Cedar College, Lagos: Ilé ìwé wa kọ́ ni Favour kú sí

Oogun Oloro

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Oogun Oloro

Ariwo ẹkun sọ nile Favour Ekemedili to jẹ akẹkọ onipele ikẹta ni ile iwe girama Cedar College, Baruwa ni agbegbe Ipaja ipinlẹ Eko.

Nigba ti BBC Yoruba kan si ile iwe naa, ọga agba ile iwe to gbe ẹrọ ibanisọrọ kọ lati fọhun lori ọrọ naa ṣugbọn olukọ mii ti ko darukọ rẹ fidi rẹ mulẹ pe iṣẹlẹ naa ṣẹ ṣugbọn kii ṣe ile iwe awọn ni Favour ti dakẹ.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Àwọn ènìyàn sọ àwọn ewu tí wọn pàdé nínú lílo òògùn ẹ̀fọn

" Rara o, wọn gbe e lọ si ile iwosan mii lati ile iwe wa, lati ibẹ wọn si tun gbe e lọ si ile iwosan ti ijọba to wa ni LASU.

Gẹgẹ bi iroyin to kan BBC Yoruba lọwọ, inu kilaasi ni Favour ati awọn akẹgbẹ rẹ wa ti wọn n duro de ẹkọ to kan nigba to mu eso olomi kan to si mu u.

Lẹyin iṣẹju diẹ lo figbe inu rirun sẹnu ti wọn si gbe e digba digba lọ ile iwosan ti ile iwe naa nibi ti nọọsi ti sare bojuwo ki lo ṣẹlẹ gan si Favour.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Àwọn ènìyàn sọ àwọn ewu tí wọn pàdé nínú lílo òògùn ẹ̀fọn

Wọn yẹ ike eso olomi to mu wo, wọn si gboorun oogun apakokoro ninu rẹ. Eyi mu ki wọn tete gbe e kuro ni ile iwosan tiwọn si lọ si ile iwosan miiran ko to di pe Favour jade laye.

Ẹwẹ iroyin kan sọ wi pe nigba ti wọn kan si iya ọmọ naa, o ru ẹbi iku ọmọ rẹ le ile iwe pe wọn ko mojuto ọmọ oun to wa ni iṣakoso ni.

"Mi o le yi ohun to ti ṣẹlẹ pada. Ọmọ mi kuro nile lọ si ile iwe, nigba to wa ni kilaasi, ṣe wọn moju to o? Ṣugbọn mo fi ohun gbogbo le Ọlọrun lọwọ" ni iya Favour sọ.

Àkọlé fídíò, 'Mo ń ṣa ike jọ láti san owó ilé iwé ọmọ mẹ́ta'

Iroyin naa ti de agọ Ọlọpaa to wa ni Ipaja lati ile iwe Cedar College, Baruwa.

Nibayii, wọn ti mu ike omi eso to mu ti wọn ni o n run oogun apakokoro lọ si yara ayẹwo ti wọn si n ṣe iṣẹ lori rẹ.