OPC láwọn mú afurasí agbébọn ajínigbé mẹ́rin l'Oyo, ọlọ́pàá ní àpapọ̀ òṣìṣẹ́ elétò aàbò ló ṣiṣẹ́ náa

Oríṣun àwòrán, Gani Adams/facebook
Ẹgbẹ Oodua People's Congress, OPC ti kede pe awọn ti mu awọn agbebọn afurasi ajinigbe mẹrin lapa Oke Ogun nipinlẹ Oyo.
Oluṣakoso ẹgbẹ OPC nipinlẹ Oyo, Ọgbẹni Rotimi Olumo to fidi ọrọ yii mulẹ ṣalaye pe ibọn AK-47 mẹrin lawọn gba lọwọ awọn afurasi ọhun.
Ọgbẹni Olumo sọ pe awọn ti fi awọn afurasi ọhun le ileeṣẹ ọlọpaa ẹkun Igbeti lọwọ.
- Hisbah mú ọkùnrin mẹ́ta tó pín fídíò ìfipábánilòpọ̀ ọmọdébìnrin 16 tó fẹ́ ṣèyàwó lórí ayélujára
- Ọ̀nà àbáyọ márùn ún rèé tí obìnrin àti ọkùnrin bá lẹ̀pọ̀ lásìkò ìbálòpọ̀
- Iyabo Ojo, Toyin Abraham, Mercy Aigbe, ta làwọn òṣèrébìnrin yìí gbè lẹ́yìn lórí ọ̀rọ̀ ìfipábánilòpọ̀?
- Háà Ibadan! Obìnrin tó bá fẹ́ wọn, igbó Sambisa ló lọ - Lizzy Anjorin
- Lawuyi Ogunniran, àgbà ọ̀jẹ̀ òǹkọ̀wé Eégún Aláré dágbére fáyé!
- Ọlọ́jọ́ Festival 2020:Ọ̀ọ̀ni ti Ilé Ifẹ̀ tí wọ ìléèdí ọlọjọ méje tí kò ní rí ẹnikẹ́ni sójú
Ṣugbọn alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi ṣalaye fun BBC Yoruba pe apapọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo pẹlu awọn fijilante lo jọ ṣiṣẹ pọ mu awọn afurasi mẹrin naa.
Nigba ti BBC Yoruba beere boya awọn ọmọ ẹgbẹ OPC wa ninu awọn to mu awọn agbebọn naa, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ko le fidi rẹ mulẹ.
''Ni nkan bii aago meje alẹ ogunjọ oṣu kẹsan an ọdun 2020 yii ni apapọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo pẹlu awọn fijilante mu awọn afurasi mẹrin ọhun ninu igbo Igbeti lagbegbe Kisi,'' alukoro ọlọpaa lo sọ bẹẹ.
O ni mẹta lọwọ ba ninu wọn nigba ti awọn to ku sa lọ pẹlu ọgbẹ ibọn lara wọn.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn agbofinro ti fọn sinu igbo naa lati wa awọn yoku to sa lọ atawọn mii to ba tun wa ninu igbo naa.
- Wo àwọn ìlúmọ̀ọ́ká tó ṣe ìgbéyàwó ní ọdún 2020 yìí
- Bah N'Daw àti Assimi Goita di adarí tuntun láti tukọ̀ orílẹ̀-èdè Mali ní ọdún kan àti aàbọ̀
- Orílẹ̀èdè Amẹrika ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wo wọlé-wọ̀de Atiku, àwọn ìyàwo rẹ̀ lórí owó tí wọ́n kó lọ sí òkèèrè
- 'Àwọn oníṣòwò lẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ nìkan ló lè forúkọ sílẹ̀ báyìí fún ìrànwọ́ ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà'
- Ìjọba Katsina ní kí àwọn iléèwé wà ṣì ní títìpa nítorí arùn Coronavirus















