Ondo Election 2020: Ẹ wo àwọn olùdíje sípò gómìnà nípínlẹ̀ Ondo tó takò bàbá ìsàlẹ̀

Oludije to wa sibi itakurọsọ BBC
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Awọn oludije ninu idibo sipo gomina ni ipinlẹ Ondo ti s fun ara ilu ohun ti awọn yoo ṣe.

Idibo sipo gomina yoo waye ni ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020.

Diẹ lara ohun ti wọn sọ ni yii;

Oluwarotimi Akeredolu

Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mú ẹyẹ bọ̀ lápò ni l'Ondo - Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Alamy

Iṣẹ pọ niwaju mi ti maa ṣe siwaju nigba tara ilu ba tun dibo yan mi ni eekeji, tori mo ṣẹṣẹ n mu ẹyẹ bọ lapo ni.

Oludije fun ẹgbẹ oselu APC, tii sun ṣe gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu lo sísọ loju ọrọ yii lọjọ Isẹgun lasiko to n kopa lori akanse eto lori BBC Yoruba pẹlu awọn Oludije gomina miran nipinlẹ naa, ti akori rẹ n jẹ itakurọsọ pẹlu awọn Oludije nipinlẹ Ondo.

Gomina Rotimi Akeredolu fi ogun rẹ gbari pe eto ilera nipinlẹ Ondo ti lọ soke lati igba toun ti de ipo gomina.

Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mú ẹyẹ bọ̀ lápò ni l'Ondo - Akeredolu

O ni lasiko to n dahun ibeere lori itakurọsọ BBC Yoruba ni ko si ijọba to ti kọja lọ nipinlẹ naa, to gbe eto lárugẹ to ijọba toun.

Akeredolu tesiwaju pé "mo ti safikun awọn ilu to n jẹ anfaani eto itọju tiya-tomo taa mọ si Mother and Child ti ijọba Olusegun Mimiko fi lélẹ̀.

Mo ti ṣe afikun ilu marun miran kun ilu meji to n jẹ anfaani eto itọju tiya-tomo, ti inu ọpọ eeyan si dun sì.

"Akeredolu tun fikun pe oun ti gba ọpọlọpọ awọn dokita si ẹnu isẹ eyi to tun mu kí eto ilera nipinlẹ Ondo túbọ̀ ru gọgọ sì.

Akeredolu ni oun yoo tun dabira siwaju si nidi atunse ọna, agbega ile ẹkọ ati ipese awọn ohun eelo amayederun lorisirisi.

"Tí ẹ bá fún mi láyé lẹ́ẹ̀kan síi, máa dá bírà."

Ìlú Ondo ló ń gba owó ìná jùlọ ju àwọn ìlú míràn lọ

Gomina Rotimi Akeredolu ti sísọ loju rẹ pe owo ti ijọba oun n na silu Ondo kọja iye ti wọn n na silu miran nipinlẹ naa lọ.

Gomina Akeredolu, ẹni to kede pe ile ẹkọ fasiti to wa nilu naa n gba obitibiti owo lapo ijọba.

O fikun pe ọpọlọpọ gbese ni ijọba to kọja lọ nipinlẹ naa fi silẹ fun òun, gbogbo rẹ̀ si lawọn n gbọ bukata le lori.

Bakan naa lo ni ijọba oun ti n mu iṣẹ ṣe lati satunse awọn opopona to ti dẹnu kọlẹ nilu naa.

Owó ilé ẹ̀kọ́ Fáṣítì Ìpínlẹ̀ Ondo ló kéré jùlọ ní Nàìjíríà

Gomina Rotimi Akeredolu ti kede pe owo ile ẹkọ fasiti ipinlẹ Ondo lo kere julọ ni Naijiria.

Akeredolu, lasiko to n dahun ibeere lori boya afikun yoo wa lori owo ile ẹkọ fasiti ipinlẹ naa to wa nilu Akungba Akoko.

Akeredolu ni ijọba oun ti ṣe adinku si owo ile ẹkọ fasiti naa lẹyin ti awọn akẹkọọ fasiti naa ṣe iwadi kaakiri ẹkun ìwọ oorun Naijiria lati mọ fasiti to n sanwo ile ẹkọ to kere julọ.

Akeredolu ni awọn akẹkọọ fasiti ipinle naa to wa ni Akungba, ti fara mọ owo ile ẹkọ tuntun naa.

O wa gba wọn nimoran lati mase jẹ káwọn oloselu si wọn lọna.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Aṣa: Ọ̀rọ̀ Ẹ̀yán ni Bunmi Femi Amao ń kọ́ wa lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà lóri BBC Yoruba

Gomina Ipinlẹ Ondo ti kede pe oun ti pari gbogbo iṣẹ akanse ti oun ba nilẹ, lai pa ikankan ti..

Akeredolu, ẹni to fi ọwọ idaniloju naa sọya lori eto itakurọsọ BBC Yoruba tun ni oun yoo tesiwaju lati pari awọn isẹ ti oun n ṣe lọwọ, tara ilu ba fi dibo yan oun pada.

N kò ní jẹ òṣìṣẹ́ ni owó oṣù, tí mo bá wọlé gómìnà ní èkejì

Gomina Akeredolu ti kede pe oun ti mu ileri oun ṣẹ lati mase jẹ awọn osisẹ ni owo oṣù.Akeredolu, ni owo osu to fẹ pari yii ni ijọba oun jẹ awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa, ti oun yoo si san.Bakan naa lo fikun pe awọn oṣiṣẹ naa ti gba owo ajemonu ìsinmi lẹ́nu isẹ, ti oun ko si ni jẹ oṣiṣẹ ni owo osu rara, bi wọn ba dibo fun oun sipo gomina ni eekeji.

Akanda ẹ̀dá 35 ni mo gbà sẹnu iṣẹ́, màá sì ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ

Gomina Ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti salaye pe oun ti yan àwọn olóṣèlú sípò igbimo olùdarí Ileesẹ ìjọba dáadáa.

Bakan naa lo ni ti oun ba pada sípò, oun yoo túbọ̀ yan oloselu sẹnu isẹ si.

Nigba to tun n dahun ibeere lori itọju awọn akanda ẹda, Akeredolu ni oun kii ta awọn akanda ẹda nu rara.

"Ijọba mi lo kọ́kọ́ sedasile Igbimọ oludari fáwọn akanda ẹda, koda mo yan amugbalegbe fun ara mi nitori ọ̀rọ̀ wọn."

Gomina ipinlẹ Ondo tun salaye pe ijọba oun gba akanda ẹda marundinlogoji sẹnu isẹ, ti oun yoo si ṣe ju bẹẹ lọ fun wọn, ti oun ba pada sipo ni ẹkeji.

Agbára àwọn bàbá ìsàlẹ̀ ti ń lọ sílẹ ní Nàìjíríà, Ọlọ́run ni bàbá ìsàlẹ̀ mi

Gomina Ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti ni ilana bi oun ṣe di gomina ti safihan pe oun ko ni gbagbọ rara ninu agbara baba isalẹ.

Akeredolu, lasiko to n foju laifi wo amulo baba isalẹ to fojuhan ni Edo, tun fikun pe o foju han gbangba ninu idibo naa pe agbara awọn baba isalẹ ti n lọ silẹ ni Naijiria.

Gomina Ipinlẹ Ondo tun fọwọ sọya pe oun ko ni baba isalẹ kankan, Ọlọrun ni baba isalẹ oun.

O wa gboriyin fun àjọ eleto idibo lori isẹ takuntakun to ṣe lori eto idibo ni Edo.

Nigba to n kadi ọrọ rẹ nilẹ, Akeredolu wa rọ awọn araalu lati wo ọpọlọpọ àṣeyọrí oun ni saa akọkọ, lati dibo fun oun ni ẹkeji nitori oun yoo ṣe bẹbẹ siwaju si.

Eyitayo Jegede

Jegede

Oríṣun àwòrán, Google

Àwọn iṣẹ́ mi ko ní ní àlébù kankan

Eyitayo Jegede to jẹ oludije ipo gomina ni ipinlẹ Ondo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP fesi si idahun awọn eeyan pe iṣẹ akanṣe ti awọn fẹ dawọle yoo fun tagba tọdọ ni iṣẹ.

Jẹgẹdẹ ni ọrọ abo n kọ ẹgbẹ oun lominu torinaa "a maa kọ agọ ọlọpaa, bareke awọn sọja sawọn ilu ti wọn ti n ji eeyan gbe.

O tun ni o yẹ ki ofin ipinlẹ jọju, iṣejọba oun yoo si fi ontẹ luu nipa biba awọn lọba lọba ṣiṣẹ.

O ni ọrọ abo kii ṣe iṣẹ ọlọpaa nikan.

A ó ran àwọn àgbẹ lọ́wọ́ ní Ondo

oludije ipo gomina ni ipinlẹ Ondo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Eyitayo Jegede ni ọrọ awọn agbẹ ko ṣee fọwọ rọ sẹyin ni ipinlẹ Ondo torinaa oun yoo ṣeranwọ fun wọn.

Jegede ni agbẹ lo to ida to le ni aadọrin awọn ara Ondo nitorinaa iṣejọba oun yoo ran awọn agbẹ lọwọ lorii eso fun irugbin atawọn nkan to le ṣe moriya fun wọn.

Àkọlé fídíò, SS3 ní mo wà báyìí, mo sì ti gba àmì ẹ̀yẹ̀ púpò nílé-lóko gẹ́gẹ́ bí onílù - Ayansike

Iṣẹ́ tí kò ní àlébù la ó ṣé fún Ondo tẹ́ẹ bá fún mi láyè

Araale kan bere pe lọdun mejọ ti Eyitayo Jegede fi ṣiṣẹ gẹgẹ bi agbẹjọro agba ipinlẹ Ondo labẹ iṣejọba Olusegun Mimiko, ki ni iṣẹ apẹrẹ rere to ṣe tawọn le wo mọ ọ lara lati dibo yan an lọtẹ yii.

Eyitayo ni lootọ ni oun wa lara ikọ aṣofin Mimoko nigba naa lọhun ti iṣẹ ire awọn ko si parẹ.

O ṣalaye pe awa ko gba iṣẹ akanṣe jọ fun awọn ẹbi wa ṣugbọn a pin in ko kan taraale tara oko to tọ si ni.

Jegede ni ki wọn ranti gbogbo iranwọ ti awọn ṣe lẹka eto ẹkọ to fi rọ awọn ọmọ ileewe lọrun ti wọn ko si ri alebu kankan lara rẹ.

To fi mọ iranwọ lẹka ilera ati ọna titunṣe ni Jegede tẹnumọ to si ni bi wọn ba fun oun laye, wọn o ni ri alebu ninu iṣẹ oun gẹgẹ bii gomina.

A ó sanwó ìdánwo aṣewọlé ìwé gíga fásitì fawọn àkàndá

Oun ti Eyitayo Jegede ni iṣejọba oun yoo ṣe fun awọn akanda ẹda ni wipe ileewe awọn akanda yoo ri iranlọwọ lọdọ ijọba oun paapaa lori irinṣẹ ti wọn fi n kawe.

O tun ni ọpọ wọn lo fẹ wọ ileewe giga bii fasiti ṣugbọn ti ko si owo, "iṣejọba mi yoo ran wọn lọwọ".

Eyitayo ni awọn akanda to fẹ ṣe ere idaraya naa yoo ri iranwọ.

Àwọn ọ̀dọ́ wa yóò màa ríṣẹ́ láì san owó orí

Araale kan bere pe ki ni Eyitayo Jegede yoo ṣe nipa ọrọ aje ipinlẹ Ondo.

Eyitayo Jegede ni lootọ Covid 19 n ṣọṣẹ lagbaye lọwọ lọwọ, amọ "lagbara Ọlọrun, a o pese iṣẹ ọwọ pupọ fawọn ọdọ".

O ni awọn olokoowo kekeke, "o yẹ ki ijọba ran wọn lọwọ kawọn naa le gba eeyan siṣẹ, ki ijọba si ko awọn oniṣẹ aladani wa si Ondo lai san owo ori".

Gbogbo eyi lo ni iṣejọba oun yoo ṣe bi wọn ba dibo fun oun.

Mi ò nígbàgbọ́ nínú agbára bàbá ìsàlẹ̀

Jegede ti ni ko sohun kankan to n jẹ baba isalẹ ninu oṣelu.

O ni o yẹ ki wọn maa dibo ni alafia ni ki esi si jade bi wọn ba ṣe n ṣe idibo tan.

Jegede kasẹ ọrọ rẹ nilẹ pe "ni ti idibo to n bọ lọna yii, a o ni fi ọmọ ṣe".

Akeredolu ni ìṣẹ́ pọ̀ níwájú mi láti ṣe tí wọn bá yàn òun sípò gómìnà ní ẹkejì

Dotun Ojon

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Oludije yi sọ pe nkan ti oun maa se yatọ ti oun ba jawe olu bori ni ọrọ idaari (leadership)

O ni eto idari doju kọ ibi kan da apa kan si ni ipinlẹ Ondo. O sọ pe kii se pe ipinlẹ Ondo ko ni alumọni tabi awọn to kawe daada sugbọn eto idari ku diẹ kaato.

O ni awọn fẹ ki awọn ara ilu jẹ adojukọ gboogi awọn to n dari eto ijọba.

Nitorin naa o fẹ ki awọn eeyan ipinlẹ Ondo ni adari daada. O ni oye oun ni ipinlẹ Ondo ni lo lasiko yi lati le lọ si ibi giga yatọ si ti tẹlẹ.

'Ti o ba jẹ iriri lọba lootọ o yẹ ki ipinlẹ Ondo ti dagba ju bayi lọ'

Oludije ẹgbẹ YPP ti sọ idi ti o se yẹ ki wọn fun awọn ọdọ lanfaani lati se ijọba.

O fesi yi ni idahun si ibeere ti eeyan kan fi sọwọ si lori itakurọsọ BBC Yoruba.

O sọ pe lootọ iriri se pataki sugbọn o yẹ ki awọn ọdọ ni anfaani lati se ijọba nitori lawọn orileede to ti gun oke agba, awọn ọdọ lo n dari eto.

Nkan ti a n ja fun lori baba isale ni eto oṣelu pada wa sẹlẹ ninu eto idibo Edo

Oludije ẹgbẹ oselu YPP ti sọ pe ọgbọn ti INEC lo lati fi saseyọri ninu eto idibo Edo jẹ eleyi to bọgbọn mu.

Dotun Ajon ni iru nkan bayi ni awọn ọmọ ẹgbẹ oselu YPP ti n pariwo lọjọ to ti pẹ.

Ni idahun si ibeere lori igbagbọ ninu agbara baba isalẹ ninu oselu Naijiria o ni awọn oloseelu to saaju ni wọn ni igbagbọ ninu baba isalẹ.

Ni ti tawọn ọdọ ode oni, o sọ pe awọn paapa julọ ninu ẹgbẹ YPP awọn ko niigbagbọ ninu baba isalẹ.

O kadi ọrọ rẹ ni ikẹyin pe ki awọn ara ilu Ondo yi ọna ti wọn n tọ saaju pada ki nkan baa le yatọ ni Ondo.

Adeleye , oludje labẹ AAC

Oríṣun àwòrán, Adeleye

Adekunle Adeleye

Nínú ọrọ tirẹ, Adekunle Adeleye salaya pé gbogbo awọn iṣ ti oun ti ṣe kalẹ nilu Oyinbo, asiko ree lati ko ere rẹ.

Adeleye ni ọkan pataki lara nkan ti oun yoo ṣe ni láti mu aabo ilu ati Ounjẹ rọrun fun ara ilu, nitori ọna yii nikan ni ilu fi le tuba ko tunṣẹ

Adeleye ni o se pataki lati gbaruku ti isẹ ti eniyan ba ba nílé

O fi kun un pe eto Mother and Child ti Mimiko ti se seyin ati awọn opopona ti gomina Akeredolu n se.