Àwọn ọmọ ìyàwó Abiola, Kudirat, wọ́ Buhari lọ iléẹjọ́, wo nǹkan tí wọ́n bèrè fún

Aworan

Oríṣun àwòrán, @OGBENIOLAIDE

Awọn ọmọ oloogbe Kudirat Abiola, ọkan lara awọn iyawo gbajugbaja oloṣelu, MKO Abiola ti wọ ijọba aarẹ Muhammadu Buhari lọ si ileẹjọ ECOWAS niluu Abuja lori ẹsun pe wọn ṣekupa iya wọn ni ọna ti ko ba ofin mu.

Khafila Abiola, Moriam Abiola ati Hadi Abiola lo gbe igbesẹ pẹlu awọn ọmọ yooku.

Ninu iwe ti wọn fi pe Ijọba lẹjọ pẹlu nọmba idanimọ, ECW/CCJ/APP/62/2022, ti Femi Falana si jẹ agbẹjọro wọn, ni awọn ijọba tẹ oju iya awọn mọlẹ, ti wọn si tun faa asọ iyi ya mọ lara.

Bakan an iwe naa ni “bi orilẹede Naijria ṣe kuna lati dabo bo oloogbe Kudirat Abiola ni o lodi si ofin ikọlu eeyan mimu iwe ofin ile adulawọ.”

Ta ni Kudirat Abiola?

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Kudirat Abiola jẹ opo nla gidi nidi agbekalẹ eto isejọba alagbadada, a ko sile sọrọ June 12, ka yọ ipa to ko sẹyin nitori o fi ẹmi rẹ lelẹ fun ijọba alagbada ni.

Wọn bi Kudirat Olayinka Adeyemi ni ilu Zaria lọdun 1951, lati igba ọdọ rẹ lo ti n fi apẹrẹ akinkanju han.

Ijẹri ohun to ṣe ni ileewe girama. Muslim Girls High School lo soo di odidi alagbara obinrin pẹlu iṣẹ takuntakun to fi jẹ adari gbogbo ọmọ ile iwe ni kilaasi aṣekagba rẹ.

Ọmọ ọdun mọkanlelogun lo fẹ Oloye Moshood Abiola.

Alhaja Kudirat ni iyawo keji ti Abiola fẹ ṣugbọn oun ni iyale ninu awọn iyawo rẹ lasiko ti wọn pa a.

Ọmọ meje ni Kudirat bi fun ọkọ MKO Abiola - Yisau Olalekan, Hafsat Olaronke, Abdul Mumuni Khafila, Hadi, Moriam, Jamiu Abiodun ati Olalekan Yisau Abiola.