Coronavirus: Seyi Makinde ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọṣẹ apakòkòrò 'hand sanitiser' lòun fi dènà coronavirus nípàdé ẹgbẹ PDP ní'bàdàn

Gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Twitter/seyi makinde

Lati ọjọbọ ni ori ayelujara ti n ho ruru, ti ọpọ eniyan si n sọ oko ọrọ̀ si gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde, ati ẹgbẹ oṣelu PDP, lori ipade itangbangba ẹgbẹ naa to waye.

Ọpọ lo gbagbọ pe ko yẹ ki Gomian Makinde le pe iru ipade nla bẹ lasiko ti arun coronavirus n rin kaakiri ilu.

Ṣugbọn nigba to ba BBC sọrọ, Akọwe ikede fun gomina Makinde, Taiwo Adisa sọ pe gbogbo igbesẹ to yẹ ni awọn gbe nibi ipade naa ni ibamu pẹlu imọran awọn eleto ilera.

Àkọlé fídíò, Elebuibon: Àwọn àṣà àtọ̀húnrìnwá ló fa títa ẹ̀jẹ̀ nítorí ògùn owo

O ṣalaye pe gbogbo awọn to wa sibi ipade itagbangba naa ni awọn fun ni ọṣẹ apakokoro (hand sanitiser) l'ẹnu ọna abawọle sibi ipade.

"A pa di dandan fun gbogbo olukopa lati fọ ọwọ wọn l'ẹnu ọna, ati lati fi ọṣẹ apakokoro pa ọwọ ki wọn o to o wọle, lai yọ ẹnikẹni silẹ.

Ti mo ba ni kin sọ iye ọṣẹ ti a ra, yoo to ẹgbẹrun mẹwa. Nitori pe iye ti a ra pọ ju iye eniyan to wa si ipade.

O tẹsiwaju lati sọ pe awọn ṣe ayẹwo ilera fun gbogbo awọn to gba papakọ ọkọ ofurufu wọle.

Lori ọrọ ti ijọba ipinlẹ Ekiti sọ pe awọn sọ fun ijọba ipinlẹ Ọyọ nipa ọmọ America to ku si ipinlẹ Ekiti, ati awọn ti wọn jọ wa si Ekiti, ti ọkan lara wọn si ti ni coronavirus, Adisa sọ pe ijọba Ekiti ko sọ fun ijọba Ọyọ tẹlẹ.

"Ọjọbọ ti ijọba Ekiti kede faye naa ni wọn sọ fun wa. Ao gbọ si tẹlẹ. Koda, wọn fi atẹjiṣẹ ṣọwọ sori foonu kọmisana eto ilera ipinlẹ Ọyọ."

O sọ pe ijọba ti lọ si ile ti wọn de si, wọn si ti fin oogun apakokoro sibẹ. Ati pe wọn ti n gbe igbesẹ si n lọ lọwọ lati mọ awọn to ba wọn ṣiṣẹ, bi itọju ile, aṣọ fifọ lasiko ti wọn fi wa nilu ibadan l'agbegbe Bodija.