Tunde Braimoh: Itẹ́ òkú ní Vault Garden ní wọ́n sin Aṣòfin náà sí ní ìlànà ẹ̀sìn Musulumi

Oríṣun àwòrán, @GiwaMoore
Awaye ku ko sin, ọrun ma kanju, gbogbo wa la n bọ.
Irọlẹ ọjọ ni wọn fi ilẹ bo oku asofin Tunde Braimoh ni asiri nilu Eko ni deedee aago meji ọsan.
Itẹ oku Vault Garden, to wa ni Awoyaya lẹba Mayfair Garden ni adugbo Lekki nilu Eko ni wọn sin asofin Braimoh si.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ ẹbi, ọrẹ, ojulumọ ati alajọse nidi oselu lo ti peju sile rẹ lati daro iku rẹ, amọ ẹtahoro wọn lo bawọn peju sibi ti wọn ti sin oku rẹ.
Eyi ko si sẹyin ofin tita kete sira ẹni to wa nita, awọn to si peju sin asofin naa ko pe mẹwa niye.

Oríṣun àwòrán, @Toosaino
Awọn abanikẹdun ti yabo ile Tunde Braimoh, aṣofin ipinlẹ Eko to jade laye lowurọ ọjọ Ẹti.
Abẹwo BBC Yoruba sile oloogbe ṣafihan awọn ololufẹ rẹ, to n sọrọ tẹdun-tẹdun pe alaanu kan ṣoṣo to ku fun awọn ni wọn fi da wọn loro.
- Ó ṣeéṣe kí ènìyàn 12,000 máa kú lójoojúmọ́ lẹ́yìn Covid-19
- Orílẹ̀-èdè mẹ́wàá tí ẹgbẹ́ alákatakítí Islamic State n fínna mọ́ ní àgbáyé
- N kò gba ₦4bn lọ́wọ́ Magu, ẹ má ró àjẹbánu mọ́ mi láṣọ - Osinbajo pariwo
- Mi ò tíì gba ìwé ìfitónilétí pé wọ́n fẹ́ yọ mí nípò igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo- Agboola Ajayi
Bo tilẹ jẹ pe a ko le fidi iru iku to pa oloogbe ọhun mulẹ, amọ o ta si akọroyin BBC Yoruba l'eti pe, ibudo itọju alarun Coronavirus to wa ni adugbo Yaba, ni Braimoh ku si.

Ko ti i pe oṣu kan ti aṣofin to n ṣoju ẹkun idibo Kosofe, nile aṣofin agba Naijiria, Bayo Osinowo jade laye.
Asofin Braimoh lo n soju ẹkun idibo Kosofe keji nile asofin ipinlẹ Eko.

Bakan naa ni asofin Buraimoh ti se alaga ijọba ibilẹ Kosofe ri, to si tun jẹ aṣoju ṣofin fagbegbe Ketu.
Ni nnkan bi oṣu meji si asiko yii, ni Braimoh ko ba pe ẹni ọgọta ọdun loke eepẹ.

Koda ninu awọn to ṣeto isinku, to si gbalejo Gomina Eko, Babajide Sanwoolu nile aṣofin agba, Adebayo Osinowo ta mọ si Pepperito, lasiko to jade laye ni Braimoh wa.
Eyi lo mu ki awọn kan ma sọ pe, o ṣeeṣe ki o ti ko arun Covid-19 ṣugbọn a ko ti fidi ọrọ yi mulẹ.

Oríṣun àwòrán, Other
Gẹgẹ bi mọlẹbi rẹ kan to fi idi isẹlẹ naa mulẹ ti wi, idaji aarọ ọjọ Ẹti oni ni asofin naa tẹri gbasọ, ko si tii si ẹni to lee fi idi ohun to ṣokunfa iku rẹ mulẹ.
Alaga agbegbe idagbasoke Ikosi Isheri nilu Eko, Ọmọọba Samiat Abolade Bada ti wa n daro iku rẹ eyi to n fi idi iku oloogbe naa mulẹ fun ọpọ eeyan.













