Kogi & Bayelsa Polls: Buhari ní ìdìbò gómìnà gbọdọ̀ lọ nírọwọ́ rọsẹ̀

Oríṣun àwòrán, Twitter/Presidency
Ṣaaju idibo gomina nipinlẹ Kogi ati Bayelsa lọjọ Satide ọsẹ yii, Aarẹ Muhammadu Buhari ti kilọ fawọn oṣiṣẹ eleto aabo lati dena awọn janduku to ba fẹ ji apoti idibo gbe.
Buhari ninu atẹjade to fi sita lati ọwọ oludamọran pataki lori ọrọ iroyin, Garba Shehu, sọ fawọn oṣiṣẹ eleto aabo pe ki wọn ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ, ki wọn rii pe awọn eeyan dibo gẹgẹ bi ẹtọ wọn.
Aarẹ Buhari sọ pe gbogbo ọna ni kawọn ẹṣọ eleto idibo fi dena ẹnikẹni to ba fẹ ji apoti idibo gbe.
- A ti gba aṣẹ ilé ẹjọ míì to tako àṣẹ́ ilé ẹjọ to wọ́gile olùdije APC ni Bayelsa
- A gbé ìgbìmọ̀ kan kalẹ̀ láti ṣiṣẹ́ lórí gbígba àkóso fásitì LAUTECH - Seyi Makinde
- "$2,600 àǹtí mi ni mo jí láti lọ sókè òkun àmọ́ àbámọ̀ ló gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ mi"
- ‘Ilé ẹjọ́ kò gbé ẹ̀sùn ìfipánílòpọ̀ yẹ̀wò, à ń lọ sí ilé ẹjọ́ - Busola Dakolo
Aarẹ ni ẹnikẹni ko gbọdọ dunkoko mọ ẹnikan tabi dena ẹnikẹni lati dibo gẹgẹ ẹtọ wọn.
Bakan naa ni aarẹ Buhari kepe awọn oludibo nipinlẹ Bayelsa ati Kogi lati ṣe jẹẹjẹ nibudo ibudo idibo, ki wọn si dibo lalaafia gẹgẹ bi ofin ti laa kalẹ.
Buhari sọ pe, ''nibi gbogbo ti eto idibo ti n waye ni oludije kan yoo ti jawe oloubori, ti omiran yoo si fidi rẹmi, ti Bayelsa ati Kogi kogi naa ko gbọdọ yatọ.''
Aarẹ Buhari rọ awọn oludije lati gba esi idibo ti yoo waye bi o ba ṣe ri laidarogbodiyan silẹ.
Aarẹ ni oludije ti eto idibo ko ba tẹ lọrun laṣẹ lati gbe ile ẹjọ lọ dipo ki o da wahala silẹ.
- Èèyàn mẹ́tàlá dèrò ọ̀run nínú ìjàmbá ọkọ̀ lópòpónà Ìbàdàn s'ÈKó
- Zlatan: Èyí mo ṣé tó, àsìkò tó láti tèsíwájú nínú ìrìnàjò mi
- Ilé ẹjọ́ ni agbábọ́ọ̀lù ọmọ Nàìjíríà, Dickson Etuhu jẹ́bi ẹ̀sùn títa ìdíje Sweden
- Àwọn ọmọ Nàìjíríà bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu NTA lórí ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ìdíje bọ́ọ̀lù
- Góòlù pọ̀ ní ìlú Madaka ṣùgbọ́n wọn kò ní ọ̀nà fún ọgọ́rùn ún ọdún















