Yahaya Bello: Iléẹjọ́ tó ga jùlọ fòǹtẹ̀ lu Yahaya Bello, wọ́n da ẹjọ́ PDP àti SDP nù

Natasha Akpoti, Idris Wada ati Yahaya Bello

Oríṣun àwòrán, Facebook

Iléẹjọ́ tó ga jùlọ fòǹtẹ̀ lu Yahaya Bello gẹ́gẹ́ bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi

Ileẹjọ to ga julọ ni Naijiria ti fi ontẹ lu eto idibo to gbe Yahaya Bello wọle gẹgẹ bi Gomina ipinlẹ Kogi.

Ninu idajọ rẹ lọjọ Aje niluu Abuja, ileẹjọ naa tu ẹjọ ti ẹgbẹ oṣelu PDP pe ẹgbẹ oṣelu APC tii ṣe ẹgbẹ Bello ka.

Lọsẹ to lọ ni igbimọ oludajọ ẹlẹni meje ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria labẹ idari adajọ agba ni Naijiria, Tanko Mohammed gbọ ẹjọ ti oludije ibo gomina fẹgbẹ oṣelu PDP, Musa Wada pe Gomina Yahaya Bello to wọle ibo naa.

Ninu idajọ ti Adajọ Inyang Okoro ka jade lorukọ igbimọ awọn adajọ mejeeje to ṣapero lori ipẹjọ naa, ileẹjọ fi ontẹ lu idajọ ileẹjọ kotẹmilọrun ati ti igbimọ igbẹjọ to n ri si awuyewuye ibo gomina to dajọ pe Bello lo jawe olubori ninu ibo gomina Kogi.

Àkọlé fídíò, Wo bí Sunday Orimola ṣe gba ikú ẹranko kú ní Ifon ni Ondo lórí ọ̀nà àtijẹ

Lẹyin ti igbimọ oludajọ ṣe agbeyẹwo koko marun un ti ẹgbẹ oṣelu PDP fi gbe Gomina Bello APC lọ si ileẹjọ, ileẹjọ giga ni awọn ẹsun naa ko lẹsẹ nlẹ.

''Lẹyin ti a wo eṣun ti oludije PDP pe ẹgbẹ oṣelu APC pe kudiẹkudiẹ wa ninu eto idibo to gbe Yahaya Bello gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Kogi, o ti han gbangba pe ko si ẹri to dalu lati fi idi ẹsun naa mulẹ, nitori naa, a tu ipẹjọ PDP ka,'' adajọ Okoro lo sọ bẹẹ.

Adajọ agba ni Naijiria, Mohammed, adajọ to ka idajọ ileẹjọ, Okoro ati Abba-Aji atawọn ọmọ igbimọ igbẹjọ mii lo fẹnu ko lori idajọ naa.

Àkọlé fídíò, Natalia Mufuta ìyá Yakub, Kamil àti Adam sọ̀rọ̀ lórí bí wọ́n ń sọ èdè mẹ́rin pàpọ

Ileẹjọ to ga julọ tun da ẹjọ onikoko meje ti oludije ẹgbẹ oṣelu SPD, Natasha Akpoti naa pe wi pe igbakeji gomina Kogi, Edward Onoja parọ ọjọ ori rẹ ati pe o tun fi ayederu iwe ẹri ranṣẹ si ajọ INEC nu.

Igbimọ oludajọ naa sọ pe ko si ẹri to daju lati fi idi gbogbo ẹsun ti SDP fi kan igbakeji gomina Kogi mulẹ.