Fuel Reduction: Awọn ọmọ Naijiria ni muri kan ti kéré ju láti yọ nínú jálá epo
Aṣẹ ti ijọba apapọ orilẹede Naijiria pa lori adinku jala epo bẹntiro si naira marundinlaadoje(125) ko tii fi bẹẹ fẹsẹmulẹ ni ilu Ibadan tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ọyọ.
Abẹwo ti ikọ iroyin BBC Yoruba ṣe si awọn ile epo kan to n bẹ nilu Ibadan lowuro Ọjọbọ lo fi idi ọrọ mulẹ.
Ohun ti pupọ ninu awọn onile epo sọ ni wipe awọn onimọẹrọ yoo nilo lati yi iye ti wọn n ta epo pada lori awọn ẹrọ ti wọn fi n ta epo ki o to di wi pe awọn onibara wọn yoo lanfani lati maa raa ni iye ti ijọba apapọ kede rẹ.Ile itaja epọ NNPC ti o jẹ ti ijọba apapọ orilẹede yii ni akọkọ ṣe abẹwo si ni agbegbe Ajanla ati opopona marọsẹ Ọjọọ nilu Ibadan.
- Ìyá ọmọ tó sọnú níléèjọ́sìn l'Akure bú sẹ́kún nílé ẹjọ
- Báwo ni o ṣe le mọ̀ pé o ní àrùn Coronavirus?
- Ṣé Makinde kò wá rugi oyin báyìí lórí ìpàdé ìtagbangba PDP tó ṣe níbàdàn Láì náání àjàkálẹ̀ àrùn coronavirus?
- Wo ohun tó mú kí Ṣèyí Makinde ó tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìpàdé ìtagbangba níbàdàn láàrín ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn Coronavirus
Naira marundinlaadoje ni wọn n ta epo nibẹ lẹyin ti awọn amojuẹrọ ti yi iye ti wọn ta jala epo kuro ni naira marundinlaadọjọ ti o wa tẹlẹ.Ṣugbọn ọpọ awọn onile itaja epo ti o jẹ aladani ni ko tii bẹrẹ si ni ta epo, ti awọn kan si n taa ni naira marundinladọjọ ti o wa tẹlẹ. Alaye wọn ni wi pe o di igba ti awọn amoju ẹrọ ba yii iye ti wọn n ta epo pada lori ẹrọ ki awọn onibara to ni anfani lati raa ni naira marundilaadoje.Awọn ọlọkọ ero ati ọlọkada to ba wa sọrọ ṣe alaye wi pe aṣẹ ti ijọba pa ko tii fi bẹẹ fi ẹsẹ mulẹ nitori naira marundinlaadọjọ ṣi ni awọn onile epo kan n taa, bẹẹ sini awọn kan gbe ilẹkun ile itaja epo wọn ti pa.
Coronavirus: Èyí ni ipa tí àdínkù owó epo bẹtiró yóò mú bá ọ̀rọ̀ ajé Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari ti buwọlu u pe ki adinku ba owo epo bẹtiro nitori bi owo eporọọbi ṣe ja walẹ l'agbaye.
Ninu atẹjade kan ti Minisita fun alumọọni eporọọbi, fi sita, o sọ pe owo eporọọbi ti ja walẹ kọja nkan to yẹ ko jẹ fun tita epo bẹtiro ti wọn gbe wọle.
Nitori eyi si ni aarẹ Naijiria ṣe paṣẹ pe ki wọn o din iye ti wọn n ta jaala epo ku.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ni bayii, naira marundinlaadoje ni wọn yoo maa ta jaala epo bẹtiro kan.
Itankalẹ ajakalẹ arun coronavirus ti mu ki okuta o ba ọja eporsbi l'agbaye. Dọla mọkandinlọgbọn ni wọn n ta agba eporọbi kan bayii, dipo ọgọta Dọla to jẹ l'oṣu Kejila.
O ṣeeṣe ki adinku to ba owo eporọbi ṣe akoba fun ọrọ aje Naijiria, nitori pe iye ti wọn n ta eporọbi tẹlẹ ni ijọba fi ṣiro owo iṣuna fun ọdun 2020.
Ko tan sibẹ o, owo eporọbi naa le ma duro soju kan, o tun ṣi le ja walẹ si.
Ọdun 2016 ni wọn ti n ta jaala epo bẹtori kan ni naira marundinlaadọjọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Minisita keji fun alumọni eporọbi, Timipre Silva sọ pe adinku naa da lori ọna ti wsn ti la kalẹ l'ọdun 2015 ṣaaju ki ijọba o to fi kun owo epo lọdun to tẹle.
Ohun ti eyi tumọ si nipe, ti owo eporọbi ba tun wọn si l'agbaye ki ọdun yii to o pari, ijọba yoo tun fi owo kun owo epo.
Ṣaaju asiko yii, ijọba Naijria ti pinnu lati ya owo to le ni biliọnu mejilelogun Dọla lati fi gbọ diẹ lara bukata iṣuna ọdun 2020. Ṣugbọn ile igbimọ aṣoju-ṣofin ti da igbesẹ naa duro.
Ko ti i fojuhan ibi ti ọrọ ọja eporọbi l'agbaye yoo ja ọrọ aje Naijriia si, paapa bi arun coronavirus ṣe n tan kiri.















