Boko Haram: Ìjọba ṣetán láti ra irinṣẹ́, sanwó oṣù fún adúnkookò mọ́ni tẹ́lẹ̀

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn ikọ agbesunmọmi to to mọkanlelẹgbẹta ti wọn jọwọ ara wọn fun ijọba, ti kẹkọọ jade nile iwe.

Ijọba si ti ṣetan lati ma a san owo iranwọ ẹgbẹrun lọna ogun Naira fun wọn ni oṣooṣu, ti wọn yoo si pese irinṣẹ fun wọn.

Kọmiṣọnna fun ọrọ iroyin ni ipinlẹ Borno, Babakura Jatau lo sọ eyi, lasiko ifọrọwanilẹnuwo kan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Jatau sọ pe, ajọ to n risi idagbasoke ẹkun ariwa Naijiria, (North East Development Commission) ati Ajọ to n risi akoso lilọ-bibọ ero lati agbegbe kan si omiran, (International Organisation for Migration) lo fi iranwọ naa ṣọwọ si awọn ikọ Boko Haram to ronupiwada naa.

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Others

O ni ko si otitọ ninu iroyin pe, ijọba n fun ẹni kọọkan ninu wọn ni N100,000, wi pe N20,000 ni awọn n san fun wọn.

Bakan naa ni wọn fikun pe, kii ṣe gbogbo wọn ni ikọ Boko Haram, amọ lara wọn jẹ awọn ti wọn jigbe fun ọpọlọpọ ọdun, ti wọn si kan an nipa fun wọn, lati ma a ba wọn jale.

Àkọlé fídíò, Hospital Wedding: Oṣù kan péré ni Tash fi ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Simon kó tó kú

Kọmiṣana fun eto iroyin ni ipinlẹ Borno, Babakura Jatau ni, lati ipinlẹ Gombe ni ijọba yoo ti ko wọn wa si ipinlẹ Borno, ti wọn yoo si ko wọn si ibugbe ti wọn yoo ti ma a gba idanilẹkọ.

‘Won yoo ma lo imọ ekọ ti wọn gba ni ile iwe ti wọn lọ, lati fi ṣiṣẹ.’

Olu ilu ileeṣẹ ikọ alaabọ lorilẹede Naijiria lo fi lede pe, ikọ Boko Haram to le ni ẹgbẹta lo ti jọwọ ara wọn, ti wọn si ti ṣetan lati darapọ mọ awujọ.

Ẹgbẹ́ Boko Haram pa àwọn òṣìṣẹ́ UN márùn ún tó wá ṣiṣẹ́ ìrànwọ́ ní Nàìjíríà

Awọn alakatakiti ẹsin Islam ti pa awọn oṣiṣẹ ajọ agbaye marun to wa ṣe iṣẹ iranwọ ni Naijiria. Oṣu to kọja ni wọn kọkọ ji awọn oṣiṣẹ naa ko.

Aarẹ Muhammadu Buhari ti da ẹbi iku awọn eeyan wọnyi le ẹgbẹ Boko Haram.

Boko Haram

Oríṣun àwòrán, others

Awọn ajọ adojutebi lo fi lede pe awọn oṣiṣẹ awọn wa lara awọn to ku.

Ipinẹ Borno lawọn alakatakiti naa ti ji awọn ọkunrin marun gbe. Wọn fifọnran kan sita loṣu to kọja eyi to fi oju awọn ti wọn ji gbe ọhun han.

Ẹwẹ, Aarẹ Buhari ti ṣeleri lati fi panpẹ ofin mu awọn apaniyan naa. O ni ijọba oun yoo rii daju pe wọn fa ẹgbẹ naa danu kuro ẹkun Ila Oorun Ariwa Naijiria.

Igbimọ ajọ adojutebi naa ni ibanujẹ ni iku awọn oṣiṣẹ wọn yii jẹ fun wọn pe o si dun wọn pẹlu gbogbo akitiyan wọn lati bere fun itusilẹ wọn.

Alabojuto ẹka itọju ọmọniyan ni ajọ isọkan agbaye, UN lorilẹede Naijiria, Edward Kallon ni ohun to ṣẹlẹ yii ko tọna pe awọn to n gbiyanju ati ṣeranwọ gan ni wọn n ṣe ikọlu si ti wọn si n pa.

Ẹwẹ, o sọ ninu ọrọ kan pe " iṣẹlẹ yii ko ni di awọn orilẹede ati ajọ agbaye lọwọ iranwọ ti wọn n ṣe fun ọgọọrọ awọn ọmọ Naijiria to nilo iranwọ ni apa Ila Oorun Ariwa orilẹede Naijiria".

Bakan naa o bu ẹnu atẹ lu iye orikoo ayẹwo awọn oṣiṣẹ alaabo kaakiri, o ni awọn oriko yii n di iṣẹ iranwọ lọwọ o si ṣi aaye silẹ fun ijinigbe, ipaniyan tabi ṣiṣe awọn eniyan leṣe to fi mọ awọn oniṣẹ iranwọ lorilẹede ti wọn n da ya sọtọ.

Ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram ti n ṣọṣẹ jiju ado oloro, ipaniyan ati ijinigbe lorilẹede Naijiria lati ọdun 2009.