Unknown gunmen: Ǹkan dé o! Àwọn jàndùkú tún yìnbọn pa ọlọ́pàá méje

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn janduku agbebọn tun ti yinbọn pa awọn ọlọpaa mẹfa lẹnu iṣẹ wọn nipinlẹ Rivers lalẹ ọjọ Ẹti, ọjọ keje oṣu karun ọdun 2021.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers, SP Nnamdi Omoni fi sita, o ni bi ago mẹjọ abọ alẹ ni iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.
O ṣalaye ninu atẹjade naa pe ọkọ Hilux lawọn agbebọn naa fi ṣe iṣẹ laabi ti wọn ṣe lọjọ Ẹti.
- Sẹ́nẹ́tọ̀ oníjó Ademola Adeleke kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní fásítì l'Amerika
- Àwọn ẹni ibi kan ń wá gbogbo ọ̀nà láti tú orílẹ̀èdè Nàíjíríà ká - Ààrẹ́ Buhari
- Ohun tí ìyàwó Adeboye ṣe ní ìgbà akọkọ tó fojú hàn lẹ́yìn ikú ọmọ wọn Dare
- Ẹbí Adeboye kéde bí ìlànà ikú Pásítọ Dare yoo ṣe lọ
- Akeredolu, jọ̀ọ́ gba iṣẹ́ lọ́wọ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ tó lu aláboyún - Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yarí
- Wo ìhùwàsí Buhari, àwọn èèkàn Nàìjíríà àti ibòmíì tó ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19
- 'Ojú olójú ni wọ́n fi sọ mí di ẹni tó n ríran lẹ́yìn tí mó fọ́jú fún ọdún méje'
Awọn ọlọpaa to wa lori afara Choba lawọn agbebọn naa kọkọ kọlu nibi ti wọn ti pa ọlọpaa meji ti wọn si tun dana sun ọkọ ọkan lara awọn ọlọpaa ọhun.
Awọn agbebọn naa tun gbera lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Rumuji nibi ti wọn tun ti pa ọlọpaa meji mi ti wọn si tun dana sun ọkọ awọn ọlọpaa.
Nnamdi sọ ninu atẹjade naa pe awọn agbofinro naa kọju ija sawọn agbebọn ọhun nigba ti wọn de eyi to mi ki meji lara wọn gbẹmi mi.

Oríṣun àwòrán, Rivers State Police
Bakan naa ni wọn tun kọlu agọ ọlọpaa to wa ni Elimgbu, bo tilẹ jẹ pe wọn ba awọn ọlọpaa naa nile.
Awọn ọlọpaa kọju ija sawọn janduku agbebọn ọhun, ṣugbọn mẹta ninu awọn ọlọpaa lo ba iṣẹlẹ naa lọ.
Awọn agbebọn naa ko ri ọkọ Hilux ti wọn gbe wa pada gbe lọ, ọkọ Sienna ti wọn ji gba lọwọ ẹnikan ni wọn gbe lọ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn agbebọn naa fara gbọta yana yana eyi to da apa si wọn lara.

Oríṣun àwòrán, Rivers State Police
Wọn tun gbe Sienna naa silẹ nigba tawọn ọlọpaa ko pada lẹyin wọn, bayii ni wọn ṣe na papa bora pẹlu apa ọta ibọn lara wọn.
Ẹwẹ, wọn ti gbe oku awọn ọlọpaa to ṣubu loju ogun lọ si mọsuari, nigbati ọga ọlọpaa ipinlẹ Rivers, Eboka Friday sẹleri pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo ṣe awari awọn kọlọnbiti ẹda naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa wa rọ awọn araalu lati fi to awọn ọlọpaa leti ti wọn ba ri ẹnikẹni pẹlu apa ibọn lara wọn.












