Coronavirus: Ìjọ kò ní tilẹ̀kùn ilé ìjọsìn nítorí Coronavirus - Ondo PFN

Oríṣun àwòrán, RCCG
Alaga ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi ti ijọ igbalode PFN ni ipinlẹ Ondo, Joshua Kolawole Opayinka ti sọ pe, ijọ ko ni gbe kọkọrọ sẹnu ile ijọsin nitori arun Coronavirus.
Biṣọbu ọhun sọ fun BBC Yoruba pe adura nikan ṣoṣo lo le dẹkun arun Coronavirus, kiiṣe titi ile ijọsin pa.
O ni "A ko le sọ pe ka ti ile ijọsin nitori Coronavirus, nitori ori bibẹ kọ ni ogun ori fifọ."
Opayinka sọ pe Ọlọrun mọ si gbogbo ohun to n ṣelẹ patapata, ati pe Ọlọrun nikan lo le yanju gbogbgo iṣorọ ati aisan to ba n ba aye finra lọwọ yii.
Aṣoju PFN naa sọ pe ohun to yẹ ki awọn ọmọlẹyin Kristi ṣe ni pe ki wọn gbohun adura soke ju ti atẹyinwa lọ.
Alufa naa tẹsiwaju pe Ọlọrun lo le aisan Ebola lọ, nitori naa Ọlọrun nikan naa lo le ṣegu arun Coronavirus.
- Àwọn ọba Yorùbá kan rèé tí wọ́n rọ̀ lóyè, tí ọba míràn jẹ lójú ayé wọn
- Bí Fayemi bá tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀, àwọn oníbáwí rẹ̀ wà l'Ekiti-Peter Fatomilọla
- Coronavirus: Wo ohun tí o ní láti ṣe láti dáàbò bo ara rẹ
- Wọ́n gbé òkú ọgá iléẹ̀kọ́ àti òṣìṣẹ́ méjì míì tó kú nínú ìbúgbàmù lọ sílé ìgbókùsí ológun ojú omi l‘Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nipa pe ọna ti ajakalẹ arun fi n tan kalẹ ni kikorajọ ọpọ eeyan, o ni ẹmi eṣu ko le raye laarin awọn ọmọ Ọlọrun.
Opayinka sọ pe "Ẹmi eṣu to n kaakiri ninu afẹfẹ ni Coronavirus, ti ẹni to ba ni arun ọhun ba ti n wọle sinu ile ijọsin, ẹmi naa ko ni ba wọle.
"Ti eeyan ba wọle sinu ile ijọsin pẹlu ẹmi naa, ẹmi naa ko ba iru ẹni bẹ jade, bẹẹni ko ni ko arun naa ran elomiran."
Nigba to n sọrọ lori pe ti ijọba ba paṣẹ pe ki wọn ti awọn ile ijọsin, Opayinka sọ pe ijọ yoo tẹlẹ aṣẹ ti ijọba ba pa lori arun naa.
Opayinka rọ ijọba ni ipari ọrọ rẹ pe, ko ma gbe agadagodo ṣenu ọna ile ijọsin latari arun Coronavirus nitori ijọ nikan ṣoṣo ni ọna abayọ si araun naa to n tan kaakiri agabaye.













