INEC, Bode George tako ara wọn lórí ọ̀rọ̀ adarí ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀rọ ICT

Bode George ati Yakubu Mamood

Oríṣun àwòrán, Collage

Ajọ Eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC ti sọ pe iroyin ofege lasan ni iroyin kan ti aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu PDP, Oloye Bode George n gbe kiri.

Bode George lo ti kede saaju pe ajọ naa ti yan ọkan lara awọn kọmiṣọna tẹlẹ nipinlẹ Eko gẹgẹ bi adari ẹka imọ ẹrọ ayelujara ICT nibẹ.

Oloye Bode George lo gbe atẹjade kan sita lọjọ Iṣẹgun, ninu eyi to ti n lọgun pe INEC ti yan eeyan kan ti orukọ rẹ n jẹ "Femi Odubiyi" gẹgẹ bii adari ẹka imọ ẹrọ ayelujara ICT ni INEC.

Oloye Bọde George ṣalaye siwaju si ninu atẹjade ọhun pe Odubiyi yii ti figbakan ri jẹ kọmiṣọna nipinlẹ Eko.

Ẹ̀yin osisẹ alaabo, ẹ lọ gbe Odubiyi lati wa sọ tẹnu rẹ - Bode George

Oloye Bọde George salaye ninu atẹjade rẹ pe, kii ṣe akoko yii ti ọpọ ọmọ Naijiria n fi apa janu lori abajade ibo aarẹ to waye loṣu keji, lo tun y ki isẹlẹ bii eyi tun waye.

George ni tori esi ibo aarẹ naa, awọn oludije kan tilẹ ti gba ile ẹjọ lọ, bẹẹ si ni ẹrọ idibo BVAS ati oju opo agbara ayelujara to n ko esi ibo pamọ, IR3V, ṣe pataki pupọ fun ipẹjọ to n lọ lọwọ.

O wa ke sawọn ajọ alaabo gbogbo lati ṣe iwadi to ba yẹ lori ọrọ naa, ki wọn si ransẹ pe ọgbẹni Odubiyi naa lati wa sọ tẹnu rẹ.

Agba oselu naa ni ọkunrin naa gbọdọ wa salaye ipa yoowu to ba ko ati ọna to gba de ẹka imọ ẹrọ ayelujara ICT lajọ INEC, lẹyin to ti ṣe kọmiṣọna fun imọ ẹrọ ati ayelujara nipinlẹ Eko nigbakan ri.

Ko si eyikeji osisẹ ajọ INEC to dipo oselu mu ri ni Naijiria - Mamood

Gbogbo awọn ẹsun Bode George yii si lo mu ki ajọ INEC fesi pada pẹlu atẹjade kan to fi soju opo ayelujara Twitter rẹ lati sẹ lori ẹsun naa.

Ajọ INEC ni irọ gbuu lọrọ yii ati pe ko si eyikeyi ninu awọn oṣiṣẹ lẹka imọ ẹrọ ayelujara ICT ajọ naa, yala lolu ileeṣẹ rẹ nilu Abuja tabi lawọn ẹka ti ipinlẹ, ti orukọ rẹ n jẹ "Femi Odubiyi."

“Awọn oṣiṣẹ ajọ yii pọnbele lo wa lẹka imọ ẹrọ ayelujara ICT wa, ko si eyikeyi wọn to di ipo oṣelu kankan mu ri ni eyikeyi ipinlẹ lorilẹede Naijiria.

“A wa ke sawọn araalu lati kọ ipakọ si iroyin yii.

O yẹ ki ẹni to n gbe iroyin yii kiri pẹlu ṣe ayẹwo rẹ daradara, ki aye to maa fi oju oniroyin ofege wo o.”

Atẹjade ti INEC fisita

Oríṣun àwòrán, INEC