Ramadan: Sultan pàṣẹ fún àwọn mùsùlùmí láti ṣ'ọdẹ òṣùpá lónìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Sultan ti ilu Sokoto, Alhaji Muhammad Saád Abubakar ti ni ki awọn musulumi lorilẹede Naijiria bẹrẹ si ni ṣọ oṣupa tuntun.
O ni ki wọn maa ṣọ ọ fun oṣu Shawwal 1440AH ni kete ti oorun ba wọ lọjọ Aje, ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, ọdun 2019.
Aṣẹ yii wa lati lee mọ ọjọ ti awẹ yoo pari ti awọn Musulumi yoo ṣi tunu.
Ninu atẹjade kan eleyi ti ajọ to ga julọ fun ẹsin Islam lorilẹ-ede Naijiria, NSCIA fi sita ni wọn ti sọ eyi.
Igbakeji akọwe agba ajọ naa, Ọjọgbọn Salisu Shehu lo fọwọsi atẹjade naa.
Sultan Abubakar ni bi awọn eeyan ba ri oṣupa ni ọjọ Aje, oun yoo kede ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrin, oṣu kẹfa, ọdun 2019 gẹgẹ bii ọjọ akọkọ ninu oṣu Shawwal ti yoo si jẹ ọjọ ọdun 'Eidel fitr' iyẹn, itunu awẹ.
Atẹjade naa tun tẹsiwaju, o ni bi o ba si jẹ pe oṣupa ko le ni ọjọ aje, a jẹ wi pe, ọjọru, ọjọ karun oṣu kẹfa ni ọdun itunu awẹ fawọn Musulumi yoo bọ si.











