Elon Musk jábọ́ kúrò nípò ẹni tó lówó jù lágbáàyé; Wo olówó tuntun tí Forbes kéde

Oríṣun àwòrán, Reuters
Forbes ati Boomberg ti kede pe Elon Musk to jẹ oludari ileeṣẹ Twitter ko ki n ṣe ẹni to lo lowo julọ mọ ni agbaye lẹyin ipin idokoowo lori ọkọ ayọkẹlẹ, Tesla wa silẹ lọdun yii.
Gẹgẹ bii Forbes ati Bloomberg ṣe sọ, Bernard Arnault, to jẹ oludasilẹ ileeṣẹ LVMH ti bọ sori tabili gẹgẹ bii ẹni to lo lowo julọ lagbaye.
Musk ni ọga agba ati ẹni to ni ipin idokowo ju ni ileeṣẹ Tesla.
Forbes ni Musk bayii ni owo to to $178bn( £152bn), ti Bernard Arnault si ni$188bn.
Dan Ives lati ileeṣẹ Wedbush Securities ni bi Musk ṣe gba iṣakoso Twitter lo ṣe akoba fun un ninu ipin idokowo rẹ pẹlu Tesla.
O ni “Musk, oju ti wọn fi n wo o lori nigboro ni pe olowo ti ko lowo mọ, ohun to ṣelẹ si ni pe gbigba Twitter jẹ ohun to dun Musk, to si tun ṣe akoba fun ipin idokowo rẹ ni Tesla.











