Magawa: Èkúté tó sàwárí bọ́mbù ilẹ̀ gbàmi ẹ̀ye wúrà PDSA

Oríṣun àwòrán, PDSA/PA
Èkúté ńlá kan to dà bi òmìràn ti gba àmì ẹ̀yẹ wúrà fún iṣẹ́ rẹ̀ láti ma ṣe awári imọ-ilẹ
Magawa a maa ti fimu filẹ̀ lati ri imọ-ilẹ Mọ́kandinlógójì àti ti àwọn méjìdinlagbọ́n ti kò bu gbàmu mọ lọ́wọ́ ri lati igba tó ṣe iṣẹ́ to yàn láàyò yìí.
Àwọn ilé iṣẹ́ ìtójú ẹranko kan ni ilẹ gẹẹsi ti wọ́n pe ni PDSA lo fún ni àmì ẹyẹ náà nítori iṣk ribiribi tó n ṣe lati dóòlà ẹmi àwọn ènìyàn, pàápàá jùlọ láwọ́n ibùdó to ti ṣiṣẹ́ ni Cambodia.
Ìròyìn sọ pé, ó lé ni mílíọ̀nù mẹ́fà imọ-ilẹ to wà ni ìlà-oòrùn- Gúúsù àwọn orílẹ̀-èdè Asia.
- APC Ekiti pàṣẹ lọ rọ́ọ́kún nílẹ̀ fún àna Tinubu àti Babafemi Ojudu
- Ọgbọ̀n ọdún ni mo fi ṣe iṣẹ́ púlọ́mbà kí n tó dí Gomina ìpínlẹ̀ Eko - Babajide Sanwo-Olu
- OPC láwọn mú afurasí agbébọn ajínigbé mẹ́rin l'Oyo, ọlọ́pàá ní àpapọ̀ òṣìṣẹ́ elétò aàbò ló ṣiṣẹ́ náa
- Wo bí ìwọ náà ṣe lè rí gbà nínú owó ìrànwọ́ tí ìjọba Nàìjíríà fẹ́ pín
Wọ́n kọọ́ sórí rẹ pé Àmìẹ̀yẹ wura PDSA " Fún ẹranko to ní ìgbpoya àti ìtẹramọ́ṣẹ́ lẹ́nu iṣẹ́" láàrín àwọn ẹranko ọgbọ̀n to ti gba irú ami ẹyẹ yìí rí, Magawa ni ẹranko àkọ́kọ́ to jẹ́ Èkúté.
Eeku náà tí kò tíì ju ọdún méje ló, lọ fún ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni Belgium Charity Apopo to wà ni Tanzania níbi ti wọ́n ti ń tọ́ọ- Wọ́n máa n irú wọ́n ni HeroRATs- bí wọ́n ṣe ń ṣe àwárí imọ̀-ilẹ̀ àti ikọ́fée láti ọdún 1990. Ẹranko náà gba ìwé ẹ̀rí lẹ́yín ọdún kan ètò ẹ̀ko

Oríṣun àwòrán, Getty Images
" Iyi nla ni fún wa ní a ṣe ri àmìẹ̀yẹ yìí gbà" Olùdari Apopo Christophe Cox sàlàyé fún ilé ìròyìn Press Association News Agency. " Sùgbọ́n ǹkan nla ni fún àwọn ènìyàn Cambodia àti gbogbo àwọn ènìyàn tó n kojú ọ̀rọ̀ imó-ilẹ lágbáyé"
Lónìí ni PDSA yóò kéde ètò àmìẹ̀yẹ Magawa lori ẹ̀rọ Ayelujara wọn
Gẹ́gẹ́ bi Apopo ṣe sọ Ìlú Tanzania ni wọ́n ti bi Magawa ti o sì wà ni ìwọ̀n kílò 1.2kg àti 70cm ní gígùn nígbà ti wọ́n bii. Èyí tóbi gaa ni sí irú àwọn èkúté míràn. Magawa kò tóbi jù o si fúyẹ daadaa, eyi ló fún ni ànfani lati le rin lórí imọ-ilẹ láì jẹ́ ki o bú gbàmù.
Wọ́n kọ́ Magawa lati ma fi imú finlẹ̀ fún àwọn ǹkan bíi kẹ́míkà, àdó olóró, èyí túmọ̀ si pé, o le ṣe àwárí ìjìnlẹ̀ lórí imo\-ilẹ ki o sì wá jáde ni kíákíá.Ní kété to bá sì ti rí im'\o-ill yiìí yóò gbẹ́lẹ̀, bákan náà ni yóò pe ènìyàn ti wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ láti ṣe èyí tó kù ni àṣeyọri.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹ́gẹ́ bí àjọ kan ti kìí ṣe ti ìjọbaHALO Trust, tó ń ri si ọ̀rọ̀ imọ-ilẹ Cambodia ti ni àkọsilẹ̀ àwọn ènìyàn tó le ni ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélẹgbẹ̀ta tí imọ̀l-ilẹ ti pa àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n àwọn mírà tó ti gé ni ọwọ ati ẹsẹ nítori imọ-ilẹ láti ọdun 1979.
- WASSCE: Ìpínlẹ̀ Delta fòfin de olùkọ́ 41 tó ṣe màgòmágó nínú ìdánwò
- Wọ́n ti yìnbọn pa ọkùnrin ẹni ọgbọ̀n ọdún tó ń jà sí ogún ilẹ̀ bàbá rẹ̀
- Ẹgbẹ́ NULGE Oyo dìbò yan olóyè ẹgbẹ́ tuntun èyí tó tako àṣẹ iléẹjọ́
- Ilé iṣẹ́ ọmọogun òfurufú sọ orúkọ Tolulope Arotile di mánigbàgbé lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà
- Daniel ń bọ̀ wá wò mí nítori mo ṣàìsàn ló dàwátì- Baba Daniel
















