Ìdí réè tí CBN fí gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin lílò dọla láti fí kó ìrẹsì,sìmẹ́ǹtì àti ọjà 41 kan wọlé sí Nàìjíríà

Aworan awọn ọja ti CBN faaye silẹ lati fi owo dọla ko wọle

Oríṣun àwòrán, Getty

Banki apapọ orilẹede Naijiria, CBN ti gbesẹ kuro lori ofin ti wọn fi de fifun awọn oniṣowo to n ko awọn ọja mẹtalelologoji kan wọle lorilẹe NAijiria ni anfani si gbigba owo ile okere fun kiko awọn ọja naa wọle,

Ọdun 2015 ni CBN gbe igbesẹ yii lori awọn ọja naa ti wọn si ni pe ko si idi fun awọn oniṣowo lati maa ko awọn ọja naa wọle mọ nitori pe awn ohun ti awọn eeyan le maa gbin tabi ṣe labẹle ni wọn.

Awọn ọja naa ni Irẹsi, simẹnti, ẹkurọ, ẹran, nnkan ọsin, ọṣẹ iwẹ, atike ati awọn nnkan mii.

Sugbọn ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ banki apapọ NAijiria naa, Isa AbdulMunin buwọlu fun awọn akọroyin salaye pe wọn ti gbesẹ kuro lori ofin to dena awọn ọja naa.

“Ninu igbiyanju lati ri pe iye owo ọja ko wọn ju, ajọ CBN yoo ṣe afikun lilọ soke karakata ọja oke okun lorekore. Bi ọja naa ba ṣe gboro si, ajọ CBN yoo ma yọwọ diẹdiẹ.

”Awọn to n ko ọja ti a fofin de tẹlẹ ti wa ni anfani lati ra awọn ọja lati oke okun.

“Ajọ CBN ṣe eyi ni ilana to ba ofiin mu ati lati ri pe awọn olutaja tẹlẹ ilana ‘Willing Seller Principle,’”

Wọn fi kun pe awọn yoo tẹsiwaju lati ṣe igbelaruge iṣesi to bojumọ nidi karakata ati idokoowo ilẹ Naijiria ki gbogbo ipenija to n koju paṣiparọ Naira si dọla baa le di ohun igbagbe.

Amọ o, ki la wọn nkan to rọ mọ igbesẹ yi ati pe bawo ni yoo ṣe lapa lẹka ọrọ aje ati lara awọn ọmọ orileede Naijiria?

Boya ka kọkọ bẹrẹ pẹlu idi ipinnu yi fi yi pada lori fifun awọn olokoowo lanfaani ki wọn le ri dọla fi ra ọja wọle.

Aworan owo dola

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Idi ti ijọba fi kọkọ fofin de lilo dọla fi ko awọn ọja yi wọle

Banki Apapọ sọ pe kika awọn oniṣowo yi lọwọ ko lati ri dọla ra loju opo CBN mu ki wọn lọ si ọdọ awọn paṣiparọ bureau d change ti eleyi si mu ki iye awọn to n wa owo dọla pọ si ju ti tẹlẹ lọ.

Wọn ni igbesẹ yi mu ki dọla wọn lọja paṣiparọ awọn to n ṣe bureau di change.

Eredi ti CBN fi lawọn gbe igbesẹ yi ko ju pe wọn fẹ ki ohun gbogbo gunrege pẹlu paṣiparọ owo Naira si ti ilẹ okere dọla.

Wọn si lawọn fẹ ko ṣe pe ati ọlọja ati ẹni to n ra owo paṣiparọ yi ni yoo jijọ lẹnu lọrọ lori bi wọn yoo ṣe ma taa tabi ra owo laarin ara wọn.

Awọn idi miran naa tun wa ti wọn tori rẹ gbe igbesẹ yi.

Ara awọn idi mii ni pe banki apapọ fẹ ki owo apamọwọ ni ọja paṣiparọ pọ nilẹ.

Wọn ni bi owo apamọwọ ba ṣe n pọ si, bẹẹ naa ni awọn aiṣedeede to n waye laarin iye ti wọn n paarọ owo yi naa maa diku diẹdiẹ.

Ki ni igbesẹ yi yoo tunmọ si lẹka ọrọ aje Naijiria?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ohun kan to ṣe apataki ninu alaye taa gbọdọ ṣe ni pe nigba ti Cbn fofin de paṣiparọ owo dọla lati fi ra awọn ọja kan wọle wọn ni eleyi ko ṣe idiwọ fun kiko awọn ọja naa wọle.

Yala wọn sọ pe ibi tawọn oniṣowo yoo kan ti maa wa dọla lo yatọ si eleyi ti Cbn pese fawọn nkan mii.

Amọ a ri wi pe ọrọ yi ri bakan.

Idi si ni pe ijọba apapọ fofin de kiko awọn ọja kan wọle bi apẹrẹ irẹsi ati igi itayin taa mọ sii toothpick.

Labẹ ofin yi ti ijọba aarẹ Muhammadu Buhari fi lelẹ, erongba ijọba ni pe awọn yoo ṣe ikunpa fawọn agbẹ ki wọn baa le pese irẹ́si labẹle.

Eyi lo bi eto Anchor Borrowers fawọn agbẹ to n gbin irẹsi labẹle.

Eto yi ko mu iyipada ti ijọba gbero nitori kaka ki owo irẹsi walẹ niṣe lo n lọ soke si.

Amọ bayii ti wọn ti wa da anfaani rira dọla lati fi le ko irẹsi wọle, ohun to ku ni pe ki ijọba gbẹsẹ kuro lori ofin to de gbigbe irẹsi wọle bi bẹẹ kọ, awn oniṣowo to ba ri owo dọla gba lọdọ Cbn ko ni lanfaani lati ko irẹsi ilẹ okere wọle.

Erongba Cbn si ni pe gbigbe ẹsẹ kuro lori paṣiparọ dọla fawọn olokoowo yi yoo mu ki eto ọrọ aje burẹkẹ si ju ti tẹlẹ lọ.

Yoo si mu ki iye owo ti Naijiria fi n ṣe paṣiparọ pẹlu dọla walẹ ju ti tẹlẹ lọ.

Awọn ileeṣẹ to kogba sile ni paapa pẹlu awọn nkan mii to pẹlu awọn ọja ti olokoowo ko ri dọla fi gbe wọle tẹlẹ yoo wa ni ṣiṣi pada.

Awọn diẹ lara awọn ọja ti CBN gbesẹ kuro lori wọn

Irẹsi, Simẹti, Ororo, Ekurọ, Epo pupa, Ẹran, Ẹfọ, Ohun ọsin, Ẹja inu ogolo, Irin, Orule, ati Ohun ko ẹru oko

Awọn yooku apoti lonirin, ilu, ọpa irin, igi, gilaasi, ohun idana, sibi, asọ tabili, ile afẹfẹ gaasi, asọ, ike, Tomati, atike ati bẹẹlọ.