Lizzy Anjorin: Wo orúkọ mẹ́rìnlá tí Lizzy Anjorin sọ ọmọ rẹ̀

Lizzy Anjorin ati ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Instagram/Lizzy Anjorin

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ẹbun pataki ni ọmọ bibi, o to bẹẹ ka ki iya aburo ku ewu.

Oṣerebinrin tiata Yoruba, Lizzy Anjorin ti n dawọ idunnu ọmọ tuntun jojolo ti Eledua fi ta a lọrẹ.

Lizzy ti n ki Ọlọrun ni mẹsan an mẹwaa lati igba ti o ti bi ọmọ naa lorilẹede Amerika.

Oriṣiiriṣii orin ati oriṣiiriṣii aworan oun ati ọkọ rẹ ni Lizzy ti fi si oju opo Instagram lati igba ti o ti bi ọmọ naa.

Lizzy ko le ṣa lai maa sọ pe Ọlọrun ọba sọ ẹgan oun di ogo nipa ọmọ tuntun to fi ta oun lọrẹ Mo gbé ìgbésẹ̀ láti ṣẹ́ oyún ọmọ mi tuntun, ọkọ mi nàá sì faramọ́ nítorí pé...

Lẹyin to ti sọ awọn oun ti o la kọja lati asiko ti oyun duro si i lara titi ti o fi bi ọmọ naa tan, Lizzy tun ti fi ọrukọ ọmọ naa soju opo Instagram rẹ bayii.

Lizzy bẹrẹ nipa kiki gbogbo awọn abiyamọ aye ku ajayọ ọjọ iya to waye lọjọ kẹsan an oṣu karun un ọdun 2021 yii.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Lẹyin naa lo bẹrẹ si ni ka orukọ ọmọ rẹ ni ọkọọkan ejeeji to fi pe mẹrinla.

Lizzy ni orukọ ọmọ naa niwọn yii:

1. OBA* ASETAN MAKU

2. OBA OKE *PEGANMIRE*

.

3. OBA OKE FAYE *YEMI*

Àkọlé fídíò, Trade by Barter, Rivers: Mọ̀ síi nípa ọjà ní Esuk Mba, níbití o ti lè fi iṣu gba edé, epo

.

4. OBA OKE *SEYIFUNMITAN*

.

5. OBA OKE FADUN *KAYOMI*

.

6. OBA OKE SORO MI *DAYO* NIWAJU ARONIPIN

.

7. *ADEWEPOMOLA*

.

8. *FLORIDA *

.

Àkọlé fídíò, 'Tééyàn bá kú a lè yọ yọ ojú yẹn tẹ́ẹ bá gbà wá láyé, a lè dá a sí fún ẹlòmíràn'

9. *OKIKI* WOLE *OLA*

10. *SEMAWON*

.

11. *MENDO*

.

12. *FARYAT*

Orukọ ikoko to ku ni:

13. *ABEBI*

14. *LAWAL*

Lẹyin to darukọ mẹrinla yii tan lo tun wa rọ awọn eeyan lati ba oun fi orukọ mẹwaa kun awọn eyi ti oun ti sọ.