wọ́ ọ̀gá rẹ̀
- Ìdùnnú subú layọ̀ nípìnlẹ̀ Ọyọ́, àwọn tó dé láti Lebanon sọ ọmọ wọn ní Seyi
- Wo ọ̀nà tí o fi lè dáàbò bo ọmọ rẹ lọ́wọ́ COVID-19 níléèwé
- Ẹ yé parọ́ kiri! Orílẹ̀-èdè Amẹrika kò ṣọ́ wọlé-wọ̀de mi àti ìdílé mi- Atiku fèsì

Oríṣun àwòrán, Twitter/MSME survival fund
FG Survival Fund: 'Àwọn oníṣòwò lẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ nìkan ló lè forúkọ sílẹ̀ báyìí fún ìrànwọ́ ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà'
Awọn eeyan ipinlẹ Oyo ni ipenija lati forukọ silẹ lori itakun-agbaye fun iranwọ powo ''Survival Fund'' ti ijọba apapọ gbe kalẹ.
Ọkan lara awọn alakoso eto naa ni ipinlẹ Oyo, Segun Ogunwuyi lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC Yoruba.
Ọgbẹni Ogunwuyi sọ pe awọn eeyan ti bẹrẹ si ni forukọ silẹ diẹdiẹ bayii lẹyin ipenija ti wọn ti kọkọ doju kọ.
- INEC fún Obaseki ní ìwé-ẹ̀rí moyege gẹ́gẹ́ bí gómìnà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn
- Ìjọba Katsina ní kí àwọn iléèwé wà ṣì ní títìpa nítorí arùn Coronavirus
- Lawuyi Ogunniran, àgbà ọ̀jẹ̀ òǹkọ̀wé Eégún Aláré dágbére fáyé!
- Ọ̀gá iléeṣẹ́ gbé £10 mílíọ̀nù ẹ̀bùn owó fún òṣìṣẹ́, èyí lohun tó pawọ́n pọ̀
- Ọ̀rọ̀ Soyinka àti Obasanjo papọ̀ lórí pé Buhari n ṣe ìpínyà Nàìjíríà
O ṣalaye pe awọn oniṣowo ni ẹka eto ẹkọ nikan ni o le lanfaani lati fi orukọ silẹ fun iranwọ owo naa bayii.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
'Àwọn oníṣòwò lẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ nìkan ló lè forúkọ sílẹ̀ báyìí fún ìrànwọ́ ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà'
Ọgbẹni Ogunwuyi ni nigba to ba ya ni eto naa yoo kan awọn mii ti ọwọja coronavirus ṣe ipalara fun bakan naa.
Nigba ti o n ba BBC Yoruba sọrọ, Ọgbẹni James Fanope to jẹ ọkan lara awọn alakoso eto owo iranwọ ijọba apapọ sọ pe oun ko le sọ ni pato iye awọn eeyan to ti fi orukọ silẹ ni ipinlẹ Eko.
O ni awọn ileewe ti wọn ba fi orukọ silẹ pẹlu ipinlẹ Eko nikan ni yoo jẹ anfaani iranwọ owo ọhun.
Ka ìròyìn yìí láti fi orúkọ sílẹ̀ fún owó ìrànwọ́ ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà!
Ago mẹwaa alẹ ọjọ Aje ni ijọba fi ikede sita pe oju opo yoo ṣi silẹ fun awọn eeyan ti yoola janfani owo iranwọ ijọba apapọ
Bẹẹ si ni wọ́n ti fi ilana atẹle lati ri owo naa gba sita fun gbogbo ọmọ Naijiria to ba forukọ silẹ.
Atẹjade kan jade lọ́jọ́ Aiku niluu Abuja lati ọfiisi to n boju to akanṣe eto yii pe oju opo yoo ṣi silẹ laago mẹwa alẹ.

Oríṣun àwòrán, SMES SURVIVALFUNDNG
Bakan naa, wọn ni isọri awọn ti yoo kọkọ jẹ anfani rẹ ni awọn ileewe.
Eto iranwo owo yii ti wọn pe ni MSME Survival Fund initiative jẹ akanṣe eto ti ijọba Naijiria gbe kalẹ fun awọn olokoowo kekeke to padanu ohun kan tabi omiran torii ajakalẹ arun Coronavirus.
Eyi si jẹ gẹgẹ bi owo iranwọ lasiko Covid-19. Biliọnu marunlelaadọrin ni owo naa.
Wo boo ṣe lee kopa.
Boo ṣe le forukọ silẹ fun N75 Biliọnu owo iranwọ ijọba
O kere tan, 1.7 miliọnu ọmọ Naijiria to jẹ oniṣowo ni yoo lanfani ati gba lara owo yii gẹgẹ bi iroyin ti BBC wadii.
Koo to wa tẹ oju opo iforukọsilẹ, wo ohun marun too ni lati mọ.
Lakọkọ, oju opo naa ni https://www.survivalfund.ng/
Ago mẹwa alẹ ọjọ Aje ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹsan ọdun 2020 ni oju opo yoo di ṣiṣi fun awọn eeyan lati forukọ silẹ.
Ati pe iṣọri awọn kan pere lo lee forukọ silẹ, awọn yii si bọ sabẹ iṣọri ti wọn n pe ni "Payroll support".

Oríṣun àwòrán, FG
Ki ni itumọ "payroll support"?
Isọri yii ni o wa fun awọn to ni owo ti wọn n ṣe ti ko si lee san owo oṣu awọn oṣiṣẹ wọn lati oṣu bii mẹta sẹyin.
Owo oṣu naa yoo jẹ laarin N30,000 si N50,000 owo Naijiria.
Ijọba Naijiria ti ṣetan lati ran oniṣowo ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta lọwọ jakejado Naijiria.
Wọn si ni pe fun ileeṣẹ owo kan ṣoṣo, ko ni ju oṣiṣẹ mẹwaa lọ to lee janfani owo naa.
Wo atẹ ilana bi eto naa yoo ṣe lọ
Ninu atẹ oke yii, awọn oniṣowo nikan to si wa labẹ ẹka eto ẹkọ lo le forukọ silẹ laago mẹwaa lọjọ Aje, ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹsan.
Lọjọ Ẹti ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kẹsan ọdun 2020, awọn olokoowo fun itura bii hotẹẹli, ile ọti, sinima, ile ounjẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ ni iforukọsilẹ kan lati ago mejila oru.
Ọjọ Aje ọjọ kejidinlọgbọn ni ti awọn oniṣowo mii lee lọ soju opo naa.
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí ọkùnrin tó gé akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ wẹ́lẹ́ wẹ́lẹ́ fún òògùn owó ní Ikorodu
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ afurasí ọlọ́pàá tó yìnbọn fún ọ̀dọ́kùnrin tó fún èèyàn lóyún s'átìmọ́lé
- Wo bí odò Nile tó gùn jù l'Áfíríkà, ṣe ń fójúu ilẹ̀ Egypt, Ethiopia àti Sudan han màbo
- Ọ̀wọ́ngógó búrẹ́dì gbòde kàn lẹ́yìn tí àwọn oníbúrẹ́dì da iṣẹ́ sílẹ̀
- Sudan tí bẹ̀rẹ̀ ìjìròrò lórí bí US yóò ṣe yọ òrúkọ̀ wọn kúrò nínù ikọ̀ agbẹ́sùnmọ̀mí àgbáyé
IKILỌ
Ijọba ti kilọ pe ki ẹ fara balẹ kọ gbogbo ohun to ba yẹ lasiko iforukọsilẹ.
Ki lẹ nilo lati forukọ silẹ?
Ṣaa ti mu iwe ẹri ileeṣẹ to n fun ni laṣẹ idokoowo ni Naijiria CAC lọwọ.
Boo ba ni i, ijọba tun ti ṣeleri lati ran eeyan 250,000 lọwọ fun sabuke CAC.
- Èèyàn mẹ́jọ jónà ráúráú nínú ìjàmbá ọkọ̀ akérò tó ṣẹlẹ̀ ní mọ́rosẹ̀ Eko sí Ibadan
- Ọlọ́jọ́ Festival 2020:Ọ̀ọ̀ni ti Ilé Ifẹ̀ tí wọ ìléèdí ọlọjọ méje tí kò ní rí ẹnikẹ́ni sójú
- Ìjọba Kaduna kéde ọjọ́ mẹ́ta fún ìdárò Emir Zazzau, Buhari, Tinubu, Babangida náà ń ṣèdárò
- Wo àwọn báńkì tó wà lẹ́yìn àwọn olówó èlé bí MMM
Bakan naa, oo nilo nọmba BVN rẹ.
lgba wo ni iforukọsilẹ yoo dopin?
Iforukọsilẹ fun gbogbo isọri tẹsiwaju titi di ọjọbọ ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹwaa ọdun 2020 ko to pari.
- Obaseki la Ize-Iyamu mọ́lẹ̀ wọlé ìbò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì ní ìpínlẹ̀ Edo
- Wo bí Sunday Shodipe ṣe pa Funmilayo tó pa kẹ́yìn l' Akinyele
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ elétò ìlera, ẹ padà sẹ́nu iṣẹ́- JOHESU
- Bí PDP ṣe na APC lálùbami ní Edo, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣẹlẹ̀ ní Ondo- PDP
- Wo ìdí tí ètò ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Edo ṣe lọ ní ìrọwọ́-rọsẹ̀
Fi orukọ silẹ nibi lati jẹ anfaani owo yii.

















