Yoruba Nations Vs Islamic petetioners: Àwọn Mùsùlùmí kan bẹ̀rẹ̀ ìpẹ̀jọ́ lòdì sí Oodua Republic, Igboho fèsì

Alfa Musulumi ati Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Koiki Media

Olori ẹgbẹ ajijagbara fun orilẹede Yoruba Nations, Sunday Igboho ti fi esi sita pe irọ nla ni awọn to gbe igbesẹ kikọwe ipẹjọ lori ayelujara pe orilẹede Oduduwa Republic ko ni faaye gba ẹtọ awọn musulumi.

Ninu ọrọ ti agbẹnusọ Sunday Igboho, Olayomi Koiki fi sita lori ayelujara, o bi wọ́n ni ibeere pe ṣe ni orilẹede Naijiria ni aabo ti wa fun Musulumi?

Koiki ni "bi ẹ ba ti ri iru ipẹjọ yii, kẹẹ bere ibere yii lọwọ wọn".

Esi Olayomi Koiki

Oríṣun àwòrán, Koiki Media

O fi kun un pe Yoruba Nation yoo faaye gba gbogbo ẹsin gẹlẹ bii ti orilẹede UK, USA, Germany, France atawọn orilẹede mii to faaye gba ẹtọ eeyan lati ṣe ẹsin rẹ.

Awọn ẹgbẹ ẹlẹsin Musulumi naa ni iha Guusu-Iwọ Oorun eyi tii ṣe ilẹ Yoruba lo n tọwọ bọwe lori itakun ayelujara kan ipetitions.com.

Wọn ni eyi wa lati tapa si ijagbara to n waye pe ki iran Yoruba da ni orilẹede tirẹ lọtọ ki wọn si yapa kuro lorilẹede Naijiria.

Gẹgẹ bi awọn kan to buwọ lu iwe ọhun ṣe sọ, ko si eto to jọ mọ pe wọn yoo gbọ ti awọn Musulumi nilẹ Yoruba ninu ija ti wọn n ja fun Yoruba Nation.

Ipejọ ori ayelujara yii bẹrẹ lati ọwọ Oyedeji Owoseni ni Ọgbọnjọ oṣu karun to si ti ko itọwọbọwe to fẹrẹẹ to ọọdunrun ati esi ọrọ to fẹrẹẹ to igba ninu iroyin ti a ti ri ikede yii.

Koko ọrọ ti wọn si kọ sinu iwe ipẹjọ ori ayelujara ọhun ka bayii pe: Ọrọ to kan awọn Musulumi ko ṣe pataki si awọn ajafẹtọọ Oodua; wọn ko tilẹ fi ti awọn Musulumi ṣe rara ninu ilana wọn, Musulumi ko ni aabo labẹ aato wọn.

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Koiki Media

Ṣe o gba pe lootọ ni eyi?

Ileeṣẹ iroyin Naijiria kan woye latinu iwe ori ayelujara ti wọn n tọwọ bọ pe ọpọlọpọ awọn to tọwọ bọ iwe naa lo jẹ Musulumi ọmọ orilẹede Naijiria ti awọn diẹ mii naa si tọwọ bọ ọ lati orilẹede Amẹrika, Burkina Faso, Sweden, Saudi Arabia ati London.

Ọkan lara wọn, Abibat Adebisi Sanusi ni "O dara ki a wa papọ gẹgẹ bi orilẹede kan, Naijiria. Ohun taa ni lati ṣe ni ka fi aaye silẹ fun anfani to pọ".

Adesina Kareem ni tirẹ kọ pe, "inu mi ko dun si awọn to n dari eto naa. Ọpọlọpọ wọn o ṣee fọkan tan pẹlu agbara".

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson Shomolu Bariga ní 'Restructuring'ti bọ́ aṣọ kò bá Omọyẹ mọ́!

Sulaiman Abdul Majeed ko si ibi kankan to han pe wọn ti faaye gba mi ninu eto ijijagbara Oodua /republic.

Baba Moshood ni "mi o ti Oodua nation lẹyin tori awọn to n ja fun un, janduku ni wọn, afipamuni ati ọdaran".

Olawuyi Abdul Akeem ni, "mi o gbagbọ ninu Oodua Nation. Mo fura si i, o ni ọwọ ẹgbẹ okunkun ati ẹsin Kristẹni ninu".

Sanusi Ibrahim ni wọn ko ni faaye gba ẹtọ oun lati ṣe ẹsin oun, o ni wọn ti n dena awọn ọmọbinrin Musulumi lati lo Hijaabu lawọn ileewe ijọba, wọn o tun gba awọn obinrin to fẹ tẹle ofin Quaran laye.

Adeniyi Liadi Oyedele sọ pe "Afojusun awọn ajijagbara naa ni lati tẹ ksin Islam ati awọn Musulumi ri mọlẹ ni iha Guusu - Ila Oorun ki wọn ba le gbe eto ikọkọ wọn jade" o si ni Musulumi ododo kankan o gbọdọ ti wọn lẹyin.

Àkọlé fídíò, Adebayo Murital David: Gbogbo iṣẹ́ tó ń múni là láyé wá láti ọpọlọ ni kìí ṣe agbára

Ẹwẹ, agbẹnusọ fun olori ajijagbara Yoruba Nations, Sunday Igboho iyẹn Olayemi Koiki ti fi esi sita pe irọ nla ni awọn to gbe igbesẹ yii n pa.

O wa gba imọran pe ki wọn ma gba "awọn eeyan perete kan to n ri jẹ nidi ibajẹ ati iwa ajẹbanu orilẹede ti wọn n pe ni Naijiria lati sọ fun wa pe ko ni si aabo fun awọn Musulumi ni orilẹede tuntun naa".

Àkọlé fídíò, 'Èmi ọmọ Ikorodu ọ̀ga, ọmọ aṣalẹ̀ jẹ́jẹ! Wo bí àwọn ọmọdé tó "tuush" yìí ṣe ń fi oríkì Yorùbá dábíra