Professor Ayo Akinwale: Iṣẹ́ rẹ ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn

Ọjọgbọn Ayo Akinwale

Oríṣun àwòrán, Etsu Muazu Idris/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ayobami Akinwale ọmọ agbo Sasa ọmọ agbo Yaya,

Ọmọ Ibadan nile Oluyole, Omo ajẹgbin jẹ 'karahun ....

Ijagboro loro Ibadan. Ọmọ Ibadan mesiọgọ,

Omo Ibadan Maja Maja ti o fina ara waju leru.......... Hmmmmn!

"O yẹ ki ọga mi pe aadọrin dun ninu oṣu kẹrin ọdun to m bọ".

Gẹgẹ bi Abdulrasheed Adeoye to jẹ oludari agba ẹka iṣẹ ọna to si ti jẹ oludari ẹka imọ Tiata ni fasiti Ilorin eyi tii ṣe ipo meji ọtọọtọ ti oloogbe Ayo Akinwale naa ti kuro to gbe eku ida le e lọwọ, wọn bi Ayo Akinwale ni ilu Ibadan, ọmọ bibi ilu Ibadan si ni pẹlu.

"Ẹni ti Ọlọrun da ti ko ṣee fara we ni Ọjọgbọn Ayo Akinwale. O mu gbogbo akẹkọọ bi ọmọ rẹ, oloju aanu si ni".

Àkọlé fídíò, 'Aràrá bíi tèmi, kó má rò pé kò sì ǹkan tó lè ṣe láyé ju iṣẹ́ agbe lọ'

Gbogbo agbaye ni Ayo Akinwale ti rin kaakiri lati lọ ṣiṣẹ.

Gbogbo oye to yẹ keeyan gba ninu imọ iṣẹ Tiata lo gba nigba aye rẹ- oye Diploma, Degree, Masters, PhD ni ẹka Tiata fasiti ilu Ibadan.

Abdulrasheed ni gbogbo ohun to wulo fun oniṣẹ Tiata ni rere lawọn atawọn akẹkọ kọ lọdọ Ayo Akinwale.

"Baa ṣe le sọrọ soke,

baa ṣe le rin lori itage,

ṣiṣẹju si eeyan, lilo ọwọ,

iru aṣọ to yẹ ka mọ ni ọga kọ wa. Bo ba wa dari ere kan lonii to di oṣu to m bọ to mu omii, ọtun ọtun lẹ o maa ri ninu iṣẹ rẹ".

Yatọ fun iṣẹ Tiata, ilumọọka ni Ayo Akinwale ninu fiimu lati igba awọn ere atijọ bii:

Afonja

Sango

Ladepo Omo Adanwo

Iranse Aje

Agbara Obinrin ati bẹẹ bẹẹ lọ pẹlu oniruuru ami ẹyẹ ti Ayo Akinwale gba gẹgẹ bi oṣere, oludari ere, ẹlẹsẹ ijo ati olohun orin - "gbogbo iha Tiata lo pe lara Ayo Akinwale". Abdulrasheed sọ fun BBC Yoruba.

Erin lo nigbo! Tigbo-tiju palolo! Ajanaku subu n dide. Ha! Osan ja! Orun ti dopa!

Gbajugbaja oṣere to tun jẹ ọkan gboogi ọga lọga lagboTiata nile ati lẹyin odi, Ọjọgbọn Ayo Akinwale ti bẹrẹ irinajo rẹ lọ sọrun.

Dajudaju, ẹja nla lo lọ laarin awọn elere Tiata pẹlu bi ayelujara awọn olukọni ati akẹkọ, to fi mọ awọn ọjọgbọn fasiti atawọn agba oṣere ṣe kun fọfọ pẹlu aworan ati iṣẹ ire ti Ayo Akinwale ṣe.

Awon olukọ imọ ẹkọ Tiata ati ẹka iṣẹ ọna ni fasiti Ilorin

Oríṣun àwòrán, Abdurasheed Adeoye/Facebook

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Àkọlé fídíò, 'Aràrá bíi tèmi, kó má rò pé kò sì ǹkan tó lè ṣe láyé ju iṣẹ́ agbe lọ'

Gẹgẹ bi oludari agba ẹka iṣẹ ọna fasiti Ilorin to gba eku ida ẹka yii kan naa lọwọ Ọjọgbọn Akinwale, Ọjọgbọn Rasheed Adeoye ṣe fi atẹjade sita, gbajugbaja oṣere yii to tun jẹ igi nla lagbo imọ ẹkọ Tiata, Ayo Akinwale jade laye lọjọ kẹtala oṣu kẹsan ọdun 2020 ni ile iwosan fasiti Ilorin.Ayo Akinwale ti jẹ adari patapata ẹka imọ ẹkọ Tiata, Performing Arts ni Fasiti Ilorin ati oludari agba ẹka isẹ ọna ni fasiti kan naa ko to jẹ Ọlọrun nipe.