Ẹ̀mí èèyàn mẹ́wàá míì tún bọ́ sọ́wọ́ àgbébọn ní Kaduna, ọ̀pọ̀ fara gbọta

Agbebon

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army

Awọn agbebọn kan ti ṣe ikọlu si abule Langson to wa labẹ ijoba ibilẹ Zango Kataf ni ipinlẹ Kaduna nibiti wọn ti gbẹmi eeyan mẹwa, ti ọpọplọpọ si fara gbọta ninu isẹlẹ na.

Awọn agbebọn naa ni wọn bẹrẹ isẹ laabi wọn ni bi aago mẹsan alẹ, ti wọn si ja ile itaja kan lole ki awọn oṣiṣe alabo to le wọn pada.

Ẹni ti iṣẹlẹ naa soju rẹ ni gbogbo awọn to farapa ninu iṣẹlẹ naa ni wọn ti gbe lọ si ile iwosan fun itoju.

Alaga ajọ to risi idagbasoke Atyap ẹkun ibi ti Langson wa, bu ẹnu atẹ lu ijoba ipinlẹ Kaduna ati awọn ẹsọ alabo ti wọn fi sọwọ si agbegbe naa fun aabo to peye.

Alaga Atyap, Dokita Sam Achie ni igbesẹ ti ijọba ipinlẹ ọhun gbe ku diẹ kaato si awọn isẹlẹ iṣekupani to n waye ni agbegbe naa.

Sam Achie, nigba to n dupe lọwọ awọn osiṣẹ ọlọpa to wa ni ikalẹ nigba ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ, ni ki wọn tubọ mura si eto aabo.

O si rọ ijọba lati fofin de awọn agbebọn to n da wahala silẹ ni Gusuu Kaduna.

O wa rọ awọn olugbe Zango Kataf lati mu aabo wọn ni ọkunkundun, ki wọn si daabo bo dukia wọn lọwọ awọn to fẹ le won kuro lori ilẹ ini wọn.

Alaga ijoba ibile naa, nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ bẹ Gomina ipinlẹ Kaduna lati fi awọn osiṣẹ alabo ransẹ si, ki wọn le digbo lu awọn alakatakiti agbebon yii.

Àkọlé fídíò, Brt-Train Accident: Grandma Oreoluwa ní ìlá alásepọ̀ ló ní òun máà se fún òun tó bá dé

À ń wá aṣojúṣòfin kan, N1m ni ẹ̀bùn fún ẹni tó bá rí – Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

Aworan

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria ti kede pe oun n wa asofin Yakubu Shehu, to jẹ aṣojuṣofin kan to n soju ipinlẹ Bauchi ni ile aṣofin apapọ ilẹ wa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Yakubu ni ẹjọ iwa ọdaran lati jẹ, to fi mọ dida alaafia ru ni agbegbe naa.

Bakan naa ni wọn tun fi ẹsun ipaniyan kan an ninu iwe ẹsun ti wọn fi ṣọwọ si Ọga agba ọlọpaa ni Naijiria.

Oludije sipo gomina fun APC ni Bauchi kede pe àwọn janduku yinbọn mọ ẹṣọ alaabo oun mẹta

Ileeṣẹ ọlọpaa tun kede pe ẹnikẹni to ba ni iroyin nipa aṣofin naa ati ibi to fi ara pamọ si, yoo gba miliọnu naira kan.

Laipẹ yii ni oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Bauchi, ajagunfẹyinti Sadique Abubakar ni eto aabo lasiko idibo aarẹ ati tile adofin dẹnukọlẹ.

O si fi ẹsun kan pe awọn onijagidijagan yinbọn mọ ẹṣọ alaabo oun mẹta.

Abubakar ni agbegbe Duguri, ni ijọba ibilẹ Alkari ni ipinlẹ Bauchi ni isẹlẹ naa ti waye.

Amọ wọn ko lee fi idi rẹ mulẹ boya ohun ti oludije sipo gomina naa sọ, ni nnkan ṣe pẹlu idi ti ileeṣẹ ọlọpaa naa fi n wa aṣojusofin ọhun.

Àkọlé fídíò, Adedapo Tejuosho: Olóyè tó bá dán ìdánkúùdán wò lára òkú mi yóò gba Ọlọ́run lọ́gàá

Afurasí 5 tó ń hú òkú, ta ẹ̀yà ara ènìyàn kó sí gbaga ọlọ́pàá

Awọn afgurasi afinisetutuola

Oríṣun àwòrán, Ogun Police

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti nawọ́ gán àwọn afurasí márùn-ún kan tí wọ́n fura sí pé wọn jẹ́ àwọn tí wọ́n máa ń lo ẹ̀yà ara ènìyàn fi ṣe oògùn owó.

Wọ́n ní àwọn márùn-ún yìí máa ń hú òkú ní itẹ́ òkú tí wọ́n sì máa ń ta ẹ̀yà ara wọn fún àwọn tó máa ń lò ó fún oògùn owó.

Àwọn afurasí náà ni Oshole Fayemi, Oseni Adesanya, Ismaila Seidu, Oseni Oluwasegun àti Lawal Olaiya.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Abimbola Oyeyemi fi léde lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ Kejìlá ọdún 2023 ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ni ọwọ́ tẹ àwọn afurasí náà.

"Gbogbo àwọn afurasí náà ló ti jẹ́wọ́ pé àwọn ló wà nídìí híhú àwọn òkú náà"

Oyeyemi ní ọwọ́ tẹ àwọn afurasí náà lẹ́yìn tí àwọn kan wá fi ìròyìn náà tó àgọ́ ọlọ́pàá Odogbolu létí pé àwọn afurasí náà ń gbèrò láti lọ hú òkú níbì kan.

Ó ní àwọn afurasí náà ló wà nídìí híhú òkú káàkiri agbègbè Ososa, ìjọba ìbílẹ̀ Odogbolu, tí wọ́n sì máa ń yọ ẹ̀yà ara àwọn òkú tí wọ́n bá hú náà tà.

Ó fi kun pé gbogbo àwọn afurasí náà ló ti jẹ́wọ́ pé àwọn ló wà nídìí híhú àwọn òkú náà.

Bákan náà lọ ní wọ́n ti tún jẹ́wọ́ pé àwọn máa ń ta àwọn ẹ̀yà ara náà fún àwọn tó máa ń lò wọ́n láti fi ṣe ètùtù ọlà.

“Nígbà tí ọ̀gá ọlọ́pàá àgọ́ Odogbolu gbọ́ sí ìròyìn náà pé àwọn afurasí yìí tún fẹ́ lọ ṣọṣẹ́ ló da àwọn ọlọ́pàá síta láti fi póró òfin gbé wọn.”

Oyeyemi tẹ̀síwájú pé Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Frank Mba ti darí ẹ̀ka tó ń rí sí ìwádìí ìwà ọ̀daràn láti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ó ní lẹ́yìn ìwádìí ni àwọn afurasí náà yóò fojú ba ilé ẹjọ́.