“Ìjọba àpapọ̀ ń parọ́ pé ìbò ààrẹ 2023 ló dára jú, ó burú ju òdo lọ - Onímọ̀ òṣèlú

Lẹyin ti ijọba apapọ sọ pe eto idibo Aarẹ Naijiria to kọja lo dara ju ninu itan ibo ni Aarẹ Naiiria, onwoye kan ti sọ pe irọ patapata ni ọrọ naa.
Dele Farotimi, to jẹ amofin ati ajafẹtọ ọmọniyan lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.
Ṣaaju ninu atẹjade kan ni agbẹnusọ Aarẹ Buhari, Garba Shehu ti sọ pe eto idibo naa yanranti, oun lo si koju oṣuwọn ju ninu gbogbo ibo Aarẹ to ti waye saaju ni Naijiria.
"Kii ṣe bi wọn ti n ṣe eto idibo, ni wọn ṣe ṣe idibo yẹn"
Garba Shehu fi kun pe esi ibo naa tẹ awọn eeyan lọrun, koda ijọba ilẹ Gẹesi gan ki ẹni to jawe olubori ku orrire, ati pe awọn to lulẹ nikan ni esi ibo ọhun ko dun mọ ninu.
Nigba to n da si ọrọ naa, Farotimi sọ pe “Ohun to wu Garba Shehu lo le fi ẹnu rẹ sọ.
Amọ gẹgẹ bii nnkan ti a fi oju wa ri, ti awọn araalu naa si ri pẹlu, kii ṣe bi wọn ti n ṣe eto idibo, ni wọn ṣe ṣe idibo yẹn.”
“Ojojumọ ni a n ke, ti a si n pariwo, Garba Shehu wa jade, o ni oju n dun gbogbo wa pe ibo aarẹ 2023 nikan lo dara ju.
Shehu ni awọn oludije aarẹ to lulẹ nikan lo n fapa janu, eyi n tumọ si pe awọn ọmọ Naijiria gan lo lulẹ.”
“Ohun to ba wu wọn ni wọn le sọ, amọ awa mọ ohun ti a fi oju wa ri o.”
"Ti wọn ba ni ki n fun idibo aarẹ ni maaki, o buru ju odo lọ”
Farotimi tẹsiwaju pe “Awọn ara oke okun, awọn to wa ni Naijiria, awa ti a ni eti ati oju, amọ pe irọ ni ohun ti Shehu sọ yẹn.
Amọ to ba ni bẹẹ lo ri o, mi o le ba jiyan.”
“Ti wọn ba ni ki n fun eto idibo naa ni maaki, o buru ju odo lọ.”
“Kii si ṣe pe awọn araalu ko dibo, wọn dibo, amọ ọtọ ni ibo ti a di, ọtọ ni esi ti a ri.”
“Kii ṣe pe INEC ko ka ibo wa o, ṣugbọn ohun to wu INEC lo fi ẹnu rẹ wi fun araye lẹyin eto idibo naa.”
Amofin naa pari ọrọ rẹ pe oun duro nibudo idibo oun lati ri pe oju oun ni wọn ka esi ibo naa.
Amọ o ni eyi jẹ iyalẹnu pe ọtọ ni esi ti INEC kede ati esi ti awọn fi oju wọn ri nibi ti wọn ti dibo.
CBN ti pàṣẹ fáwọn báǹkì láti gbà tàbí san Naira àtijọ́ fún aráàlú - Soludo

Oríṣun àwòrán, CBN
Gomina CBN nigba kan ri, Ọjọgbọn Charles Soludo ti fidi rẹ mulẹ pe banki apapọ Naijiria naa ti ke si awọn ile ifowopamọ lati maa san owo naira atijọ fun awọn araalu.
Soludo fikun pe wọn tun ti pasẹ fun awọn banki lati gba owo atijọ kan naa lọwọ awọn araalu.
Gomina CBN nigba kan ri naa lo fi ikede naa sita nin atẹjade kan loju opo Facebook rẹ.
O ṣalaye pe, gomina CBN lọwọlọwọ, Godwin Emfiele lo paṣẹ bẹẹ fawọn alaṣẹ ile ifowopamọ ninu ipade kan ti wọn ṣe lọjọ Isinimi.
O fi kun pe Emefiele funra rẹ lo sọ bẹẹ fun oun.
Atẹjade ọhun ni “CBN ti paṣẹ fun awọn banki lati maa san owo atijọ fawọn araalu, ati ki wọn tun maa gba owo atijọ kan naa lọwọ wọn.”
“Awọn oṣiṣẹ to n gba owo ni banki yoo maa fun awọn to ba fẹ san owo naa ni ‘code’ ti wọn yoo maa fi san owo wọle, wọn si le san owo ni aimoye igba...”

Oríṣun àwòrán, C. C. Soludo CFR
CBN lo pa ṣẹ yii nibi ipade igbimọ awọn ile ifowopamọ kan lọjọ Aiku - Soludo
“Gomina CBN lo pa ṣẹ yii nibi ipade igbimọ awọn ile ifowopamọ kan lọjọ Aiku, ọjọ kejila, oṣu Kẹta, ọdun 2023 yii.”
“Emefiel funra re tun sọrọ naa fun mi lori ẹrọ ilewọ lalẹ ọjọ Aiku kan naa.”
Lẹyin naa lo rọ awọn eeyan ipinlẹ Amambra to jẹ gomina rẹ lati maa gba ₦200, ₦500 ati ₦1000 atijọ naa lọwọ ara wọn.
O tun ni ki awọn araalu lọ fi ẹjọ eyikeyi banki to ba kọ lati gba owo naa sun ijọba ati CBN, ati pe oun yoo gbe irufẹ banki bẹẹ tipa.
Ẹwẹ, ọpọ ọmọ Naijiria lo ti n reti ki Aarẹ Muhammadu Buhari tabi Godwin Emefiele funra rẹ sọrọ lori owo naa lẹyin ti ile ẹjọ to ga julọ l’Abuja ti ni ki awọn eeyan maa na owo ọhun.
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?
A fún Malami atí Emefiele di ọ̀la láti tẹ̀lé àṣẹ ilé ẹjọ́ lórí àmúlò Naira àtijọ́ àti tuntun bí bẹ́ẹ̀ kọ́... - Àwọn gómìnà

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn gomina ti wọn gbe ijọba apapọ lọ si ileẹjọ lori lilo owo Naira atijọ ati tuntun ti fun wọn ni gbedeke di Ọjọ Iṣẹgun lati mu aṣẹ ileẹjọ giga naa ṣẹ.
Awọn gomina naa ni awọn fun agbẹjọro agba ati Minisita feto idajọ, Abubakar Malami ati gomina Banki apapọ ilẹwa, CBN, Godwin Emefiele di ọla ọjọ Isẹgun, lati gbe igbeṣẹ lori aṣẹ ile ẹjọ to ga julọ nipa nina Naira atijọ ati tuntun papọ.
Awọn gomina naa ni awọn yoo fi ẹsun titẹ oju ofin mọlẹ kan ijọba apapọ ti wọn ko ba ṣe ohun to tọ ni kiakia.
Bẹẹ ba gbagbe, ileẹjọ to ga julọ ni Naijiria lo paṣẹ pe ki wọn gba awọn araalu laaye lati lo owo Naira atijọ to jẹ N1,000, N500 ati N200 titi di Ọjọ Kọkanlelọgbọn, Oṣu Kejila, ọdun 2023.

Oríṣun àwòrán, Others
A pada lọ sile ẹjọ, ti ijọba ko ba sọrọ lori aṣẹ ileẹjọ giga lati lo Naira atijọ mọ tuntun - Awọn gomina
Lẹyin ọṣẹ kan ti ileẹjọ to ga julọ pa aṣẹ naa, Malami ati Emefiele ko i tii sọ ọrọ kankan lori aṣẹ naa.
Eyi si mu ki awọn ileeṣẹ ati awọn oniṣowo kọ lati gba owo atijọ naa ni ọwọ awọn eniyan.
Iroyin kan ni ileẹjọ ti fi aṣẹ wọn ranṣẹ si ijọba apapọ lati gba awọn araalu ni aaye lati lo owo atijọ naa fun osu mẹwaa.
Agbẹjọro fun awọn gomina ti wọn gbe ijọba apapọ lọ si ileẹjọ, Abdulhakeem Mustapha ni igbeṣẹ to kan ni lati pada lọ si ileẹjọ, ti ijọba ko ba sọrọ lori aṣẹ ileẹjọ giga naa.
‘’Ohun ti a o ṣe ni lati pe ipẹjọ tako ijọba pe wọn kọ lati tẹlẹ aṣẹ ileẹjọ, eyi to jasi titẹ oju ofin mọlẹ.’’
Bakan naa ni awọn ipinlẹ to ku ni awọn yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu igbesẹ awọn ipinlẹ toku lori gbigbe ijọba apapọ pada lọ si ileẹjọ ti wọn ko ba ti ba awọn araalu sọrọ lori aṣẹ ileẹjọ giga julọ naa.
















