Àwọn ìdí tí Hamas ṣe kọlu Israel rèé

Oríṣun àwòrán, AFP
Ikọlu ti awọn ikọ ọmọ ogun Palestine ṣe si Israel lọjọ keje, oṣu Kẹwaa yii jẹ eyi to jẹ airotẹlẹ.
Ojiji ni eyi si ṣẹlẹ lai ṣe ikilọ rara, nitori to jẹ ipaya to ti n ṣẹlẹ laaarin ilẹ Israel ati Palestine lati ọjọ to ti pẹ sẹyin.
Awọn Hamas sọ pe ọpọ nnkan lo fa a ti awọn fi ṣagbatẹru ikọlu naa - mẹrin ninu rẹ ni a a maa ṣe agbeyẹwo rẹ.
Gaza
Gaza jẹ agbegbe to gun ni iwọn kilomita mọkanlelogoji (41km), to si tun fẹ ni iwọn kilomita mẹwaa (10km), laarin orilẹede Israel, orilẹede Egypt ati agbegbe agbami okun Mediterranean.
Eeyan to le diẹ ni miliọnu meji lo n gbe ni Gaza.
O wa lara ilẹ ati agbegbe ti Palestine n ṣakoso rẹ.
Gẹgẹ bi ajọ agbaye UN ṣe sọ, ida ọgọrin awọn ara Gaza lo jẹ pe nipa iranlọwọ ilu to wa lagbaye ni wọn fi n gbe, to si jẹ pe ounjẹ ti awọn to le ni miliọnu wọn n jẹ lojoojumọ lo n wa lati ita fun wọn.
Eyi lo tumọ si pe pupọ awọn to n gbe nibẹ lo jẹ pe iṣoro ni igbe aye jẹ fun wọn nibẹ.
Gẹgẹ bi iwadii ajọ agbaye ṣe fidi rẹ mulẹ lọdun 2021, o kere tan, wakati mẹtala ni wọn fi n lo ina mọnamọna lojumọ.
Bakan naa, ajọ eleto ilera agbaye, WHO sọ pe, o kere tan, eeyan kan ṣoṣo nilo omi ti ko din ni ọgọrun lita lati mu, lati wẹ ati lati dana lojumọ kan.
Ni ilẹ Gaza, omi ti n eeyan kan n ri lo jẹ lita mejidinlaadọrun-un.

Iwadii fidi rẹ mulẹ pe ilẹ Israel lo ṣakoso agbegbe afẹfẹ wọn, to si n jẹ pe awọn lo n ṣakoso ẹni tabi nnkan to le wọle sibẹ lati awọn agbegbe ẹnu ibode wọn.
Bakan naa lo jẹ pe awọn ara Egypt ni wọn n ṣakoso awọn to le wọle si Gaza lati ẹnu ibode wọn.
Ohun ti wọn n jiya rẹ ni pe o ṣe pataki fun eto aabo wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lonii, ninu ikọlu to waye ni opin ọsẹ to kọja, ijọba Israel kede sita wi pe awọn ti gbe ìdótì le ilẹ Gaza, leyi ti wọn ko nii gba ounjẹ, omi, epo rọbi ati awọn ohun eelo miiran laaye lati wọle sibẹ.
Lati ọdun 2007 ni a gbọ pe awọn Hamas ti n ṣakoso Gaza, nigba ti ikọ ologun ẹlẹsin musulumi kan ti wọn fi ara jin fun ijọba Palestine igba naa lati gbe wahala dide.
Mọṣalaṣi Al-Aqsa
Pupọ awọn nkan lo n fa ipaya laarin awọn ara Israel ati awọn ara Palestine ju tu mọṣalaaṣi al-Aqsa to wa ni Jerusalem lọ.
Mọṣlaaṣi naa to wa lori oke jẹ eyi to wa ni ibi mimọ julọ ninu ẹsin Isilaamu, ṣugbọn bẹẹ naa lo tun jẹ ibi mimọ julọ fun awọn ara Jew, ibi ti wọn mọ si Temple Mount.
Ninu ohun kan ti wọn gbe jade lakoko ikọlu naa, Muhammad al-Deif, to jẹ olori ogun Hamas, ti ikọ al-Qassam (al-Qassam Brigade), sọ pe ikọlu naa jẹ eyi ti wọn fi gbẹsan ohun ti wọn pe ni ogun ojoojumọ si ilẹ al-Aqsa eyi ti awọn ara Israel fi n bu ẹnu atẹ lu ojiṣẹ wọn ni mọṣalaaṣi al-Aqsa.
Ni ọdun diẹ sẹyin, awọn agbaagba ẹlẹsin nilẹ Israel ti ṣabẹwo si inu ọgba naa, ẹyi to n kọ awọn ara Palestine lominu.
Agbegbe naa tun ti jẹ ibi ti awọn ẹlẹsin Palestine ati ẹṣọ ogun ilẹ Israel ti n wọya ija.
Ninu oṣu kẹrin, awọn ọlọpaa yabo mọṣalaaṣi naa pẹlu awọn eroja ogun bii ọta ibọn oni rọba ati ohun ija girẹneedi, lẹyin ijakadi to ṣẹlẹ lori ọrọ ẹsin.
L’ọdun 2021, bi awọn ara Israel ṣe gbogun fun ọjọ mọkanla gbako, eyi da rogbodiyan silẹ laarin Israel ati Hamas.
Aṣoju Hamas niluu Lebanon, Osama Hamdan, sọ fun BBC kọminu lori erongba ijọba orilẹede Israel wi pe ayipada kankan le mu ewu dani.
Awọn alakoso ilẹ Israel sọ pe ohun to jẹ awọn logun julọ ni lati daabo bo awọn ẹlẹsin nibẹ, ki wọn si ni anfaani lati ṣe ẹsin wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileto awọn Jew
Lati igba ti Israel ti gba iṣakoso agbegbe yii lẹyin ogun ti wọn ja l’ọdun 1967, ni iye awọn ara Jew ti wọn wa ni agbegbe West Bank ti bẹrẹ sii le si i.
Ajọ agbaye ninu akọsilẹ wọn jẹ ko di mimọ awọn ara Jew ti ko din ni ẹgbẹrun ẹẹdẹgbẹrin (700,000) ni wọn gbe ni agbegbe yii l’ọdun 2022.
Bo tilẹ jẹ pe ajọ agbaye ati awọn orilẹede kan sọ pe agbegbe naa ko ba ofin mu labẹ ofin agbaye, sibẹ Israel tako ọrọ naa.
Gbogbo igba ni awọn iṣẹlẹ rogbodiyan to n jẹ kayeefi n waye lati ọdọ awọn ara Israel si awọn ara Palestine ti wọn n gbe ni West Bank, ti ajọ agbaye si sọ pe iṣẹlẹ to le ọgọrun iru ẹ lo n waye laarin oṣu kan.
Hamdan sọ pe eeyan ti ko din ni irinwo ni wọn ti le danu kuro lori ilẹ wọn latigba ti ọdun 2022 ti bẹrẹ.
Hamas ninu ọrọ rẹ ni, “awọn ara Israel n gbiyanju lati le awọn ara Palestine danu kuro ni West Bank.”

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọsẹpọ aarin Israel ati Arab
Orileede meji pere ti wọn jẹ Arab ni Israel n fi ọgbọn ba ṣe papọ, awọn naa si ni Egypt ati Jordan, lẹyin ti wọn tọwọ bọwe alaafia l’ọdun 1979 ati 1994.
Sibẹsibẹ, lati bi ọdun diẹ sẹyin bayii, o si ti fi aaye ajọsọ miran si orileede bii United Arab Emirates.
Ninu oṣu kẹsan-an, Ọmọọba ilẹ Saudi Arabia, Ọmọọba Mohammed bin Salman sọ fun tẹlifiṣan ilẹ Amẹrika, iyẹn Fox News wi pe lojoojumọ ni orileede wọn gbiyanju lati ni ajọṣepọ to dan mọnran pẹlu Israel.
Bo tilẹ jẹ pe Saudi Arabia ti figba kan ri sọ pe asọyepọ ti awọn ba ṣeyoo jẹ ki wọn da ipinlẹ Palestine silẹ, ṣugbọn ti Hamas tako ọrọ naa, pẹlu bi wọn ṣe sọ pe bi irẹpọ ba fi waye, yoo di dandan fun Israel lati fun Palstine ni awọn ohun ti wọn n fẹ.
Ninu ọrọ ti wọn gbe sọrọ amohunmaworan lọjọ keje, oṣu kẹwaa, Ismail Haniyeh, to jẹ olori Hamas, takọ igbimọ Arab ti wọn duro lori wi pe ki asọyepọ wa laarin awọn ara Jew.
O sọ ninu ọrọ rẹ pe “gbogbo ipawọpọ ati asọyepọ to ba waye ko le pana wahala to n ṣẹlẹ.”















