Òtítọ ní Obasanjo sọ, Buhari n fí agbára fún ẹlẹ́yàmẹ̀yà ní Nàìjíríà-Soyinka

Aworan Wole Soyinka

Oríṣun àwòrán, CHARLES IGBINIDU/Twitter

Onkowe Ọjọgbọn Wole Soyinka ti ṣe atilẹyin fun ọrọ ti aarẹ ana Olusegun Obasanjo sọ wi pe ogun ẹlẹyamẹya gbinlẹ si labẹ ijọba Aarẹ Buhari.

Soyinka sọ ọrọ yii ninu atẹjade to fi lede to pe akọle rẹ ni "Between 'Dividers-in-chief' and Dividers-in-law," ni ile rẹ ni Ijegba, Idi-Aba Estate, Abeokuta.

Ilumọọka ọjọgbọn yi ni botilẹ jẹ pe oun ko gba ti Obasanjo nitori o pẹlu awọn adari to ba Naijiria de ibi to wa bayii, lori ọrọ to sọ, oun gbe lẹyin rẹ.

O ni gbogbo ọrọ ikilọ ti Obasanjo ti n fi lede labẹ iṣejọba aarẹ Buhari lo tọna ti o si yẹ ki wọn kiyesi, ṣugbọn ijọba keti ikun si nitori Obasanjo lọ sọ ọrọ yii.

O ṣalaye pe ''iyẹn o ni wi pe mọ yi ohun pada lori iwa buruku ti Aarẹ ana, Olusegun Obasanjo wu nigba ti o wa ni ipo.'

'Amọ, a gbọdọ wo ọrọ ti oun sọ fun itẹsiwaju orilẹede Naijiria ati awọn ikilọ rẹ lai bikita ibi ti ọrọ naa ti wa.'

Soyinka fi kun pe 'Orilẹede Naijiria ti n lọ si okun igbagbe nitori ko si ifẹ tabi ajọṣepọ to le e mu isọkan gbinlẹ mọ lorilẹede Naijiria.'

Aarẹ Buhari ati Aarẹ tẹlẹ, Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O ni kaka ki wọn gbọ imọran Obasanjo, radarada ni ijọba aarẹ Buhari n ba kaakiri.

'Ẹlẹyamẹya ti ohun waye labẹ iṣejọba aarẹ Buhari ko ṣẹyin ihuwasi aarẹ fun ara rẹ, ati awọn igbesẹ ati eto ti aarẹ n ṣe ti ko mu itẹsiwaju ba orilẹede Naijiria.'

Ọjọgbọn Wole Soyinka ṣe iranti asiko ti awọn darandaran pa awọn eniyan lọgọọrọ, sugbon kaka ki aarẹ Buhari gbe igbesẹ lati da abo bo awọn eniyan, ohun ti aarẹ Buhari sọ ni pe ki awọn eniyan naa wa ọna lati gbe ni alaafia.

Bakan naa ni o sapejuwe ẹka eto idajọ ni Naijiria ti wọn ko naani ẹtọ awọn araalu afi awọn oṣelu ati awọn alagbara ti wọn le lo ọna magomago lati ri wi pe idajọ naa lo bi wọn ṣe fẹ.

Aarẹ Buhari ati Aarẹ tẹlẹ, Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lai Mohammed, Ayo Fayose, Afẹnifẹre, Ndigbo, Arewa dá sí ọ̀rọ̀ Buhari àti Obasanjo

Awọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ si ni da si ọrọ ti Aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria, Olusegun Obasanjo sọ ati esi ti Aarẹ Muhammadu Buhari fun Obasanjo.

Ko pẹ ti Minisita to n ri si iroyin ati aṣa, Lai Muhammed naa tẹnu bọ ọ̀rọ̀ yii lawọn ọmọ Naijiria naa tu kẹkẹ ọrọ silẹ.

Alhaji Lai Muhammed fi sita pe bi kii ba ṣe ti aarẹ Buhari ni, orilẹede Naijiria o ba ti fori sanpọn.

Olusegun Obasanjo ati Muhammadu Buhari

Ni Ọjọbọ, ọsẹ to kọja ni Baba Obasanjo sọ wipe orilẹede Naijiria ti n lọ sokun igbagbe nitori oun gbogbo ti n dẹnukọlẹ lasiko iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari.

Ileeṣẹ Aarẹ nigba ti wọn n fesi sọ wi pe Obasanjo gan an ni mọndaru to n pin orilẹede Naijiria, ti o si n sọrọ ẹlẹyamẹya lati igba de igba.

Amọ, awọn ẹgbẹ ọmọ Yoruba ati ẹgbẹ miran lapapọ ti n fesi si ọrọ gbọn mi si omi o to to n waye laarin awọn mejeeji.

Ayo Fayose, Afẹnifẹre, Ndigbo, Arewa dasi ọrọ Buhari ati Obasanjo

Lara awọn to kọkọ fesi ni Gomina ipinlẹ Ekiti tẹleri, Ayo Fayose ni bi o tilẹ jẹ pe oun ko fi igba kan gba ti Obasanjo, otitọ ọrọ gbaa ni Baba Obasanjo sọ.

Lasiko ti Fayose n ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Dele Momodu lo sọ bẹẹ.

Bakan naa ni ẹgbẹ Afẹnifẹre naa ni awọn faramọ ohun ti Obasanjo sọ nitori Aarẹ Buhari ti kuna lati jẹ ki isọkan o jọba lorilẹede Naijiria.

Ninu ọrọ ti wọn, ẹgbẹ awọn ọmọ Igbo, Ohanaeze Ndigbo sọ wi pe otitọ ọrọ ni Obasanjo sọ nitori o mọ ibi ti bata ti n ta orilẹede Naijiria lẹsẹ, amọ o ṣeni laanu wipe ijọba to wa lode yii ko gbọ ọrọ si awọn eniyan lẹnu.

Àkọlé fídíò, 'Aràrá bíi tèmi, kó má rò pé kò sì ǹkan tó lè ṣe láyé ju iṣẹ́ agbe lọ'

Amọ ninu ọrọ ti wọn, ẹgbẹ Arewa Consultative Forun ni Aarẹ Buhari ni awọn ṣe atilẹyin fun pẹlu ẹgbẹ oselu APC, ati wi pe ọrọ Obasanjo gan an lo n da idarudapọ silẹ lorilẹede Naijiria.

Alaga ẹgbẹ Arewa naa, Audu Ogbeh ni ọrọ agọ ni Obasanjo sọ, eleyii ti ko mu ọpọlọ dani rara, ti o si le e da wahala silẹ lorilẹede Naijiria.

O fikun wi pe nigba ti Obasanjo wa lori oye, ọpọlọpọ nkan ni ko fararọ fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria.

Awọn ọmọ Naijiria naa dasi ni ori ẹrọ ayelujara

Bakan naa ni awọn ọmọ Naijiria kan to n sọrọ lori ẹrọ ayelujara naa n sọ wi pe ohun ti Obasanjo sọ dara.

Amọ, awọn miran ni awọn agbalagba bii Baba Obasanjo gan lo wa nidi iṣoro to ba orilẹede Naijiria, pe kii ṣe Buhari nikan ni o ba Naijiria de ibi ti o wa.

Obasanjo gan an ló ń ṣe ìpínyà Nàìjíríà, Buhari ló ń tún ṣe -Iléeṣẹ́ ààrẹ

Ileeṣẹ aarẹ orileede Naijiria ti sọko ọrọ pada si aarẹ ana, Olusegun Obasanjo pe ohun gan an lo n gbe igbesẹ lati mu ipinya ba Naijiria.

Garba Shehu to jẹ oludamọran aarẹ lori ọrọ iroyin ni o fesi yi ni idahun si ọrọ ti Obasanjo sọ pe Naijiria ti pin yẹlẹyẹlẹ labẹ ijọba Buhari.

Shehu sọ pe Buhari n tun Naijiria ṣe ni ati pe Obasanjo lo n mu ipinya ba orilẹede naa.

Eyi kii ṣe igba akọkọ ti ileeṣẹ aarẹ labẹ ijọba Buhari yoo maa tako ọrọ aarẹ ana Obasanjo .

Ninu atẹjade tuntun yii, Shehu ni ohun to yẹ Obasanjo gẹgẹ bi agba ilu ni ko daba ọna ati yanju ipenija to n ba Naijiria finra dipo bo ti ṣe n ru ina si ipinya labẹ ẹsin ati ẹya.

Garba tun mẹnu ba bi aarẹ Buhari ṣe mu ọkan akin lati yọ owo afikun epo rọbi taa mọ si ''subsidy'' eleyi ti ijọba Obasanjo da laba ṣugbọn ti wọn ko ṣọkan akin lati sọ di mimuṣẹ.

O tun mẹnu ba idagbasoke ti ijọba Buhari ti mu ba Naijiria nipa pipese ayika to faye gba karakata ati idunadura pẹlu awọn ilẹ okeere.

O sọ pe pẹlu bi Buhari ti ṣe ṣe aṣeyọri to yi, ko jẹ iyalẹnu pe awọn oloṣelu ti ko ni aseyọri lasiko wọn yoo maa jowu aarẹ Buhari.

Àkọlé fídíò, Obasanjọ: Ọbasanjọ ní òhun yóò fi ìyókù ayé òun san oore Ọlọrun ni

Nàíjíríà ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ láyé Buhari, ìjákulẹ̀ dé! - Obasanjo gbarata

Yoruba ni agba kii wa lọja ki ori ọmọ tuntun wọ, bẹẹ si ni agba ti ko ba kẹhun sọrọ, afaimọ ko ma kẹ itan sare to ba ya.

Idi ree ti aarẹ tẹlẹ ni Naijiria, Olusegun Obasanjo fi n figbe bọnu pe Naijiria ma ti n kuna lọ laye isejọba Buhari, eyi to yẹ ka tete doola rẹ.

Ilu Abuja ni Obasanjo fi kede bẹẹ ninu ọrọ apilẹkọ rẹ to pe akori rk ni "Ẹ jẹ ka rin jinna si isubu", to gbe kalẹ nibi ipade apero kan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn oniruuru ẹlẹgbẹjẹgbẹ to jẹ ti ẹya kọọkan lawọn ẹkun gbogbo to wa ni Naijiria , bii Afenifere, Middle Belt, Agbaagba lẹkun ariwa, Ohanese Ndi Igbo ati Pan Niger Delta Forum.

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Others

Obasanjo ni aile se akoso oniruuru ẹya to wa nilẹ yii lo mu ki orilẹede yii pin yẹlẹyẹlẹ, eyi to jẹ isoro kan gboogi to n ba wa finra.

Aarẹ tẹlẹ naa wa fewe ọmọ mọ awọn eeyan to n lu ilu ogun, ti wọn si ni awọn yoo ya kuro lara Naijiria ni lati sọra se.

"Bi ẹya kọskan ba pin kuro lara Naijiria, ẹ ma gbagbe pe a si tun jẹ alamuleti ara wa, tawọn araalu yoo si nilo lati maa ba ara wọn se."

O wa gbe imọran kalẹ pe ti yoo ba se rere, o gbọdọ kọkọ wa ojutu sawọn isoro to nii se pẹlu irẹpọ to sọnu laarin ẹya kọọkan.

Àkọlé fídíò, Mistura Oseni Akintunde: Ara múmú kìí ṣe oríṣun ìfipábánilòpọ̀, ìran àwòjù ló ń fà á

Bakan naa lo woye pe igbesẹ sise ipade apero miran tile asofin apapọ ilẹ wa n gbero kan wa lati fi akoko sofo ni.

O wa gbe oriyin fawọn ẹgbẹ ibilẹ to ti tako igbesẹ naa, eyi to se apejuwe bii ọna lati baana owo miran.

Kí ló mú Obasanjo ti ilẹ̀kùn mọ́ ẹbí, òṣìṣẹ́, ojúlùmọ̀ ní ibi òkú àna rẹ̀?

Awọn ẹbi Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Other

Aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria, Olusegun Obasanjo ti sọ idi ti oun fi ti ilẹkun ile ijọsin mọ awọn oṣiṣẹ rẹ ati ojulumọ, to wa si ibi ayẹyẹ oku iya iyawo rẹ ni Ọjọ Ẹti.

Baba Obasanjo ninu atẹjade to fi lede sọ wi pe, nitori arun Coronavirus ni oun ṣe gbe igbesẹ naa.

Obasanjo salaye pe, bi eto isinku ọhun ṣe bẹrẹ ni agogo mẹwa owurọ ni ijọ Saint Peters Anglican Church to wa ni Isara-Remo, ni ipinlẹ Ogun, ni oun funra oun ti ilẹkun ile ijọsin ọhun, ki awọn eniyan ma ba raye wọle.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, 'Ó ṣe pàtàkì kí obìnrin gbádùn ìbálòpọ̀ nítorí...'

O fikun pe oun tẹle aṣẹ ijọba to tako ipejọpọ awọn eniyan ọlọgọrọ lasiko ajakalẹ arun Coronavirus yii.

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Others

N ṣe ni awọn oṣiṣẹ ati ojulumọ naa duro sita lẹyin igbesẹ Baba Obasanjo, ti wọn si lọ sin oku ohun lẹyin isin.

O ku diẹ ki Mama Florence Adenekan pe ẹni aadọrun ọdun lo jade laye.

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Others

Mama Adenekan ni iya Bola Obasanjo to jẹ ọkan lara iyawo Baba Obasanjo.

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Others

Iroyin gbe pe, iyawo Obasanjo ko si nibi eto isinku naa, tori o wa ni Ilẹ Gẹẹsi lasiko isinku iya rẹ, ti Baba Obasanjọ si ṣe oju rẹ ni ibi isinku ohun.

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Others

Lẹyin isinku naa ni Baba Obasanjo wa tẹsiwaju lọ ki awọn lọbalọba to wa ni agbegbe naa.

Obasanjo bẹ̀rẹ̀ ọ̀sìn ẹja 50,000 ní oko rẹ̀ láti dènà ebi

Yoruba ni ati okeere ni oloju jinjin ti n mu ẹkun sun, bẹẹ si ni igi gogoro ma gun mi loju, ati okeere la ti n lọ ọ.

Ọsin ẹja Obasanjo

Idi ree ti aarẹ tẹlẹ ni Naijiria, Oloye Olusegun Obasanjo fi gunle ọsin ẹja bii ẹgbẹrun lọna aadọta lati dena iyan to le waye lẹyin arun Coronavirus.

Bakan naa ni Obasanjo tun laago ikilọ fun awọn olori orilẹ-ede ede ni ilẹ Afirika pe, ki wọn tete dawọle ọgbin oúnjẹ lọpọ yanturu lẹyin arun Coronavirus.

Oloye Obasanjo woye bẹẹ lasiko to n sọrọ níbi ifilọlẹ ọgbin ẹja naa eyi to waye nibudo iyawe kawe rẹ (OOPL) to wa nilu Abeokuta.

Obasanjo, ẹni tí inu rẹ dun jọjọ lori ọgbin ẹja naa ni, ironu jinlẹ lori iyan to lee sẹlẹ lẹyin ti arun Covid-19 ba kasẹ nilẹ lagbaye, lo mu ki oun gunle ọgbin ẹja naa.

Ọsin ẹja Obasanjo

"Mo ro pe o yẹ ka mu ọrọ ohun tí yoo sẹlẹ lẹyin arun Coronavirus ni ibaada, mo si gbagbọ pe awọn ijoba ilẹ Afirika yẹ ki wọn ronu bi wọn yoo ṣe ni oúnjẹ ni anisẹku, ki ọwọ ebi ma ba ka awọn eeyan wọn."

Awọn ẹgbẹrun lọna aadọta ẹja to wa ni oko Obasanjo naa lo jẹ ẹja alaran ati ọbọkun ti wọn tu da sinu odo ẹja lati dagba.

Olusegun Obasanjo wá rọ àwọn ìjọba Áfíríkà láti bẹ̀rẹ̀ ọ̀gbìn oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu gẹ́gẹ́ bíi ọ̀nà láti dènà ebi lẹ́yìn àrùn Covid-19.