Andrew Haruna: So-bàtà tó di ọ̀jọ̀gbọ́n fásitì tó di ọ̀gá àgbà

Andrew

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Ko si ẹni ti ko lè gòkè àgbà láyé tóo bá ti ní ifọkansìn.

Iṣẹ ọwọ́ loriṣiiriṣii ni ọdọmọde Andrew Haruna to ti di ọjọgbọn bayii to tun n tukọ fasiti ijọba apapọ ni Gashau nipinlẹ Yobe (FUGA) fi bẹrẹ aye rẹ.

Lati kekere ni iwe kika ti wu Andrew ṣugbọn ko si agbara rara.

Koda nigba to ku diẹ kaato fawọn obi rẹ, ko jẹ ki eyi di i lọwọ lati ma lọ sinu ọgba ile iwe laini kọbọ lapo.

Itan Igbesi aye Ojogbon Andrew Haruna:

A bi Haruna lọdun 1957 ni abule Gar ni ijọba ibilẹ Alkaleri ni ipinlẹ Bauchi.

O lọ sile iwe alakọbẹrẹ Gar Local Education Primary ni Bauchi lọdun 1964 si ọdun 1970.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa lori BBC: Olùkọ́ Kikelomo Ogunboye tan ìmalẹ̀ sí ìwà olè ọ̀gá ọlọ́pàá

Andrew lọ si ati ti girama Government College Maiduguri ni Bornu lọdun 1971 si odun 1975.

O tẹra mọ iṣẹ siso bata ni kete to pari idanwo iwe mẹwaa rẹ ni kilomita ẹgbẹta si abule rẹ.

Àkọlé fídíò, Divorcee: Ó sàn kí wọ́n yàgò fúnra wọn ju ki wọ́n ṣe ara wọn léṣe- Fisayo

Iṣẹ agbẹ ni iṣẹ ti ọjọgbọn Andrew Haruna mu lọkunkundun lati igba ewe.

Haruna n ta igi idana to ba ṣe ta lati oko fun ọpọlọpọ ọdun.

O tun maa n ran iya rẹ lọwọ nidi akara dindinta ko too tun maa ba awọn onibara rẹ so bata wọn to ba ja nigbogbo igba ti oju n pọn ọn.

Awọn obi Andrew fẹran pe ko kawe ṣugbọn agbara ni ko si ni eyi ti wọn jọ n sa ipa wọn pe ki o le mọọkọ ko mọọ ka.

Idi iṣẹ siso bata yii ni Andrew ti n da owo jọ to n fipamọ ko le kawe di ipele iwe giga fasiti

O kawe gboye ninu imọ ẹda ede ni fasiti Maiduguri ko to lọ si fasiti London lati kawe de oye ọmọwe lọdun 1990.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ

O gba iranlowo university fellowship to fi lo kawe laarin odun 1983 si odun 1990 ni School of Oriental and African Studies, ni fasiti London

O gba ami ẹyẹ ti Kwame Nkrumah to wa fawọn olori lọdun 2016 si ọdun 2017.

Àkọlé fídíò, World Diabetes Day: Ọdún kọkandinlogun ti mo ti wà lẹ́nu itọ ṣúgà nìyí

Ọdun 1982 ni wọn gba Andrew si iṣẹ aran olukọ agba fasiti lọwọ ninu eyi to ti bẹrẹ iṣẹ lati di olukoni.

Lọdun 2016 ni haruna Andrew di ọga agba patapata fun fasiti ijọba apapọ to wa ni Gashua nipinlẹ Yobe.

Ko si ipo ti ẹda ko lee de laye ti eeyan ko ba ti sọ ireti nu laye ti o dẹ tẹpa mọṣẹ pẹlu igbagbọ ninu Olodumare fun iranlọwọ ayanmọ ẹni.