Mohammed Umar: Ta ni ọ̀gá àgbà tuntun fún EFCC?

Oríṣun àwòrán, Others
Mohammed Umar ni ijọba Naijiria yan gẹgẹ bi oludari ti yoo ma ṣakoso gbogbo eto ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu,EFCC ni Naijiria.
Mohammed Umar jẹ ọga ti o gaju lọ ni ipo to tẹle Ibrahim Magu, ti ijọba ni ko lọ rọọkun nile, lori ẹsun pe o ṣe owo kumọkumọ ati awọn ẹsun miran ti wọn fi kan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bayii ti wọn ti ni ki Umar Abba maa dari eto ajọ naa, ibeere tawọn eeyan n beere ni pe ta ni Umar Abba jẹ?
Ta ni Mohammed Umar:
Ṣaaju ki wọn to yan sipo, Umar Abba jẹ igbakeji Kọmisana ọlọpaa to si tun jẹ oludari gbogbo eto ni ajọ EFCC.
Ọmọ ilu Kano ni Umar Abba jẹ ohun si ni yoo ma dari EFCC titi ti Minisita feto idajọ Abubakar Malami yoo fi kede adele alaga ajọ naa
A ko tiribi fidi ọrọ mulẹ lori ọdun ti wọn bi Umar tabi ileẹkọ to ti kẹkọ jade ṣugbọn lọpọ igba lo ti lọ ṣoju adele alaga Magu lawọn aaye to ba ni ko ṣoju ohun.

Oríṣun àwòrán, Others
Lọdun to kọja, oun lo lọ ṣoju Magu nibi ti ajọ EFCC ati ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ FBI ti n ba awọn akọroyin sọrọ nilu Ekonibi ti wọn ti jabọ iye owo ti wọn ri gba pada lọwọ awọn gbajuẹ.
Bakan naa mi Umar lewaju ninu bi ajọ EFCC ti ṣe n tọ pinpin aarẹ ile aṣofin agba Naijiria tẹlẹ Bukola Saraki.
- Ó ṣeéṣe kí ènìyàn 12,000 máa kú lójoojúmọ́ lẹ́yìn Covid-19
- Orílẹ̀-èdè mẹ́wàá tí ẹgbẹ́ alákatakítí Islamic State n fínna mọ́ ní àgbáyé
- N kò gba ₦4bn lọ́wọ́ Magu, ẹ má ró àjẹbánu mọ́ mi láṣọ - Osinbajo pariwo
- Mi ò tíì gba ìwé ìfitónilétí pé wọ́n fẹ́ yọ mí nípò igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo- Agboola Ajayi
Ohun lo buwọlu iwe aṣẹ ti wọn fi beere iwe ẹri to fi mọ awọn iwe adehun iṣẹ kọngila gbogbo ti Bukola Saraki fọwọ si nigba ti o wa ni Gomina.
Wọ́n ti kéde Mohammed Umar gẹ́gẹ́ bí alága fìdíhẹ àjọ EFCC

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ijọba apapọ ti kede Mohammed Umar gẹgẹ bi alaga fidi hẹ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijria, EFCC.
Umar ni yoo ma tukọ ajọ ọhun lẹyin ti wọn jawe lọ gbele ẹ fun Ibrahim Magu, to jẹ alaga ajọ naa tẹlẹ.
Gẹgẹ bi eto ajọ naa ṣe ri, ipo Umar to wa ni ipo adari ẹka iṣẹ ninu ajọ ọhun lo tẹle alaga.
Atẹjade kan ti Ọmọwe Umar Jibrilu Gwandu, tii se igbakeji osisẹ alarena, nileesẹ agbẹjọro agba ati Minisita feto idajọ ilẹ wa fọwọ si lo kede iyansipo tuntun naa.
Bakan naa ni atẹjade ọhun tun kede pe, aarẹ orilẹede yii, Muhammadu Buhari ti fọwọ si pe ki adele alaga tẹlẹ fun ajọ EFCC, Ibrahim Magu lọ rọọkun nile na.
Ọjọ Aje, ọjọ Kẹfa oṣu Keje ọdun 2020 ni wọn fi panpẹ ofin mu Magu, ti wọn si gbe e lọ si ile aarẹ ni Abuja nibi ti igbimọ kan ti aarẹ gbe kalẹ ti fọrọ wa lẹnu wo.
Ayo Salami, to ti fi igba kan jẹ aarẹ ile ẹjọ kotẹmilọrun lo dari igbimọ oluwadii naa.

Oríṣun àwòrán, Instagram/officialefcc
Magu wọjọgbọn lẹyin ti adajọ agba Naijiria, Abubakar Malami kọwe mọ ọ lori awọn aṣemaṣe kan.
Wọn fẹsun kan Magu pe na owo ti ajọ ọhun rigba pada lọwọ awọn to lu owo ilu ni ponpo, o si tun lu awọn ohun ini jọba kan ni gbanjo fun awọn eeyan kan to sun mọ ọ.
Wọn tun ni o kọ lati jọwọ ara rẹ sabẹ iṣakoso ọfiisi adajọ agba ilẹ Naijiria.












