Wyclef Police Ibadan: Kí ni Ọ̀gá Ọlọ́pàá yóò ṣe fàwọn Ọlọ́pàá Ibadan tó ṣe obìnrin bó ṣe wù wọ́n nínúu fídíò?

Ibadan

Oríṣun àwòrán, Getty/Screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

"Lẹyin ti a ṣewadii iwa aidaa si ọmọniyan ti awọn ọlọpaa kan wu si ọmọbinrin kan ti a ri ninu fọnran to gbalẹ kan lọjọru ọjọ kejilelogun oṣu karun ọdun 2020, ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti da ọlọpaa mẹta mọ to ṣe e ati araalu kan to ba wọn kopa ninu iwa aibofin mu yii".

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Frank Mba lo fi ọrọ yii lede ninu atẹjade wọn pe iṣẹ ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria si ti ri ọlọpaa mẹta, wọn ti mu meji to ṣe obinrin kan bo ṣe wu wọn ninu fọnran ọhun to gba ori ayelujara kan lẹnu ọjọ melo kan sẹyin.

Atẹjade naa fi kun un pe wọn ti mu afurasi meji bayii. ASP Tijani Olatunji ati Insipẹkitọ Gboyega Oyeniyi.

Igbakeji ọga ọlọpaa Mba sọ pe wọn ti ko wọn si atimọle ọlọpaa to wa ni Panti, Yaba ni ipinlẹ Eko.

Getty/Screenshot

Oríṣun àwòrán, others

Bakan naa o ni wọn ti tẹra mọ akitiyan lati mu awọn meji to ku.

Ọga agba patapata awọn ọlọpaa lo paṣẹ pe ki wọn ṣe iwadii lẹyin ti fidio bi awọn ọlọpaa yii ni iha Guusu-Ila Oorun Naijiria ṣe ṣe obinrin kan baṣubaṣu gba ori ayelujara kan to si ni ki wọn fi panpẹ ọba mu awọn oniṣẹ laabi naa.

Ohun to ṣẹlẹ gangan

Ninu fidio naa, wọn ko ṣẹkẹṣẹkẹ si obinrin naa lọwọ ti wọn ba ni ile ti wọn ti fẹ lọ mu afurasi ole kan.

Àkọlé fídíò, Working religious women: Ẹ̀lẹ́hàá kìí ṣe ọ̀lẹ- Aminat Adegoke

Wọn ko ṣẹkẹṣẹkẹ si obinrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Towobola lọwọ, wọn ṣe fidio rẹ bi wọn ṣe n bere ọrọ lọwọ rẹ lori ibalopọ oun ati afurasi ọdaran ti wọn fẹ mu.

Fidio naa si ti mu ki ọpọlọpọ fara ya lori ayelujara.

Àkọlé fídíò, Itan Ilu gangan