Olowo of Owo: Bí ìjọba bá ṣe àtúntò tó yẹ, Sunday Igboho yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wọn

Àkọlé fídíò, Olowo: Bí ìjọba bá ṣe àtúntò tún yẹ, Sunday Igboho yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wọn

Olowo tilu Owo, Ọba Ajibade Gbadegesin ti ke si ijọba lati wa nnkan se nipa awọn Fulani to n wa goolu ni Owo.

Ọba Gbadegesin, lasiko ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba ni o yẹ ka se akoso Naijiria gẹgẹ ba se fọwọsowọpọ gba ominira.

O ni ohun toju awọn to n pe fun idasilẹ Yoruba Nation ri, lo mu ki wọn maa pariwo fun iyapa Naijiria.

Olowo fikun pe ti ijọba ba se atunto to yẹ, Sunday Igboho yoo dakẹ, ti yoo si fọwọsowọpọ pẹlu ijọba.

Bakan naa lo woye pe ọpẹlọpẹ pe ikọ alaabo Amotekun to ti wa saaju akoko yii, bibẹẹ kọ, Ọlọrun lo mọ ohun ti oju awọn eeyan ipinlẹ Ondo ko ba ri tori eto aawo to mẹhẹ.

Ọba Gbadegesin wa rọ ijọba lati gba eto atunto Naijiria laaye, ki ohun gbogbo le tuba tusẹ.