Kenya Prisioners: Àwọn ẹlẹ́wọ̀n mórí lé ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fún ẹ̀kúnwó owó oṣù ẹlẹ́wọ̀n

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn to ti ṣẹwọn ri mẹta lorilẹ-ede Kenya ti morile ile ẹjọ kotẹmilọrun bayii lẹyin ti ile ẹjọ giga kan da ẹjọ wọn nu
Awọn mẹta yii ni wọn pe ẹjọ fun ẹkun owo oṣu fawọn ẹlẹwọn to n ṣiṣẹ lọgba ẹwọn nibi ọdun mẹrin sẹyin.
Awọn mẹta to ṣẹwọn ri yii ṣalaye pe iyipada ilẹ naa eyi ti wọn sọ pe o mu awọn lẹru, ati pe o tapa sofin ẹtọ ọmọniyan wọn.
Ọdunrun un naira o le diẹ lawọn elewọn n gba lọdun bayii lorilẹede naa, ọdun 1979 tii ṣe ogoji ọdun sẹyin nijọba ti ṣe agbeyẹwo owo oṣu awọn ẹlẹwọn kẹyin.
Awọn ẹlẹwọn lorilẹede kenya maa n ṣe aga ijoko, tablili fawọn ile iṣẹ ijọba ati ile igbimọ aṣofin.
Bakan naa ni wọn maa n ṣe ohun ti wọn maa n kọ nọmba ọkọ si.
Awọn to ti figba kan wa lẹwọn yii tun sọ fun ile ẹjọ pe lọpọ igba lawọn ẹlẹwọn kii lanfani si awọn ohun ti wọn nilo bi ọṣẹ, ọṣẹ ifọyin atawọn nkan miran.
Ọkan lara awọn olupẹjọ naa, Aloys Onyango sọ fun ile ẹjọ pe ko paṣẹ fun awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn lati sanwo oṣu oun fun ọdun mẹrindinlogun t'oun lo lẹwọn.












