School reopening: Ìjọba ìpínlẹ̀ Rivers kéde ọjọ́ tí àwọn iléèwé yóò wọlé padà

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Google

Ìjọba Katsina ní kí àwọn iléèwé ṣì wà ní títìpa nítorí àrùn Coronavirus

Ijọba ipinlẹ Katsina ti sọ wi pe ileekọ alakọbẹrẹ ati girama ko tii le wọle pada ni asiko yii ni ipinlẹ naa.

Kọmisọnna fun eto ẹkọ nipinlẹ naa, Ọjọgbọn Badamasi Lawal lo sọ bẹẹ pe awọn ṣi n ṣe agbeyẹwo bi eto ẹkọ yoo ṣe ri ni Naijiria lasiko arun Coronavirus yii.

Lawal ni idanwo aṣekagba ti wọn ṣẹṣẹ ṣetan yii ni awọn fi wo boya yoo ṣeese ki awọn akẹkọọ pada si ileewe lai lugbadi arun Coronavirus.

O ni ileewe ko ni ṣi pada ni ipinlẹ Katsina titi di igba ti ijọba apapọ ba fi ilana tuntun lede pẹlu akoko ati igba ti awọn akẹkọọ le pada lai si ewu.

''Idanwo aṣekagba yii ni awọn fẹ fi mọ boya ko ni si ẹni ti yoo lugbadi arun naa lasiko idanwo to n lọ lọwọ.''

Amọ, inu wa dun wi pe ko si ẹnikankan ninu awọn akẹkọọ ẹgbẹrun lọna mẹfa to ṣe idanwo naa to lugbadi arun Coronavirus.

Kọmiṣọnna fun eto ẹkọ naa wa fikun wi pe awọn n ṣe atunṣe awọn ileewe ti ojo arọrọda naa bajẹ ni igbaradi fun awọn akẹkọọ to fẹ wọle pada si ẹnu ẹkọ wọn.

Àkọlé fídíò, Abule Ado explosion: Irọ́ ńlá ní NNPC pa lórí ìbúghbàmù Abule Ado níbí tí ẹ̀mí èèyàn 23

Ṣé Nàìjíríà lẹ́mìí nkan tí Ghana ń ṣe fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ "Secondary" tí yóò wọlé ní October yìí?

Aarẹ Nana Akufo Addo ti orilẹede Ghana lo kede pe ki awọn akẹkọọ onipele keji ati ikaarun ti ileewe Girama ti wọn ti wa nisinmi sile fun ọpọlọpọ oṣu wọle sẹnu ẹkọ wọn pada lọjọ ikarun un, oṣu kẹwaa titi di ọjọ kẹrinla, oṣu kejila pe ki wọn fi pari saa ẹkọ ti wọn wa ki asiko arun Coronavirus to bẹrẹ.

GHANA

Oríṣun àwòrán, GHANA EDUCATION SERVICE/FACEBOOK

Eyi waye gẹgẹ bi aarẹ Akufo ni ki awọn akẹkọọ ti ileewe jẹleosinmi, alakọbẹrẹ titi de ipele kini ni girama ṣi jokoo sile di inu oṣu kini ọdun 2021.

Ninu ọrọ to sọ lorii ẹrọ amohumaworan lalẹ ọjọ Aiku ni aarẹ Akufo-Addo ti sọ pe igbesẹ yii waye lẹyin ọpọlọpọ gbigba imọran lọdọ awọ tọrọ kan ni ẹka eto ẹkọ.

O wa fi awọn alakalẹ wọnyii silẹ pe o ṣe koko ki wọn tẹle e:

  • Ati akẹkọọ, ati olukọ, wọn gbọdọ tẹle awọn ofin Covid-19.
  • Akẹkọ ọgbọn pere lo lee wa ninu kilaasi kan naa ni ẹka awọn wẹwẹ ni girama onipele ikeji.
  • Akẹkọ mẹẹdọgbọn pere lo lee wa ninu kilaasi kan naa ni ẹka ti awọn agba girama onipele ikeji.
Àkọlé fídíò, Natalia Mufuta ìyá Yakub, Kamil àti Adam sọ̀rọ̀ lórí bí wọ́n ń sọ èdè mẹ́rin pàpọ
  • Gbogbo oṣiṣẹ ileewe to jẹ olukọni atawọn ti ko kọni to fi mọ awọn ọmọ ileewe gbudọ maa wọ ibomu wọn, ijọba yoo si pese awọn ibomu to ṣee tun lo fun wọn.
  • Ijọba yoo tun pese garawa irọmi si eyi ti wọn n pe ni "Veronica bucket", galọọnu ọṣẹ ifọwọ, beba inuwọ, ẹrọ to n yẹ igbona ara wo ati mili-lita igba oogun apakokoro sanitaisa.
  • Lara anfani ti awọn akẹkọ yoo jẹ ni pe wọn yoo maa fun ẹka awọn ọmọ wẹwẹ ileewe girama onipele keji ni ounjẹ gbigbona ni ọọkan lojoojumọ.
  • Lafikun wọn gbudọ fin gbogbo ileewe pẹlu kẹmika apakokoro ki wọn to wọle.Ko gbudọ tii si ipejọpọ kankan bii tito lori ila tabi ṣiṣe ere idaraya; awọn eeyan lati ita ko gbudọ lo inu ọgba ileewe fun inawo kankan.
  • Lakotan wọn yoo fun ileewe ti ko ba ni ibudo itọju alaisan lanfani lati maa lo awọn mii to wa nilu.
Àkọlé fídíò, 'Oyenusi ló mú mi wọ ẹgbẹ́ adigunjalè kó tó di pé mo b'Ólúwa pàdé'

Aarẹ orilẹede Ghana ni ẹka eto ẹkọ ti ṣe gbogbo eto ti ko ni jẹ ki awọn akẹkọọ padanu nkankan to yẹ pẹlu bi wọn ko ṣe lọ sileewe lọdun yii.

Ninu ọrọ rẹ aarẹ Akufo ni laipẹ wọn yoo pinu lorii igba ti awọn ere idaraya yoo bẹrẹ ṣugbọn lọwọlọwọ bayii, awọn ibudo itura bii eti okun, ibi igbafẹ, ile sinima ati ile ijo yoo ṣi di titi pa di igba ti alakoko ba ni o to.

Àkọlé fídíò, Wo bí Sunday Orimola ṣe gba ikú ẹranko kú ní Ifon ni Ondo lórí ọ̀nà àtijẹ