Lagos Explosion: Ohun tí a mọ̀ tó fa ìgbúgbàmù Eko rèé, ọ̀rọ̀ rèé lẹ́nu ó ṣojú mi kòró

Abule-Ado

Oríṣun àwòrán, others

Ọpọ awuyewuye lo ti n waye lori ohun to fa Ibugbamu to ṣelẹ lọjọ Isinmi, ọjọ karundinlogun, Oṣu Kẹta ọdun 2020 lagbegbe Abule-Ado, nipinlẹ Eko.

Ijọba ipinlẹ Eko ti gbe igbimọ kan dide lati wa okodoro ohun to fa igbugbamu naa, gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu si ti ṣeleri pe oun yoo fi esi iwaadi naa lede.

Lẹyin ọjọ diẹ si ti isẹlẹ naa waye, awọn ibere ti ọpọ eeyan n bere bayii ni pe, kini ohun to ṣokunfa ibugbamu ọhun gan?

Ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye

Awọn ibi ti ibugbamu naa palara bẹrẹ lati agbegbe Adegbola Olujobi, titi de opopona Otunba Gani Adams ni Abule-Ado.

O jẹ agbegbe ti ọpọ eeyan n gbe, opa epo gba ibẹ kọja, ibẹ naa si ni ile iwe Bethlehem College wa, bakan naa ni ile epo NIPCO wa ladugbo ọhun pẹlu.

Abule-Ado

Oríṣun àwòrán, others

Ki ni ohun to ṣẹlẹ?

Gẹgẹ bi ọrọ ti awọn oṣoju mi koro sọ, ibugbamu naa waye laarin ago mẹjọ si mẹsan an owurọ ọjọ Isinmi.

Ọpọ awọn idile to n gbe agbegbe naa ti lọ si ile ijọsin lakoko naa, bẹẹ naa ni awọn akẹkọ ile iwe Bethlehem College naa ti wa ni ibi adura owurọ nigb ti iṣẹlẹ ọhun waye.

Ọkan lara awọn ti ọrọ ọhun ṣoju rẹ sọ fun BBC pe, ọna ile ijọsin ni oun wa fun adura owurọ nigba to oun gbọ orun gaasi.

Abule-Ado

Oríṣun àwòrán, @followlasema

O ni "Mo pinu lati lọ sọ fun alufaa ijọ nipa gaasi to n run, ṣugbọn ki n to de ẹnu ọna ile ijọsin naa, gaasi ọhun ti gba gbogbo agbegbe naa, to si to gbana lẹyin iṣẹju diẹ si."

Alaga ijọba ibilẹ Amuwo odofin, ọgbẹni Valentine Buraimoh ba BBC sọrọ lẹyin wakati diẹ ti iṣẹlẹ ọhun waye, o ni ibugbamu ọhun waye nitori ọpa epo to fọ .

Ọkọ to bọ ha sinu gọta

Elomiran ti ọrọ ọhun ṣoju rẹ sọ pe ọkọ kan to bọ ha sinu gọta lo fa ṣababi ọpa epo to fọ.

Àkọlé fídíò, Coffee Painter: Adebukola ní kò sí ìrànwọ́ lẹ́yìn ẹ̀kọ́ girama lòun ṣe ń ya àwòrán

O ni lẹyin ti awakọ ọkọ akoyọyọ naa n gbiyanju ati wa ọkọ naa jade ninu gọta to bọ ha si lo fọ ọpa epo naa, ti gaasi inu rẹ si fọn sita.

Ọrọ ti ẹni naa sọ farajọ fidio kan to tan kalẹ loju opo Facebook, eyi to ṣafihan ọkọ akoyọyọ to wa lẹba ibi ti gaasi naa ti fọn jade.

Ibi ọrọ de duro

Awọn adola ẹmi ti sọ pe ogun eeyan lo ba iṣẹlẹ ọhun lọ ti awọn marundinlọgbọn si farapa.

Ileeṣẹ to n risi iṣẹlẹ pajawiri ipinlẹ EKo, LASEMA, ati ileeṣẹ ijọba apapọ to n risi iṣelẹ pajawiri, NEMA ti n ṣiṣẹ takuntakun lojukjo iṣẹlẹ ọhun lati ṣe iwaadi okodoro lori ibugbamu ọhun.

Àkọlé fídíò, Human Calculator: N kò lo idán àbí àlùpàyídà fún ìṣirò ọpọlọ tí mò ń ṣe