Tanzania church crusade: Àwọn ọmọ ìjọ náà ń sáré lọ 'wájú pẹpẹ láti gba ìfàmì òróró hàn

Ibi isọji ni iṣẹlẹ na ti ṣẹlẹ

Oríṣun àwòrán, GODFREY THOMAS, AYO TV

O kere tan eeyan ogun lo ti dagbere fáyé ti awọn mii si fara pa nibi ipejọ isọji itagbangba ijọ kan ni ilu Moshi.

Awn olujọsin n ṣe isin lọwọ ni papa iṣere kan ni iha ariwa ilu Moshi orilẹede Tanzania lọjọ abamẹta nigba ti iṣlẹ yii ṣẹ.

Kọmisana ọlọpaa ẹkun ti Moshi, Kippi Warioba sọ pe awọn wa fun isọji naa n sa lọ siwaju pẹpẹ lati lọ gba ifami ororo yan alabunkun fun lọdọ pasitọ.

Pasitọ Moniface Mwaposa ti o maa n pe ara rẹ ni "Apositeli" lo dari isọji naa.

Aarẹ orilẹede Tanzania ti fi ọrọ ibanikẹdun rẹ ranṣẹ o si pe fun ki awn eeyan ri i pe abo gidi wa ni iru ipejọpọ nla bẹẹ.

Awọn tori yọ nibi iṣẹlẹ naa sọ pe Ọgbẹni Mwamposa sọ fun ọgọọrọ eeyan to wa nibi isọji ọhun pe ki gbogbo wọn gba apa ibi kan ti wn ni o da "ororo ibunkun silẹ".

Tori eyi, gbogbo ero to wa nibẹ bẹrẹ si ni sare siwaju lati lọ tẹ ororo ibunkun naa mọlẹ pẹlu ireti pe awọn yoo ri iwosan gba.

Peter Kilewo to wa nibi isọji ọhun ṣalaye iṣẹlẹ naa bi eyi to buru jai. O s fun ileeṣẹ iroyin AFP pe "lai laanu ni wọn n tẹ awọn eniyan mọlẹ ti wọn si n fi igunpa rọ ara wọn danu".

O fi kun un pe "afi bii pe oniwaasu naa n fọn kiti kiti owo dollar kiri".

Papa iṣere isọji

Oríṣun àwòrán, Image copyrightGODFREY THOMAS, AYO TV

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti gbe Pasit naa, Ọgbẹni Mwamposa fun ifọrọwanilẹnu wo.

Bẹẹ si ni Ọgbẹni Warioba sọ pe awọn alaṣẹ ti n ṣamojuto boya wọn gbe awọn awọn mii to fara pa lọ si awọn ile iwosan tabi ibudo ilera.

Ọwọ alẹ ni iṣẹlẹ naa waye ti ero si pọ nitori naa o ṣeeṣe ki awọn to fara pa ṣi pọ ṣugbọn o ni awọn ti n moju to eto naa.

Aworan atọka orilẹede