Coronavirus: Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì Nàíjíríà ṣe ẹ̀rọ àyẹ̀wò àrùn jáde

Olutọju alarun Coronavirus

Idunnu ti sibu lu ayọ ni orilẹede Naijiria nitori ijọba ti kede pe agbega yoo ba eto ayẹwo awọn eeyan to seese ko ni arun Coronavirus lara.

Aseyori nla si leyi fun ijọba Muhammadu Buhari nidi gbigbe ogun ti itankalẹ arun Coronavirus.

Agbẹnusọ fun aarẹ Buhari lori eto iroyin, Bashir Ahmad lo kede aseyọri nla yii loju opo Twitter rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Shehu ni "Orilẹede Naijiri ti n se ohun eelo ayẹwo arun Coronavirus, ta mọ si Testing Kits funra rẹ, eyi tawọn onimọ isegun oyinbo labẹle se jade.

Shehu fikun pe, ko si aniani pe aseyọri nla naa yoo mu ilọsiwaju ba eto ayẹwo fawọn araalu, lati mọ awọn ti ina arun Coronavirus ti bọ si abẹ asọ wọn.

Àkọlé fídíò, Coronavirus in Nigeria: Ìwádìí fihàn pé ọ̀pọ̀ aráàlú ni kò gbà pé àrùn Covid-19 wà

Ẹgbẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi kéde àdúrà nítórí àrùn Coronavirus

Awọn ọmọ ijọ kan n gbadura

Oríṣun àwòrán, Rccg

Saaju la ti sọ fun yin pe ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria, CAN ti dari awọn ile ijọsin, lati ya ọjọ kejilelogun ati ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹta sọtọ fun adura nitori arun Coronavirus.

Alaga CAN, Alufa Samson Ayokunle parọwa si ijọ lati tẹlẹ amọran ti awọn eleto ilera gbe kalẹ lọna ati dena itankalẹ arun naa ni bi wọn ṣe n gbadura.

O ni ijọba ko tii fi to ẹgbẹ ọhun leti pe o ti wọgile ijọsin ti eeyan rẹ ju aadọta lọ.

Lẹyin naa lo rọ awọn ile ijọsin lati gunle isin olojule ti awọn eeyan ti yoo wa nibẹ ko ni pọ ju boṣeyẹ lọ, tabi ki wọn maa ṣe isin lati ori itakun agbaye ti awọn ọmọ ijọ le darapọ mọ lati ile wọn.

O tẹsiwaju pe ijọ tun le pin isin si isọri ti eeyan ti yoo wa ni isọri kan ko ni pọ ju aadọta lọ.

Ẹgbẹ CAN tun wa rọ awọn ijọ lati pese ọṣẹ ati omi si ile ijọsin wọn fun imọtoto awọn eeyan, ati pe ki wọn gbiyanju lati jina diẹ si ẹnikẹni to ba n sin, tabi wukọ.

Lati igba ti arun Coronavirus ti bẹ silẹ lorilẹ-ede China lọdun 2019, arun naa ti tan de o orilẹ-ede to le lọgọrun un, eyi si ti mu kin wọn wọgile oriṣiriṣi apero ati ipade kaakiri agabye.

Àkọlé fídíò, Làá hàn mí: Ètò yìí ló ń kìlọ̀ fún wa láti mú ìmọ́tótó ní pàtàkì láti dènà Coronavirus