Ìbàjẹ́ mi kò le ní kí Makinde má lulẹ̀ lásìkò ìbò, lílọ ni yóò lọ - Teslim Folarin

Oríṣun àwòrán, Facebook
Oludije sipo gomina fẹgbẹ oselu APC, Oloye Teslim Folarin ti fesi pada fun eekan ẹgbẹ oselu PDP kan, to n polongo ibo fun gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, ko le wọọle ibo fun saa keji.
Oluwa rẹ ni Taofeek Arapaja, tii se igbakeji alaga apapọ fẹgbẹ oselu PDP lẹkun iwọ oorun Naijiria, to si tun ti jẹ igbakeji gomina tẹlẹ nipinlẹ Oyo.
Arapaja lo kopa lori eto ori redio kan nilu Ibadan laarọ ọjọ Isẹgun, to si n fi suna buruku pe oludije gomina fẹgbẹ oselu APC naa ati awọn eekan ẹgbẹ mii to jẹ alatako.
Amọ nigba to n fesi pada fun Arapaja ninu atẹjade kan akọwe iroyin rẹ, YSO Olaniyi fisita, Folarin wa se apejuwe igbakeji gomina ana naa bii oloselu to ti ba ijakulẹ pade.
"Ọkan Arapaja ko balẹ mọ nitori ọpọ ifẹ ati ifontẹlu tawọn eeyan n fun mi"
Atẹjade naa ni “Ko si iru ibanilorukọjẹ ti ẹ le se fun emi Teslim Folarin, to le gba Seyi Makinde silẹ lọwọ ijakulẹ lasiko eto idibo gomina to n bọ lọjọ Satide.
Oloselu alagbada ni mi, mo si jẹ agba ilu to n tẹ ilẹ jẹjẹ nipinlẹ Oyo, nitori naa, n ko ni kọbi ara si ẹsun ibanilorukọjẹ kankan, asọdun tabi atako lọdọ oloselu kankan.
Mo si fẹ fi da awọn eeyan ipinlẹ Oyo loju pe ọkan Arapaja ko balẹ mọ nitori ọpọ ifẹ ati ifontẹlu tawọn eeyan n fun mi, to fi mọ bi ọpọ ọmọ ẹgbẹ oselu PDP se n fi ẹgbẹ naa silẹ lati dara pọ mọ alatako.
Ohun to da mi loju ni pe Ọlọrun ọba atawọn mẹkunnu nipinlẹ Oyo wa lẹyin eto Itesiwaju ipinlẹ Oyo ti yoo waye lọdun yii.”
Atẹjade naa wa rọ awọn eeyan ipinlẹ Oyo lati mase tti sawọn ọrọ ibanilorukọjẹ, asọdun tabi atako kankan nitori Teslim Folarin nikan lo le seto isejọba to pegede bii gomina ipinlẹ Oyo.
Ki lo ti waye saaju...
Ẹ dìbò sáà kejì fún Makinde, láti sẹ̀san rere lórí bó ṣe dúró ti Tinubu àti ilẹ̀ Yoruba – Fayose

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook
Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose ti ke si awọn eeyan ipinlẹ Oyo lati dibo yan gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde fun saa keji.
Fayose lo kede bẹẹ lasiko to n kopa lori eto redio kan nilu Ibadan, to si ni ki wọn dibo yan Seyi Makinde pada, ko ba le pari iṣẹ rere to bẹrẹ nipinlẹ naa.
O ṣapejuwe Makinde gẹgẹ bi ẹni to pegede julọ fun ipo gomina ni ipinlẹ naa.
Ninu ọrọ rẹ, Fayose ni ọdun mẹrin akọkọ ti Makinde ṣe, fihan pe o ṣiṣẹ ribiribi, to si ni ki wọn tun dibo fun ki o le pari iṣẹ rere to bẹrẹ.
"Ajimobi ṣe saa meji, o yẹ ki Makinde naa lanfaani lati ṣe saa meji pẹlu"
Fayose tẹsiwaju pe bi o tilẹ jẹpe oun ati Makinde ko gba ti ara wọn lori ọrọ eto oṣelu, amọ Makinde fakọyọ pẹlu awọn eto igbayegbadun to n se fawọn eeyan ipinlẹ Oyo.
‘’Ajimobi ṣe saa meji, ero mi ni pe ki awọn eniyan fun Makinde ni anfaani lati ṣe saa meji naa.
Lara awọn iṣẹ akanṣe ti Makinde se to wu mi lori, ni agbegbe Circular Road to jasi Asejere, to fi mọ ọna Iṣẹyin.’’
‘’Mi o ni ero tako ẹnikẹni, amọ Makinde lo fakọyọ ju ninu gbogbo awọn eniyan to n dije du ipo gomina nipinlẹ Oyo.’’

Oríṣun àwòrán, Others
"Ẹ san Makinde ni ẹsan rere pada pẹlu bo se duro ti Tinubu lati jẹ ki agbara pada si ẹkun guusu"
Fayose tun kesi awọn eeyan ipinlẹ Oyo lati gboriyin fun Makinde to duro gidigba lẹyin Aṣiwaju Bola Tinubu lati di ipo aarẹ mu.
O ni iṣẹ akinkanju lo ṣe to fi doju ti awọn ti ko fẹ jẹ ki agbara wa si guusu Naijiria.
Bakan naa lo ke si gbogbo awọn oludije sipo aṣojuṣofin ni Ile Igbimo Aṣofin apapọ ti wọn fi idirẹmi lẹgbẹ oṣelu PDP lati fi ọwọ wọnu, ki wọn si ṣiṣẹ pọ pẹlu Makinde.
‘’Mo fẹ sọ fun yin pe ko si gomina to le ṣe gbogbo iṣẹ yii tan, ọdun mẹrin miran n bọ, ẹ fi ọkan balẹ.’’
‘’Ko si bi gomina Makinde ṣe le ṣiṣẹ tako Tinubu, ọmọ Yoruba atata ni, to si ri pe ero naa wa si imuṣẹ.’’
Bakan naa lo rọ awọn ara ilu lati jade ni witiwiti lati dibo yan Makinde fun saa keji gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Oyo.
















