Adedapo Tejuosho: Olóyè tó bá dán ìdánkúùdán wò lára òkú mi yóò gba Ọlọ́run lọ́gàá

Àkọlé fídíò, Adedapo Tejuosho: Olóyè tó bá dán ìdánkúùdán wò lára òkú mi yóò gba Ọlọ́run lọ́gàá

Osile ti Oke Ona Ẹgba, Ọba Adedapo Tejuosho ti salaye pe aigbọran ọmọ Naijiria si asẹ Ọlọrun lo mu ki a maa la isoro nla kọja.

Ọba Tejuosho, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni Ọlọrun lo n fi wa rẹrin lasiko yii nitori pe o ti pe wa tẹlẹ amọ ti a ko dahun si ipe rẹ.

Bakan naa lo ni orilẹede Naijiria ko le pin si wẹwẹ bayii amọ ti yoo ba tiẹ wa pin, kii se asiko yii ni lọrun fẹ ko pin.

"Wọ̀n kan n pariwo pe Buhari se daadaa ni tabi ko se daadaa, ko si ohun to n sẹlẹ, ti Ọlọrun ko mọ si."

O wa sọ asọtẹlẹ pe ti ileri Ọlọrun ba sẹ, Naijiria si n bọ wa di ara awọn orilẹede alagbara lagbaye.

Nigba to n sọrọ nipa ilana oye jijẹ ati isinku ọba nilana abbalaye, Ọba Tejuosho ni ofin tuntun ti wa bayii eyi to wọgile ilana sinsin ọba alaye nilana ẹsin ibilẹ.

"Mo ti sọ fun awọn oloye mi pe ti mo ba ku, ti wn ba dan idankudan wo lara oku mi, wọn yoo gba Ọlọrun ni ọga.

O ti di ofin bayii pe ki wọn fi ọba jẹ tabi sin ọba kan nilana ẹsin ti ọba naa n hu ati akọsilẹ ohun to ba sọ.

Iwa ọdaran si ni ti Oloye kankan ba tapa si ofin naa.