Edo State House of Assembly: Obaseki ní Oshiomole fẹ́ fipá gbàjọba lọ́wọ́ òun

Gẹgẹ bi ara igbesẹ ki ẹnikẹni ma joko ṣe ohunkohun ni ile aṣofin ipinlẹ Edo, gomina ipinlẹ naa, Godwin Obaseki ti paṣẹ ki wọn lọ yọ awọn orule ile naa igbimọ aṣofin naa lẹyin ti gomina ọhun atawọn agbofinro to fẹ fi tipa gbe ilẹkun ile nla naa ti pa ti gbe'na woju ara wọn.
Ni kete to le awọn agbofinro naa jinna lo paṣẹ pe kawọn kọngila wa bẹrẹ atunṣe ileegbimọ naa.
Gomina Ọbaseki ṣalaye fun BBC News latẹnu agbẹnusọ rẹ, Crusoe Osagie pe awọn alagbara oloṣelu kan pẹlu gomina ipinlẹ kan lorilẹede Naijiria ni wọn gbimọ pọ lati fẹ fi tipa gba ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Edo ki wọn lee da rugudu silẹ ṣaaju idibo gomina to fẹ waye nibẹ lọjọ kọkandinlogun oṣu kẹsan ọdun 2020.
Gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Edo ṣe sọ, "Adams Oshiomhole atawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC kan, pẹlu gomina Hope Uzodinma lo wa nidi iṣẹlẹ naa.

Wọn fẹ fi tipatipa gba akoso ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa eleyii ti wọn n tun ṣe lọwọlọwọ.
A gbọ pe wọn lọ rọ ayederu ọpa aṣẹ ile naa eyi ti wọn fi fẹ ya bo ile igbimọ aṣofin ti ko si lẹnu iṣẹ bayii nitori atunṣe to n lọ lọwọ nibẹ, lati gbọna ti ko tọ ṣe agbekalẹ ileegbimọ aṣofin miran lowurọ Ọjọbọ.
Gomina ipinlẹ Edo, olori ile aṣofin nibẹ, igbakeji olori ile aṣofin ipinlẹ naa wa ni ileegbimọ aṣofin naa lati ba igbesẹ naa jẹ.
Fun oṣu meji bayii inu gbọngan ipade nla to wa ni ileegbimọ aṣofin naa lawọn ọmọ ileegbimọ aṣofin ipinlẹ naa ti n ṣe ipade wọn.
Agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Edo, ọgbẹni Crusoe Osagie fi ẹsun kan gomina ana ni ipinlẹ naa, Adams Oshiomhole to tun jẹ alaga ana fun ẹgbẹ oselu APC lo n gbiyanju lati fi ipa gba ile aṣofin naa.
Gómìnà Obaseki àtàwọn Ọlọ́pàá tó gbàkóso ílé Aṣòfin Edo forígbárí

Ohun taa gbọ ni wi pe Gomina ipinlẹ Edo Godwin Obaseki ati igbakeji rẹ ti lọ tu awọn ọlọpaa to duro gbagba si ẹnu ọna ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Edo ti wọn si n gbiyanju ati fi tipa tikuuku wọle.
Obitibiti ọlọpaa lo pejọpọ si Ile Igbimọ Aṣofin ipinlẹ Edo to wa ni ilu Benin.
Awọn ọlọpaa naa yabo ile igbimọ aṣofin naa pẹlu ọkọ wọn, ti wọn si duro wamuwamu sibẹ.
Eleyii n waye lẹyin wakati diẹ ti awọn aṣofin ipinlẹ naa yọ igbakeji abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa.
Igbakeji Kọmisọnna ọlọpaa ni ipinlẹ Edo, Ayoola Ajala lo dari awọn ọlọpaa naa.
Ẹgbẹ oṣelu PDP loju opo Twitter ni ẹgbẹ oṣelu APC n lọ awọn ọlọpaa naa lati da ẹru ati ipaya silẹ ni ilu naa nitori Gomina Obaseki n gbajumọ si nipinlẹ naa.
- Ìtàn ayé Shina Rambo, adigunjale tó fi oyún 27 gún ọṣẹ
- Àgbáríjọ àwọn nọ́ọ̀sì fẹ́ gbé Olamide Baddo lọ sílé ẹjọ́ fún ìbanilórúkọjẹ́
- Wo atẹ àlàkalẹ̀ ìdánwò WAEC fún ọdún 2020 tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní August 17
- Ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ti ń fi ọtí àmupara bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ ní kí ìjọba dẹwọ́ọ òfin títà ọtí lásìkò Covid-19
Bí Ẹ̀ka aláṣẹ́ ti já agbára gbà mọ́ ìgbìmọ̀ olùdarí APC lọ́wọ́
"Aug 2018 ni ìgbìmọ̀ aláṣẹ APC ti ṣe ìpàdé kẹ́yìn, Oshiomole ti kùnà"
Àwọn gómìnà lábẹ́ àsía ẹgbẹ́ òṣẹ̀lú All Progressive Congress (APC) tí kési alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Adams Oshiomole lati pe ipade igbimọ alakoso ẹgbẹ́ tàbi kó kọ̀wé fipò sílẹ̀.
Awọn gómìnà naa sàlàyé pé, bi alága apapọ ẹgbẹ kò se lee pe àwọn àgbàgbà ẹgbẹ́ sí ìpàdé, ti n mú idàrúdàpọ̀ bá ètò ẹgbẹ́.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Òbítíbitì ẹ̀gbin ti sọ ìlú Ibadan di ààtàn - Aráàlú figbe bọnu
- Àwọn ẹni òkùnkùn ló já ìṣẹ́gun mi gbà, mò ń lọ sílé ẹjọ́ tó ga jùlọ - Bayo Adelabu
- Ọ̀pọ̀ àwòrán rèé tó ń sàfihàn bí Ibadan se kún fún ẹ̀gbin àti òórùn
- Àbádòfin ìdájọ́ yíyẹ igi fún 'ni tórí ọ̀rọ̀ ìkóríra! Àwọn ọmọ Nàìjíríà la ohùn
- Olùdásílẹ̀ Twitter bá wọn jó 'Soapy' ní Nàìjíríà , ó fi òǹtẹ̀ jan Tacha
Oludari agba fun ẹgbẹ́ àwọn gomina, Salihu Lukman, lo kede bẹẹ nínú àtẹjáde kan to fọwọsí lọjọru nílùú Abuja.

Oríṣun àwòrán, @SPNigeria
Àtẹjáde náà ni " kò sí ohunkohun miran, to ba ti yàto si ìpàdé ẹlẹgbẹ́jẹgbẹ́ tàbi ìpáde àpérò gbogboogbo, to lee parí ǹkan to ti dàrú nínú ètò ẹgbẹ́"
"O sàn kí Oshiomhole bìkítà fún ilana ẹgbẹ́ to wa nínú iwe ofin ẹgbẹ́, láti pe ìpade àwọn èèkàn ẹgbẹ ki wọn lee sọ̀rọ̀ lórí gbogbo kùdìẹ̀kudiẹ̀ to n ba ẹgbẹ́ APC fínra, tàbi ko gba pé òun ko kunju òṣùwọ̀n láti tukọ ẹgbẹ̀, ko sì kọ̀wé fipò sílẹ̀."
Lukman sàlàyé pé, o pọ̀ndandan ki Oshiomole kọwe fipo rẹ silẹ, paapaa pẹ̀lú ìròyìn to n jáde láti ìpínlẹ̀ Edo pé, àwọn oloye ẹgbẹ̀ APC ti díbò "a ò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀" fun Oshiomhole.

Oríṣun àwòrán, @KBStGovt
"Dipo ka gbajumọ ọna ti APC yoo fi bori ninu awọn eto idibo to wa nilẹ, n se la n foju tẹnbẹlu ara wa. Gbogbo awọn ami buruku yii to waye ni ipinlẹ Zamfara, Rivers, Bauchi ati Adamawa lo tun fẹ suyọ abyi ni Bayelsa."
Lukman fikun pe o se ni laanu pe igbimọ alakoso ẹgbẹ to yẹ ko wa ojutu sawọn isoro yii lo fẹ dabi eyi ti wọn ti so rọ. Osu kẹjọ ọdun 2018 ni wọn ti se ipade kẹyin, ti ẹka alasẹ to yẹ ko maa se amusẹ ipinnu ti igbimọ alakoso ba se, ti wa ja agbara gba mọ igbimọ alakoso ẹgbẹ lọwọ.
Edo APC vs Oshiomole: Ẹ̀kà ìpínlẹ̀ tàbí ìjọba ìbílẹ̀ kò láṣẹ láti yọ alága àpapọ̀ ẹgbẹ́

Oríṣun àwòrán, Jubril A. Gawat
Ẹgbẹ oṣelu APC ti bẹnu atẹ lu igbesẹ awọn ọmọ ẹgbẹ naa kan ni ipinlẹ Edo, ti wọn lawọn paṣẹ lo fidimọle fun alaga ẹgbẹ naa lapapọ, Adams Oshiomole.
Idahun yii n waye nitori bi ẹka ẹgbẹ naa nilu Benin ṣe ni oun ko ni igbagbọ mọ ninu alaga ẹgbẹ nipinlẹ ati alaga apapọ ẹgbẹ naa.
Yakubu Nabena, to jẹ igbakeji akọwe ipolongo ẹgbẹ APC ṣalaye fun ikọ BBC pe, igbesẹ to yẹ kọ ni awọn to paṣẹ lọ gbele rẹ fun Oshiomole tẹle.
- Àwọn ẹni òkùnkùn ló já ìṣẹ́gun mi gbà, mò ń lọ sílé ẹjọ́ tó ga jùlọ - Bayo Adelabu
- Ẹ gbà wá o! Ìbọn àti afẹ́fẹ́ aláta ní DSS fi tú wa ká lásìkò ìwọ́de fún ìdásílẹ̀ Sowore
- Òfin ọ̀dájú ni àṣọ́bodè ṣe pé epo kò gbọdọ̀ dé ẹnu bodè Nàíjíríà - Ilé aṣojú-ṣòfin
- Ẹ wo àwọn ààrẹ tí ikọ̀ ọmọ ogun ti gba ìjọba lọ̀wọ̀ wọn
O ni ''alawada lawọn to gbe iru igbesẹ yii'' nitori pe wọn ko laṣẹ lati paṣẹ lọ fidimọle fun alaga ẹgbẹ lapapọ. Ohun ti wọn ṣe ko mu ọgbọn wa rara. Wọn ni lati mọ nnkan ti ofin ẹgbẹ sọ ki wọn to gbe iru igbesẹ bẹẹ''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O wa ṣalaye pe, awọn igbesẹ kan wa labẹ ofin ẹgbẹ ti eeyan gbọdọ ṣe, ki o to le ni oun fẹ yọ alaga ẹgbẹ lapapọ
''Ni ipele nipele ni ohun gbogbo wa ninu eto. Ki eeyan to le yọ alaga ẹgbẹ lapapọ tabi ki wọn to le kọwe lọ joko sile fun-un, igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ lo le se bẹẹ.''
Ohun ta ti jabọ ṣaaju lori ọrọ yii
Nkan ko ṣebi ẹni rọgbọ falaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress APC, Adams Oshiomole pẹlu bi awọn ọmọ ẹgbẹ naa kan ni ipinlẹ Edo ṣe lawọn jawe lọ rọọkun nile fun un.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lọjọ Iṣẹgun niroyin gbori afẹfẹ kankan lẹyin ti ẹka ẹgbẹ naa ni Benin tii ṣe olu ilu Edo kede pe awọn jawe lọ rọọkun n'le falaga ẹgbẹ naa ni ipinlẹ ohuin, Anselm Ojezua.
Ko pẹ si igba naa ni ikede miran wa lati ile ijọba pe wọn ti yọ akọwe ẹgbẹ naa ati pe wọn tun kọwe lọ fidimọlẹ fun alaga ẹgbẹ naa lapapọ Adams Oshiomole.
Titi di bi a ti ṣe n ṣe akojọpọ iroyin yii, Adams Oshiomole tabi alaṣẹ ẹgbẹ naa kankan loke ko tii fesi si igbesẹ yi.
Lẹnu ọjọ mẹta yii ni fa ki n fa ti n waye laarin Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki ati Adams Oshiomole.
Toun ti bi awọn agbagba ẹgbẹ naa ti ṣe gbiyanju lati dẹkun aigbọraẹniye laarin wọn,iṣẹlẹ to ṣẹlẹ yi n ṣafihan pe nnkan ko rọgbọ ni ipinlẹ naa falaga ẹgbẹ APC.
Awọn alaga kan ni digbi lawọn wa lẹyin Oshiomole
Bi awọn kan ti ṣe ni awọn ko fẹ ri imi Oshiomole lakitan mọ lawọn agbarijọpọ alaga ijọba ibilẹ kan sọ pe gbọingbọin lawọn wa lẹyin rẹ.
Gẹgẹ bi ohun ta ri ka ninu iwe iroyin Naijiria kan,atẹjade kan tawọn alaga Etsako West,Etsako Central fi sita sọ pe ''awa ni alaga ijọba ibilẹ mẹrindinlogun a o si mọ nipa ipade to waye nibi ti wọn ti kọwe akoniigbagbọ ninu rẹ mọ fun alaga ẹgbẹ wa Adams Oshiomole''
Wọn tẹsiwaju pe dipo Oshiomole,Gomina Godwin Obaseki lawọn ko ni igbagbọ ninu rẹ ati alaga ẹgbẹ APC ni ipinlẹ Edo,Anselm Ojezua.
Wọn wa tẹnumọ pe Oshiomole ṣi ni alaga olori awọn ati pe ''wamuwamu lawọn wa lẹyin rẹ''














