APC: Kí ni àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó ń da Oshiomole láàmú?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iji nla lo n ja lagbo ẹgbẹ oṣelu APC bayii. Iji naa si n fi alaga ẹgbẹ oṣelu naa lakalaka lọwọlọwọ.
Awọn eekan ẹgbẹ oṣelu naa ni wọn ti n ke si Adams Oshiomhole pe ko kọwe fi ipo silẹ nitori pe igba rẹ ko fẹ ṣe bi ẹni san ẹgbẹ oṣelu naa.
Ninu awọn to n pe ipe yii ni igbakeji Adams Oshiomohle gan funrarẹ fun iha ariwa, Sẹnetọ Lawan Shu'aib ati alaga ẹgbẹ naa to fi ipo silẹ.
Amọṣa awọn alaga ẹgbẹ oṣelu APC lẹkun aaringbungbun Gusu ti dide atilẹyin fun un.
Ki ni awọn ohun ti Adams Oshiomhole ṣe gan an to n fẹ bu u lẹsẹ bayii? Eyi ni atupalẹ diẹ nibẹ.
Abajade idibo ipinlẹ Zamfara

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kii ṣe wahala kekere ni ọrọ abẹnu to waye laarin agbo APC ni ipinlẹ Zamfara ati Rivers ko ba ẹgbẹ oṣelu naa.
Ọpọlọpọ lo reti ki alaga ẹgbẹ oṣelu APC naa o gbe igbesẹ lati tete yanju ọrọ naa ki o to burẹkẹ.
Ṣugbọn kaka ki Oshiomole ko awọn adari ẹgbẹ oṣelu naa sodi lati tete pa ina rẹ ki eefin rẹ to ru sita, idakeji rẹ lo waye.
Nitori dukuu wọnyii, ipinlẹ mejeeji yii ni APC padanu. Wọn ko tilẹ jẹ ko fa oludije kalẹ ni ipinlẹ Rivers lasiko idibo to kọja.
Ipinlẹ Zamfara ti wọn tun ti fa eeyan silẹ, lọsẹ to kọja ni ile ẹjọ to ga ju lorilẹ-ede Naijiria ti wọgile gbogbo awọn oludije to jẹ ti APC nipinlẹ naa.
Ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa ni ko ṣebi ẹni dunnu si bi awọn adari ẹgbẹ oṣelu naa ṣe mu ọrọ naa.
Ọpọ eekan ẹgbẹ lo fi ẹgbẹ silẹ.
Lootọ ọpọ le sọ pe ẹsẹ wọn ti wa ni ita ṣaaju ibọsipo Adams Oshiomole gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ oṣelu APC.
Sibẹ ọpọ ọmọ ẹgbẹ lo ṣi n wo o pe iye awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC lọdun 2018 si asiko eto idibo apapọ ọdun 2019 ku diẹ kaa to.
Lara awọn eekan to fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ ni aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnetọ Bukọla Saraki, ati olori ile aṣoju-ṣofin, Dogara, gomina Aminu Tambuwal atawọn eekan miran.
Wahala oun pẹlu awọn gomina tẹlẹ, Amosun tipinlẹ Ogun ati Rochas Okorocha

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kii ṣe iroyin pe titi ti wọn fi kuro ni ipo gomina ni ipinlẹ koowa wọn, ati Amosun pẹlu Rochas Okorocha, ko si eyi to fojuure wo Adams Oshiomole titi ti wọn fi kuro ni ipo.
Ohun to si fa aawọ aarin wọn ko ju bi alaga ẹgbẹ APC naa ṣe faake kọri pe oun ko ni fọwọ si eeyan ti wọn fa kalẹ gẹgẹ bi oludije awọn ipo oṣelu nibẹ lai yan ipo gomina silẹ.
Rochas Okorocha fa ọkọ ọmọ rẹ, Uche Nwosu siilẹ gẹgẹ bii gomina, Amosun ni tirẹ naa fa eeyan tirẹ silẹ ni ipinlẹ Ogun.
Ọpọ lo wo o pe bi APC ṣe kuna ni ipinlẹ Imo ko ṣẹyin eyii.
Pipadanu awọn ipinlẹ to jẹ ti APC ni 2015 fun PDP lọdun 2019

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ awọn alagbara ẹgbẹ oṣelu APC lo ṣi n fapa janu pe awọn iwa ati ọrọ Adams Oshiomole kun ara ohun to fa a ti ẹgbẹ oṣelu APC fi padanu awọn ipinlẹ bii, Zamfara, Imo Oyo ati Adamawa.
Ninu iwe to kọ, igbakeji alaga APC fun ẹkun ariwa Sẹnetọ Lawal Shu'aibu ni "ipinlẹ mẹtalelogun ni a ni lọdun 2015, ṣugbọn nigba to di ọdun 2019 a padanu meje".
"A tun ni ọgọta sẹnetọ lọdun 2015, nibayii mẹtadinlọgọta la ni. A ko gbe ọ wọle lati wa fidirẹmi ninu idibo, a ko lee gba eyii rara".
Bi eniyan ba tun wa wo awọn ẹsun ti Sẹnetọ Shu'aibu ka silẹ fun Oshiomhle ninu lẹta to kọ si i pe ko fi ipo silẹ gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ oṣelu naa, aigbọ ọrọ lẹnu awọn ọmọ ẹgbẹ jẹ awọn ẹsun ti wọn fi kan an.
Bakan naa, ibinu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, eto ati ilana ti awọn alaṣẹ naa n gba to eto ẹgbẹ oṣelu APC naa ko gbẹyin ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan Adams Oshiomole.
Nigba ti BBC News Yoruba kan si alukoro ẹgẹ oṣelu APC, Ọgbẹni Issa Onilu, o ni ẹgbẹ oṣelu APC yoo fi ero rẹ han lori ọrọ ọhun ni ọsan ọjọ aje.













