Babatunde Gbadamosi: Kìí ṣe Tinubu ní ipò ààrẹ̀ tọ́ sí, ìgbà wo ní ìtan ajá ń kan lèmọ́mù?

Àkọlé fídíò, Tunde Gbadamosi: Kìí ṣe Tinubu ní ipò ààrẹ̀ tọ́ sí, ìgbà wo ní ìtan ajá ń kan lèmọ́mù?

Yoruba ni agba kii wa lọja, ki ori ọmọ tuntun wọ, agba ti ko si kẹhun sọrọ, yoo kẹ itan sare.

Idi ree ti gbaju gbaja oloselu kan ati onisowo pataki nipinlẹ Eko, Babatunde Gbadamosi fi n ke tantan pe asiko ti to fun ẹya Yoruba lati da duro.

Gbadamọsi, ẹni to ti du ipo gomina fun igba meji nipinlẹ Eko ni gba gba gba ni oun wa lẹyin idasilẹ orilẹede Yoruba lasiko yii, nitori ohun gbogbo ti yiwọ fun orilẹede Naijiria ta wa.

Gbajumọ oloselu naa, to tun sọrọ nipa ero lori eto atunto ti awọn oloselu kan n polongo wa fọwọ gbaya pe ọrọ ti kọja lori rẹ.

O ni ti eto idibo yoo ba tiẹ waye lọdun 2023, laise abosi, ta si fẹ sọ otitọ, ẹya ibo ni ọpọn sun kan lati fa oludije fun ipo aarẹ kalẹ.

Babatunde Gbadamosi wa bu ẹnu atẹ lu erongba asaaju ẹgbẹ oselu APC, Asiwaju Bola Ahmeds Tinubu lati dije fun ipo aarẹ Naijiria lọdun 2023.

O si fi gbogbo ẹnu sọ pe kii se Tinubu ni ipo aarẹ tọ si nitori ko si ba se fẹ pin itan aja, ti yoo kan lemọmu.