'A fẹ́ àyípadà sí ọjọ́ orí tí ọmọdé lè bẹ̀rẹ̀ ìbálòpọ̀ lábẹ́ òfin sí ọmọ ọdún 16 dípò 18'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, ìjọba kéde òfin tuntun láti mú àdínkù bá ìbálòpọ̀ láàárín àwọn ọmọdé ní orílẹ̀èdè India.
Ṣùgbọ́n bí òfin yìí lábẹ́ ohun tí ìjọbaorílẹ̀ èdè náà pè ní "Protection of Children from Sexual Offences (POCSO) Act" ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìwà ọ̀daràn ni ìbálòpọ̀ fún ẹni tí kò bà ì tíì pé ọmọ ọdún méjìdínlógún síbẹ̀ níṣe ni ìwà yìí ń pọ̀ si láàárín àwọn ọ̀dọ́.
Ní báyìí, ìpè ti ń wáyé ní orílẹ̀èdè India láti ṣe àgbéyẹ̀wò òfin yìí kì wọ́n sì mú àyípadà bá iye ọjọ́ orí tí àwọn ènìyàn ti lè bẹ̀rẹ̀ sí ní ìbálòpọ̀ láì tako òfin ìjọba.
Bákan náà ni àwọn ènìyàn ń fẹ́ kí ìjọba yí òfin náà padà nípa pé wọ́n kò ní ka ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò bá ì tíì pé ọmọ ọdún méjìdínlógún tó fi ní ìbálòpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn.
Ṣaájú àkókò yìí, ìròyìn ní ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tí àwọn òbí wọn bá lọ fẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá pé wọ́n fi ipá bá lò pọ̀ ni wọ́n máa ń jiyàn rẹ̀ wípé àwọn gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni kìí ṣe wí wọ́n fi ipá bá àwọn lò pọ̀.
Ìdí nìyí tí ìjọba fi gbé òfin POCSO kalẹ̀ nítorí bí ìbálòpọ̀ láàrín àwọn ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn kò ì tíì pé ọdún méjìdínlógún ṣe di tọ́rọ́ fọ́nká sílé.
Ìwádìí ìjọba India lọ́dún 2007 fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìdá mẹ́tàléláàdọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́ yìí ló ti kojú ìwà ipá nídìí ìbálòpọ̀.
Bẹ́ẹ̀ náà ni òfin yìí sún ọjọ́ orí tí àwọn ènìyàn ti lè ní ìbálòpọ̀ sí ọdún méjìdínlógún láti ọdún mẹ́rìndínlógún.
Òfin yìí kò sí ní ìbámu pẹ̀lú nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ - Àwọn ènìyàn
Àmọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èèwọ̀ ni láti ní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó ní India síbẹ̀ ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ní orílẹ̀èdè náà ló ń ní ìbálòpọ̀ ní èwe.
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí National Family Health Survey (NFHS-5) ṣe sọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin ló ní àwọn ti ń ní ìbálòpọ̀ kí àwọn tó pé ọmọ ọdún méjìdínlógún, tí àwọn mìíràn sì ní kí àwọn tó pé ọdún mẹ́ẹ̀dógún ni àwọn tí ń ní ìbálòpọ̀.
Ìdí nìyí tí àwọn ènìyàn fi ń bèèrè pé kí ìjọba yí òfin padà sí sísọ ọjọ́ orí tí ènìyàn ti lè bẹ̀rẹ̀ sí ní ìbálòpọ̀ di ọdún mẹ́rìndínlógún dípò ọdún méjìdínlógún tó wà báyìí.
Àwọn tó ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọdé ní àwọn òbí ń lo òfin láti fi dárí àwọn ọmọbìnrin bó ṣe wù wọ́n dípò kí wọ́n gbà wọ́n láyè láti ní ọ̀rẹ́kùnrin.
Àjọ yìí ní sísọ ìbálòpọ̀ tó wá láti ọkàn ènìyàn méjì di ìwà ọ̀daràn ń bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan jẹ́ síi ni.
Swagata Raha tó jẹ́ olórí àwọn aṣèwádìí Enfold ní òfin yìí kò bá ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lójú ayé mú rárá.















