Kidnapping in Nigeria: Ara sọ́ọ́bù oníṣòwò ni wọn ti rí nọ́ńbà ìpè rẹ̀, tí wọn sì tàn-án jáde lásìkò ìsìn

Oríṣun àwòrán, Others
Ọjọ gbogbo ni ti ole, amọ ọjọ kan soso ni ti olohun, bẹẹ lọrọ ri nigba tọwọ palaba awọn afurasi ajinigbe kan segi laipẹ yii.
Gẹgẹ bi ileesẹ ọlọpaa ti kede rẹ, ọwọ sinkun awọn ọlọpaa kogberegbe SARS lo mu awọn afurasi ajinigbe mẹrẹẹrin naa, lasiko ti wọn n ji olokoowo kan, Chekwas Daniel, gbe.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Eré ìtàgé lórí ayélujára, àbíkẹ́yìn faraya pé iṣẹ́ ilé ń pá òun lórí, ó gbé òfin kalẹ̀ fún ẹbí
- Boko Haram 601 parí iléẹ̀kọ́, ìjọba yóò san ₦20,000 lóṣù fún ẹnì ìkọ̀ọ̀kan
- Aráàlú faraya torí èèyàn 63 tó dèrò ọ̀run ní Gúúṣù Kàdúná láàrin ọ̀sẹ̀ kan
- Hospital Wedding: Oṣù kan péré ni Tash fi ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Simon kó tó kú
- Èèyàn 11 kú, èèyàn 438 míràn tún kó COVID-19 ní Nàìjíríà l'Ọ́jọ́ Àbámẹ́ta
- Lizzy Anjọnrin fẹ̀si fáwọn agbọ́yì-sọ̀yí lórí ìgbéyàwó rẹ̀, Madam Sajẹ dasójú ilé iṣẹ́, àti àwọn ǹkan míràn tó ṣẹlẹ̀ lágbo tíátà lọ́sẹ̀ yìí
Kọmisana ọlọpaa Janet Agbede, to wa fun ipinlẹ Abia nibi ti isẹlẹ naa ti waye ni, awọn afurasi ajinigbe yii lo ri nọmba ipe ọkunrin ti wọn ji gbe lara sọọbu rẹ, to kọ si.
Olokoowo naa to n ta asọ, lo n jọsin ni sọọsi lọwọ nigba ti awọn afurasi ajinigbe naa pe e, ti wọn si parọ pe awọn fẹ ra obitibiti asọ olowo iyebiye.
Ara ọkunrin naa bu mọ asọ, to si sare jade kuro ni sọọsi lati lọ da awọn onibara naa lohun, ti wọn sọ pe awọn wa niwaju sọọbu rẹ.
Ni kete to de iwaju sọọbu naa, ko ri awọn onibara naa, o pe wọn pe oun ti de, to si n silẹkun ẹnu ọna sọọbu rẹ naa.
Lasiko to n si lọwọ ilẹkun sọọbu naa lọwọ, to kọ ẹyin si ita, lawọn ajinigbe naa ba wọ lojiji lọ sinu mọto wọn, ti wọn si n fi tipa ji gbe lọ.

Oríṣun àwòrán, Others
Sugbọn ori re, ti i gbe alawore ko ni, lo mu ki awọn eeyan tete fi isẹlẹ naa to awọn ọlọpaa SARS leti, ti awọn onitọun si gba ya wọn, ti ọwọ si tẹ wọn.
Agbede ni orukọ awọn ajinigbe ti ọwọ tẹ naa ni Bright Chinonso, Eze Ernest, Chisom Godwin and Chinoyerem Chineye.
O fikun pe iwadi kikun ti n waye lori isẹlẹ naa, ti wọn ko si ni pẹ gbe wọn lọ sile ẹjọ.
Ọwó pálábá tọkọtaya tó ra ọmọ méjì ní ₦140,000 ségi

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police
Ki lo le mu ki eeyan kan ra ọmọ lọmọ pẹlu erongba lati tun wọn ta?
Ibeere re to gba ẹnu awọn eeyan lẹyin ti ọwọ ọlọpaa tẹ tọkọtaya kan nilu Eko ti wọn lawọn ra awọn ọmọkunrin meji kan ni ẹgbẹrun lọna ogoje Naira lọwọ obinrin kan nilu Jos.
Ninu atẹjade kan ti alukoro ọlọpaa nilu Eko DSP Bala Elkana fi sọwọ sawọn oniroyin, o ni obinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Chukwunonso Blessing lawọn gba awọn ọmọ naa lọwọ rẹ.
O ṣalaye pe awọn Ọlọpaa Ọtẹlẹmuye mu ni oju ọna ọja Alaba nibi to ti fẹ wọ ọkọ lọ si Onitsha pẹlu awọn ọmọ naa,Joshua James ọmọọdun mẹfa ati Samuel Gbawune ọmọọdun mẹta.
Nigba ti wọn koju rẹ lati mọ ibi ti o n ko awọn ọmọ naa lọ, o sọ pe ohun n ko wọn lọ ba ọkọ ohun arakunrin Chukwunonso Happiness .
Abalọ ababọ ọrọ naa, Chukwunonsọ jẹwọ pe oun ra awọn ọmọ naa ni lọdọ arabinrin kan nile awọn ọmọ alainiya kan nilu Jos toun si ko wọn wa si Eko.
Ileeṣẹ ọlọpaa lawọn ti doola awọn ọmọ naa bayi ti awọn si rọ ẹni to ba mọ obi awọn ọmọ naa lati kan si agọ Ọlọpaa.













