Àwọn èèyàn tó sá kúrò nílé ṣàlàyé ìrírí wọn bí Israel ṣe fún wọn ní gbèdéke láti kúrò ní àríwá Gaza

Àwòrán bí àwọn ènìyàn ṣe ń sá kúrò nílé wọn

Oríṣun àwòrán, Reuters

    • Author, Ethar Shalaby
    • Role, BBC Arabic

Kò dín ní èèyàn méjìlá, tó fi mọ́ àwọn ọmọdé, tó pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìkọlù tó wáyé sí àwọn ọkọ̀ kan tó ń lọ síẹkùn gúúsù Gaza.

Ilé iṣẹ́ ètò ìlera orílẹ̀ èdè Palestine ti dẹ̀bi ìkọlù ọ̀hún ru orílẹ̀ èdè Israel, tí iléeṣẹ́ ètò ààbò Israel sì níàwọn ń ṣèwádìí ìkọlù náà.

Ìkọlù ọ̀hún ló ń wáyé lẹ́yìn gbèdéke tí Israel fún àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Palestine tó ń gbé ní àríwá Gaza láti fi kó kúrò níbẹ̀ kọjá.

Wọ́n ní kí àwọn ènìyàn tó lé ní mílíọ̀nù kan tó ń gbé agbègbè náà kó kúrò níbẹ̀, gba àwọn ọ̀nà méjì kan tí wọ́n kalẹ̀ ṣaájú kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ ìkọlù sí ikọ̀ ọmọ ogun Hamas.

Aṣẹ yii waye lẹyin ti eeyan to le ni 1,400 ọmọ Israel ku ninu ikọlu Hamas si Israel.

Lára àwọn ènìyàn tó ń gbé ẹkùn àríwá Gaza bá BBC sọ̀rọ̀ lórí àwọn nǹkan tí wọ́n kojú lẹ́yìn tí wọ́n fún wọn ní gbèdéke náà.

Awọn Abu Sharar tí ìyàwó rẹ̀, Haneen wà nínú oyún ní ó ṣeéṣe kí ìyàwó òun bí ọmọ ní ọjọ́ mélòó kan sí àsìkò yìí tó sì pọn dandan fún òun láti wá ilé ìwòsàn fún-un.

Bí ọkọ̀ ṣe pọ̀ lójú ọ̀nà ni àwọn ènìyàn náà ń fi ẹsẹ̀ rìn

Oríṣun àwòrán, EPA

Sharar, ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, tó tún jẹ́ agbẹjọ́rò ní òu kò fẹ́ kúrò ní ilé àwọn lẹ́yìn tí Israel pàṣẹ náà àmọ́ àwọn ẹbí padà tu àwọn láti kúrò nílé kí àwọn le móríbọ́ lọ́wọ́ ìkọlù Israel.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ó ní àwọn ti darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ará ìlú ló ti ń sa kúrò ní àríwá Gaza ati pé kò ju wàkátì kan lọ tí òun fi kó àwọn ẹrù tí àwọn máa nílò tí ìyàwó òun bá bímọ.

“Lọ́wọ́ kan ni a kúrò nílé wa láì ṣe wí pé a ní ibì kan tí a mórílé, kò sí ààbò níbì kankan, bẹ́ẹ̀ kò sí ètò kankan tí wọ́n ṣe fún wa.”

Ó ṣàlàyé pé ìlú Rfah ni àwọn wà báyìí ní gúúsù Gaza lọ́dọ̀ àwọn ẹbí kan tí wọ́n ń gba àwọn tó sa kúrò nílé wọn ní àlejò.

Ó fi ku pé ìdí tí àwọn fi lọ sí Rafah ni pé àwọn gbọ́ pé ilé ìwòsàn tí wọ́n ti ń gbẹ̀bí kan tó dára wà níbẹ̀.

Ìlú ti Israel pàṣẹ pé kí àwọn ènìyàn kó kúrò níbẹ̀ ni àwọn ènìyàn pọ̀sí jùlọ ní agbègbè Gaza Strip.

Gbogbo àwọn tó tikó kúrò ní ilé wọn báyìí ni wọ́n gbọ́kànlé àwọn ọ̀rẹ́, ẹbí àtàwọn àjòjì tó ń gbé ní gúúsù Gaza láti lọ fara pamọ́ síbẹ̀ fún ìgbà kan ná.

Woroud al-Dahdouh jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún tó sì tún jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́, ó fi ìlú Gaza sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹbí rẹ̀ méje, tí wọ́n sì ti wà ní ìlú kan ní gúúsù Gaza, al-Balah.

Woroud ní ilé kan tí àwọn tí àwọn ń gbé níbẹ̀ ti lé lógún báyìí ni àwọn wà báyìí àti pé àwọn kò ti ẹ̀ rí àga fi jokòó mọ́ ní ilé tí àwọn wà.

Ó ní níṣe ni òun ń wa ẹkún mu bíi gaàrí bí àwọn ṣe ń kúrò ní ilé àwọn àti pé òun kò lè sọ bí ó ṣe rí lára òun pé àwọn fi ilé àwọn sílẹ̀ lọ sí ibi tí àwọn kò mọ̀.

“A kàn kúrò ílé kíákíá ni, a ò mú ohunkóhun ju ìwé ìrìnnà wa lọ, bákan náà ni mo mú àwòrán ẹbí wa kan lọ́wọ́ fún ìràntí.” Woroud sọ èyí bó ṣe ń sunkún.

Ìyá Woroud, Nagah ní àwọn kò mọ àwọn tí wọ́n gba àwọn sílé rí rárá àmọ́ òun dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn fún ààyè tí wọ́n fi gba òun àtàwọn ẹbí òun.

Ìwé tí Israel fi sọ fún àwọn ènìyàn láti kúrò nílé wọn

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ṣaájú ni ikọ̀ ọmọ ogún Hamas ti sọ fún àwọn ènìyàn láti má kò ó kúrò nílé wọn, tí àwọn èèyàn ṣì wà ní àríwá Gaza báyìí.

Maysoon al-Batsh ní òun kò ní kó kúrò ní ilé àwọn nítorí kò sí ibi tí òun fẹ́ lọ ní gúúsù Gaza àti pé kò sí ibi tí ààbò tó péye wà.

Ó ní ó tẹ́ òun lọ́rùn láti ú sílé àwọn ju kí òun kúrò nílé lọ.

Ṣaájú ni àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ìyẹn United Nations ti ṣèkìlọ̀ pé lílé àwọn ènìyàn tó lé ní mílíọ̀nù kan kúrò nílé wọn lọ́jọ́ kan ṣoṣo jẹ́ ohun tí kò le ṣeéṣe àti pé ó máa ṣàkóbá ńlá fún àwọn ènìyàn.

Ọ̀nà kan ṣoṣo ló so àríwá àti gúúsù Gaza pọ̀, kò sí epo, kò sí omi tó bẹ́ẹ̀ gẹ́.

Gbogbo ọkọ̀ tí àwọn èèyàn ń rí ni wọ́n ń wọ̀ kúrò nílé

Oríṣun àwòrán, EPA

Àjọ UN tó wà fún àwọn àtìpó ní Palestine ni gbogbo ilé àwọn àti ilé ẹ̀kọ́ ló ti kún pátápátá.

Bákan náà ni àjọ ètò ìlera àgbáyé, World Health Organization ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ Israel láti ní kí àwọn ènìyàn kúrò nílé wọn, pé ọ̀pọ̀ nínú wọn ló nílò ètò ìlera.

Agbẹnusọ WHO, Tarik Jasarevic ní bí ìgbà tí èèyàn dájọ́ ikú fún àwọn ènìyàn náà ni ìgbésẹ̀ láti lé wọn kúrò nílé wọn láàárín àsìkò péréte yìí.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Palestine ló ti ń wá ọkọ̀ tí wọ́n fi máa kó ara wọn kúrò ní àríwá Gaza tó fi mọ́ àwọn 500 tó ń ṣe àtìpó ní ilé ìjọsìn Aguda kan ṣoṣo tó wà ní Gaza.

Àlùfáà ìjọ náà, Gabriel Romanelli sọ fún BBC pé ìṣòro ńlá ló jẹ́ fún àwọn láti rí ọks tí yóò kó àwọn ènìyàn náà kúrò.

Ẹ̀wẹ̀, akọ̀wé ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Anthony Blinken ti ṣèkìlọ̀ fún fún Israel láti tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́, kí wọ́n rí dájú pé àwọn kò mú ẹ̀mí àwọn ará ìlú lọ.

Ènìyàn 1,300 ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn ní Israel lẹ́yìn tí ikọ̀ Hamas bẹ̀rẹ̀ ìkọlù sí wọn ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá.

Bákan náà ni ènìyàn tó ti kú ní Palestine ti lé ní 2,200 lẹ́yìn tí ìkọlù náà bẹ̀rẹ̀.

Additional reporting by Ricardo Senra (BBC News Brasil)