Emefiele kéde pé ká máa ná Naira owó àtijọ́ àti tuntun lọ

Naira atijọ ati tuntun

Oríṣun àwòrán, CBN

Banki apapọ lorilẹede Naijiria ti kede pe awọn ara ilu le bẹrẹ si ni na owo atijọ N200, N500 ati N1000 lọ titi opin ọdun 2023.

Adari eto iroyin fun banki naa, Isa Abdulmumin lo kede bẹẹ ninu atẹjade kan to gbe soju opo ayelujara Twitter banki apapọ ilẹ wa, CBN ni Ọjọ Aje.

Abdulmumin ni CBN gbe igbeṣẹ naa lẹyin aṣẹ ileẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria, ti wọn fi lede ni Ọjọ Kẹta, Oṣu Kẹta, ọdun 2023.

Ikede ti CBN fisita

Oríṣun àwòrán, CBN

Banki apapọ ilẹ wa naa fikun pe ‘’Gẹgẹ bi iwoye wa, Banki apapọ ati ajọ awọn ileeṣẹ ifowopamọsi ti paṣẹ pe ki wọn tẹle aṣẹ ile ẹjọ to ga julọ, eyi to ni ki wọn maa na owo atijọ titi di Ọjọ Kọkanlelọgbọn, Oṣu Kejila, ọdun 2023.''

‘’Nitori naa, a ti paṣẹ fun awọn ti ọrọ kan lati tẹle aṣẹ ileẹjọ bi o ṣe yẹ.’’

Ṣaaju ni aarẹ Muhammadu Buhari ti ni ki CBN ma da ẹbi ru oun, ti ko ba le tẹle aṣẹ ileẹjọ to gajulọ ni Naijiria.