Sunday Igboho on Adeboye: Àjìjàgbara, Sunday Adeyemo sọ pé àwọn èèyàn ṣi òun gbọ́ ni lórí ikú ọmọ Adeboye

Sunday Igboho ati Enoch Adeboye

Oríṣun àwòrán, livetimesng.com

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọkan pataki lara awọn to n polongo idasilẹ Oduduwa Republic, Sunday Adeyemo 'Igboho' ti fesi si ẹsun ti awọn eeyan kan fi kan pe o fi iku ọmọ yọ Pasitọ Enoch Adeboye.

Opin ọsẹ to kọja ni fidio ifọrọwanilẹnuwo ti Igboho ṣe pẹlu ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ ori ayelujara, Koiki Media, nibi to ti sọrọ nipa Adeboye, ati awọn olori ẹsin ti ko ṣe atilẹyin fun idasilẹ Oduduwa Republic.

Ninu fidio naa to tẹ BBC Yoruba lọwọ, ni ẹni to n fi ọrọ wa Igboho l'ẹnuwo ti sọ pe ko ki Anoch Adeboye lori iku ọmọ Baba Adeboye, Dare to di oloogbe l'ọsẹ to kọja.

Àkọlé fídíò, Alara tí Ilara Epe: Òjò gbọ́dọ̀ rọ̀ lásìkò ọdún Ẹlẹ́gba ni ìlú Epe- Oba Olufolarin Ogunsan

Eyi waye lasiko ti Igboho n fi ọrọ idupẹ ranṣẹ si gbogbo awọn alatilẹyin rẹ.

Esi ti Sunday Igboho fọ ni pe ko si nkan to kan oun pẹlu iku ọmọ Adeboye.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Lẹyin naa lo tẹsiwaju lati sọ pe ẹgbẹlẹgbẹ ọmọ ijọ ni ijọ RCCG to jẹ ti Adeboye, eyi to yẹ ki pasitọ naa lo anfaani rẹ lati polongo idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa fun wọn.

Ko tan sibẹ o, Igboho tun lo anfaani naa lati fi èpè ranṣẹ si gbogbo awọn 'ojiṣẹ Ọlọrun ti ko ba ṣe atilẹyin fun Yoruba Nation'.

O ni Ọlọrun yoo pa awọn iyawo ati ọmọ wọn.

Ọrọ naa fa awuyewuye ati ibinu laarin awọn ọmọ Naijiria, paapaa lori ayelujara.

Ọpọ lo si bu ẹnu ẹtẹ lu nkan ti Igboho sọ ninu fidio naa ti wọn n pin kiri lori ayelujara.

Ṣugbọn ni bayii, Ọgbẹni Igboho ti tun sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo miran pe awọn eniyan ṣi oun gbọ ni.

O ni "ti mo ba dakẹ, wọn a ni mo ti gba rìbá. Mo tun sọrọ, wọn ni mo bu Baba Adeboye.

"Kilode ti ma a fi bu u?"

O ṣalaye pe wọn ṣi oun gbọ ni o, oun ko bu Adeboye, oun kan fi awọn to tako Yoruba nation gégùn-ún.

"Awọn to n dalẹ Yoruba ni mo fi gégùn-ún."

Àkọlé fídíò, Trade by Barter, Rivers: Mọ̀ síi nípa ọjà ní Esuk Mba, níbití o ti lè fi iṣu gba edé, epo

Yatọ si eyi, o sọ pe ka ni ọmọ Adeboye, Dare, to kú wa laye ni, "oun naa i ba ko ipa pataki ninu orilẹ-ede Yoruba wa tuntun".

Lẹyin naa lo gbadura pe ki oloogbe sun re.

Igba akọkọ kọ niyii ti ẹnu kun Sunday Adeyẹmọ lori ọrọ sisọ rẹ nipa awọn adari, lati igba to ti bẹrẹ ipolongo fun idasilẹ Oduduwa Republic.

Ni asiko diẹ sẹyin lo sọ ọrọ abuku nipa Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, ṣugbọn o pada tọrọ aforiji.