Yakubu Dogara: Gómìnà Bauchi da ₦4bn owóyàá ìlú sápò iléeṣẹ́ àdáni kan

Bala Muhammed ati Yakubu Dogara

Oríṣun àwòrán, Yakubu Dogara Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Olori tẹlẹ fun ile asoju-sofin, Yakubu Dogarati kede fun araye pe, ọna aibofin mu ti ijọba ipinlẹ Bauchi n gba gbe isẹ agbase jade, jẹ ọkan lara ohun to mu oun kuro ninu ẹgbẹ oselu PDP.

Dogara sisọ loju ọrọ yii lasiko to n ba BBC sọrọ lati ipasẹ amugbalẹgbẹ rẹ feto iroyin, Turaki Hassan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa lo tun n kọminu lori aisan owo osu osisẹ lasiko ati bi gomina Bala Muhammed se kuna lati seto idibo ijọba ibilẹ laarin osu mẹfa akọkọ to gori oye, gẹgẹ bo ti seleri.

Muhammadu Buhari ati Yakubu Dogara

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina Facebook

"Ijọba ya biliọnu mẹrin naira, ti wọn si ba owo naa ninu apo asunwọn banki fun ileesẹ adani kan, bi o tilẹ jẹ pe orukọ ijọba ipinlẹ Bauch ni wsn fi ya owo naa.

Bakan naa ni wọn tun n gbe isẹ agbase sita lai bikita, lai naani owo ilọpo meji ti wọn n na lori rẹ lai tẹle abala ofin to yẹ."

Dogara fikun pe, ọkan lara isoro ti oun ri pẹlu awọn asaaju ẹgbẹ oselu PDP ati ijọba ipinlẹ Bauchi ni bi gomina ko se bọwọ fun agba atawọn ọba alaye, lodi si ileri rẹ.

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Coronavirus di adákẹ́jà ní Somalia, ikú ọ̀wọ́ọ̀wọ́ ń peléke si

Gbogbo awọn isẹlẹ yii si ni olori ana nile asoju-sofin fi ni o mu ki oun ko aasa oun kuro ninu ẹgbẹ oselu PDP lọ si APC.

Amọ sa, Dogara ti wa sẹ lori ahesọ ọrọ kan to n ja ranin-ranin nilẹ pe, oun fẹ du ipo gomina ipinlẹ Bauchi tabi pada sile asoju-sofin, lo mu ki oun pada sinu ẹgbẹ oselu APC.

Yakubu Dogara padà sí APC, Buhari kí i kúàbọ̀ ní Aso Rock

Dogara

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ ọ, adari ile igbimọ aṣoju ṣofin tẹlẹ, Yakubu Dogara ti pada si ẹgbẹ oṣelu All Peogresives Congress, APC.

Alaga egbe naa, Mai Mala Buni lo fi lede lẹyin ti ohun ati Dogara kọwọ rin lọ si ile Aarẹ ni Aso Rock ni Abuja.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ẹgbẹ oṣelu APC ni Yakubu Dogara kọkọ wa ko to ṣi lọ si ẹgbẹ oṣelu PDP lasiko ti oun ati aarẹ ile igbimọ aṣofin tẹlẹ, Bukola Saraki jẹ adari awọn aṣofin.

Dogara

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Dogara ni adari ile igbimọ aṣoju-ṣofin nigba naa.

Ẹwẹ, Dogara ti ni oun yoo ba awọn oniroyin sọrọ laipẹ ọjọ.

Àkọlé fídíò, Working religious women: Ẹ̀lẹ́hàá kìí ṣe ọ̀lẹ- Aminat Adegoke