NIMC: NIMC, NCC, NITDA àti GBB gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ papọ̀ kí ètò aàbò Nàìjíríà lè dára síi

Oríṣun àwòrán, Instagram/Bashir Ahmad
Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu gbigba iṣakoso kaadi idanimọ orilẹ-ede yii lọ si ẹka ijọba to n ri si eto ibanisọrọ.
Agbẹnusọ fu minisita eto ibanisọrọ, Uwa Suleiman lo fidi ọrọ naa mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita.
O sọ ninu atẹjade naa pe Aarẹ Buhari gba lati gbe iṣakoso kaadi idanimọ fun ẹka ijọba to n ri si eto ibanisọrọ nitori ipa ribiribi ti ileeṣẹ ijọba naa ti ko ninu ilọṣiwaju ọrọ aje Naijiria.
O ni ileeṣẹ Galaxy Backbone Limited, National Information Technology Development Agency, National Identity Management Commission, Nigeria Communication Commission, ati Nigeria Data Protection Regulation gbọdọ fọwọsowọpọ.
- Ọ̀fẹ́ ni China yóò kọ́ fásítì $50M ètò ìrìnnà sí Daura ìlú Ààrẹ Buhari- Amaechi
- Irọ́ ni, kò sí olóyún nínú àwọn tí Tírélà pa ní Ondo ṣùgbọ́n awakọ̀ ti sá lọ- Ọlọ́pàá Ondo
- Ọba ni mí, mi ò le b'ọ̀rìṣà, Olorì tuntun tó ń bọ̀ já gbogbo ''scale''- Oluwo ti Iwo
- Iléẹjọ gíga jùlọ da ẹjọ́ SDP àti PDP nù, wọ́n ní Yahaya Bello ló wọlé ìbò gómìnà Kogi
- Ẹ̀yin ọmọ ìta tó ní Funke Akindele ra ilé fún mi, irọ́ ni o - Ajirebi
- Ìtàn ayé Henry Fajemirokun, olówó tó fi owó mọ Olúwa àti ènìyàn
Suleiman ni igbesẹ Aarẹ yoo fun ẹka ijọba to n ri si eto ibaraẹnisọrọ lati ṣamojuto gbogbo awọn ẹka ti wọn ni ohun kan tabi omiiran ṣe pẹlu kaadi idanimọ daadaa.
Lọdun 2007 ni ijọba sẹ ofin to ṣe agbekalẹ ẹka ijọba, NIMC lati maa bojuto ipese kaadi idanimọ fawọn ọmọ Naijiria.
Ijọba apapọ ri kaadi idanimọ bi ohun to wulo fun eto aabo, bakan naa lo ṣe pataki fun eto ọrọ aje Naijiria.
Ẹka ijọba to n ri si eto ibaraẹnisọrọ ti wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati fi ọrukọ silẹ fun kaadi idanimọ.
Kò sí ìfòyà tí ẹ bá ti ní nọ́mbà ìdánimọ̀, kékeré ni káàdì ìdánimọ̀ - NIMC
Ajọ to n pin kaadi idamọ Naijiria, NIMC, ti sọ pe nọmba idanimọ lo ṣe pataki ju kaadi idanimọ, nitori naa, ki awọn ti ko ba tii ri kaadi wọn gba ma foya.
Aṣoju ajọ ọhun to ba BBC sọrọ ṣugbọn ti ko fẹ fi orukọ rẹ lede ni, ko si otitọ ninu iroyin kan to sọ pe ẹnikẹni ti ko ba forukọ silẹ fun numba idanimọ ọhun yoo ṣewọn oṣu mẹta.
O ṣalaye pe ijọba n te kaadi idanimọ naa jade diẹ diẹ ni, idi ree ti ọpọ awọn to ti forukọ silẹ ko ṣe tii fi ri kaadi wọn gba.
Ni ti pe awọn ti ko ba forukọ silẹ fun kaadi idanimọ ọhun bakan naa yoo san owo itanran ẹgbẹrun lọna ọgọrun un naira, o ni ajọ naa ko tii gbe aṣe lati ṣe bẹẹ jade.

Oríṣun àwòrán, @NIMC
O ni "Ko si otitọ ninu iroyin yẹn. Ti a ba tẹlẹ ilana ti a fi n ṣiṣẹ, ko si nnkan to jọ bẹẹ."
Nigba to n ṣalaye pataki nọmba idanimọ ọhun, o ni kaadi idanimọ ni ọjọ lori, ṣugbọn nọmba idanimọ wa titi lai.
O ni "Ti eeyan ba ti ni nọmba idanimọ lo ṣe koko ju. Ẹnikẹni to ba ti gba nọmba idanimọ lee lo fun ohunkohun bii nile ifiwopamọ, ati ririn ajo lọ si oke okun, gbigba owo ifẹyinti, ati bẹbẹ lọ."
Ni ti awọn ọmọ Naijiria to wa loke okun, o ni ajọ naa ti wa lawọn orilẹ-ede bii Amẹrika ati Canada, ki awọn ọmọ Naijiria to wa lọhun lee forukọ silẹ lai si idiwọ.
















