Allen Onyema: Iro ni ile Amerika pa mo mi lori esun jibiti

Oríṣun àwòrán, Facebook/Allen Onyema
Alaga ilẹ isẹ ọkọ ofurufu Air Peace, Allen Onyema ti ni iro lasan ni ilẹ Amerika pa mọ oun lori ẹsun iwa jibiti ti wọn fi kan oun.
Onyema sọ eyi ninu atẹjade ti wọn fi lede si oju opo ikansiraẹni Twitter wọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
O ni ọmọ Naijiria rere ni oun, ti kii se magomago ninu gbogbo ohun ti oun ba n se.
Owurọ ọjọ Abamẹta ni iroyin gbe e pe orilẹede Amẹrika ti fi ẹsun jibiti ogun miliọnu dọla ati kikowo pamọ silẹ okeere lọna aitọ kan oludasilẹ ile iṣẹ ọkọ ofurufu Air Peace.
Aláìṣẹ̀ ṣì ni Onyema Air Peace títí America afí fìdí ẹ̀sùn jìbìtì $20m múlẹ̀- America
Amẹrika fẹ̀sùn jìbìtì $20m kan olùdàsílẹ̀ Air Peace, Allen Onyema
Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe ilẹ Amẹrika ti fi ẹsun jibiti ogun miliọnu dọla ati kikowo pamọ silẹ okeere lọna aitọ kan oludasilẹ ile iṣẹ ọkọ ofurufu, Air Peace, Allen Onyema.
Ẹka idajọ orilẹ-ede Amẹrika lo kede ọrọ naa loju opo itakun agbaye wọn.
Ẹka naa fẹsun kan Ọgbẹni Onyema loju opo agbọrọkaye wọn pe gbe ogun miliọnu dọla lati orilẹ-ede Naijiria sawọn apo ikowosi kan l'Amẹrika.
- Ẹ yé parọ́ kiri! Mi ò gbèrò láti lọ fún sáà kẹ́ta gẹ́gẹ́ bí ààrẹ - Buhari
- Iléẹjọ́, ẹ sọ fùn ọ̀gá DSS kó fún wa ní ₦1bn torí àhámọ́ lọ́nà àìtọ́ - Sowore àti Bakare
- Àgbẹdọ̀! Má kọ̀wé fipò sílẹ̀, àwọn àgbààgbà Yorùbá sọ fún Osinbajo
- Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ń fa súnkẹrẹ-fàkẹrẹ nílùú Eko
- Aàrẹ, igbákejì aàrẹ àti aàrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kọ̀wé fipò sílẹ̀ lọ́jọ́ kan náà
Bakan naa ni wọn ni o lo ayederu iwe pe oun fẹ fi owo naa ra ọkọ ofurufu lorilẹ-ede Amẹrika ni.
Onyema ati Ejiroghene Eghagha to jẹ alakoso eto inawo ile iṣẹ ọkọ ofurufu Air Peace ni wọn jọ fẹsun kan papọ.
Atẹjade ti ẹka eto idajọ ilẹ Amẹrika fi sita ṣalaye pe lati ọjọ kọkandinlogun, oṣu kọkanla ni ẹka naa ti fẹsun kan wọn pe wọn jọ gbimọ pọ lati lu jibiti pẹlu ile ifowopamọ l'Amẹrika.
Byung J. to jẹ olori ẹka idajọ lapa ariwa ẹkun Georgia sọ ninu atẹjade naa pe Onyema lo ipo rẹ gẹgẹ bi gbajugbaja oniṣowo ati oludasilẹ ile iṣẹ Air Peace lati lu jibiti pẹlu ayederu iwe.
O ni ijọba Amẹrika ṣetan lati daabo bo ẹka ile iṣẹ ifowopamọ lọwọ awọn onijibiti ti wọn n fi ọrọ owo ṣiṣe boju wa si Amẹrika.
Aṣoju ẹka idajọ Amẹrika mii, Robert Hammer sọ ninu atẹjade naa pe Onyema ṣe ọpọlọpọ eto lati ra oniruuru nnkan lorilẹ-ede Amẹrika, amọ o ni jibiti naa ni gbogbo rẹ ba de.

Ni ipari atẹjade naa, ẹka idajọ ilẹ Amẹrika sọ pe alaiṣẹ si ni Onyema ati Eghagha afi ti ijọba Amẹrika ba fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni wọn jẹbi ẹsun ti wọn kan wọn.
Nigba ti ile iṣẹ BBC kan si alakoso ile iṣẹ Air Peace, o ni oun ko tii le sọ nkankan lori ọrọ naa, amọ ile iṣẹ iroyin Punch sọ pe Onyema ni irọ ni wọn n pa mọ oun.
Ileeṣẹ iroyin naa ni pe Onyema ni ẹsun ti wọn fi kan oun tako iru eeyan t'oun jẹ ati pe oniṣowo to wa ilọsiwaju orilẹ-ede Naijiria ni oun.
Onyema loun ko jẹbi gbogbo ẹsun ti ẹka idajọ ilẹ Amẹrika fi kan oun, o ni oun ko tii ṣe jibiti ri pẹlu owo ti oun n ṣe.
Onyema ṣalaye siwaju si pe awọn agbẹjọro oun ti wa lori ọrọ naa bayii ati pe oun o kowo lati Naijiria lọ si ilẹ okere lọna aitọ ri.
Ẹwẹ, ọpọ lo gboṣuba fun Onyema ninu oṣu kẹsan an lẹyin to lo baalu ile iṣẹ rẹ lati gbe awọn ọmọ Naijiria ti wọn ha si orilẹede South Africa lasiko ikọlu awọn ọmọ ilẹ naa sawọn ọmọ Naijiria lọfẹẹ.
Koda ile aṣoju-sofin daba pe ki ijọba fi oye da Onyema lọla fun oju aanu rẹ.
Gbogbo igbiyanju BBC lati ba Onyema funra rẹ sọrọ ko tii so eso kankan di asiko yii.














