Ilé ẹjọ́ ju olùkọ́ iléèwé aládàni sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá fún ẹ̀sùn lílú jìbìtì àti ìwé yíyí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile ẹjọ giga ijọba apapọ nilu Eko ti ju olukọ ile ẹkọ aladani kan, Folarin Olayinka, si ẹwọn ọdun mẹwaa, fun pe o tẹ ayederu owo Dọla.
Ọdun 2010 ni igbẹjọ ti bẹrẹ lori ẹsun ti wọn fi kan Olayinka, ti wọn si lo jẹbi meji ninu ẹsun meje ti ajọ EFCC, fi kan-an.
Awọn ẹsun naa ni i ṣe pẹlu erongba lati lu jibiti, nini owo ilẹ okeere dani lọna ti ko ba ofin mu, ati ṣiṣe ayederu iwe sọwedowo.
Wọn ni ọdaran naa gbiyanju lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 2008, lati fi iwe sọwedowo mọkandinlọgọrin to jẹ ti ilẹ America ranṣẹ silẹ okeere ni agbegbe Idi-Iroko, nipinlẹ Eko, pẹlu erongba lati lu jibiti.
Apapọ owo naa le ni ẹgbẹrun mejidinlogoji Dọla ($38,315).

Oríṣun àwòrán, EFCC/TWITTER
Ajọ EFCC tun sọ pe o ṣe ayederu sọwedowo ilẹ America ti owo ori rẹ to ọrinlenirinwo ati maarun Dọla ($485).
Ọdaran naa ti kọkọ sọ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun naa, ṣugbọn ẹlẹri mẹrin rojọ tako o pẹlu awọn ẹri (ayederu sọwedowo) ti wọn ko wa sile ẹjọ.
Nigba to ri pe aṣiri oun ti tu lo sọ fun ile ẹjọ pe iṣẹ ati oṣi lo mu oun hu iru iwa bẹ ẹ.
Ajọ EFCC sọ pe ẹsun naa tako ofin orilẹ-ede Naijiria to ni i ṣe pẹlu ọrọ owo.
Onidajọ Chukwujekwu Aneke, to da ẹjọ naa, sọ pe o jẹbi ẹsun kinni ati ikeji, to si ju u si ẹwọn ọdun marun un fun ikọọkan.













