Ramadan: Àwọn mùsùlùmí tí kò bẹ̀rẹ̀ àwẹ̀ títí d'ìgbà tí wọ́n tó fojú r'óṣù

Aworan Sultan Sokoto

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Olori Musulumi ni Naijiria ni o ma n saba paṣẹ bibẹrẹ awẹ Ramdan ni Naijiria

Ninu oṣu Ramadan ọdun yi,gẹgẹ bi iṣe rẹ Sultan Sokoto kede pe ki awọn musulumi bẹrẹ awẹ lọjọ Aje lẹyin ti wọn ri oṣu lawọn ilu kọọkan.

Amọ bi awẹ naa ti ṣe di meji lọjọ iṣẹgun, niṣe ni awọn musulumi kan n sọ pe awẹ ti awọn ṣẹṣẹ di ẹyọkan ni.

Nibo ni wọn wa ati pe ki lo mu wọn faake kọri toun ti aṣẹ olori Musulumi ?

Akọroyin BBC,Mansur Abubakar jabọ lati ilu Kano nibi ti o ti ba awọn musulumi ti wọn kii bẹrẹ awe bi wọn ko ba foju ri oṣu fun ara wọn.

Ẹ gbọ awijare wọn lori igbesẹ wọn yi i.

Jamilu Shehe ni tirẹ salaye pe lati igba toun ti wa ni kekere ni ohun kii bẹrẹ awẹ ayafi ti ohun ba foju ri oṣu.

Ramadan
Àkọlé àwòrán, Jamilu Shehe

"Kii ṣe wi pe mo ṣarifin si Sultanamọ lati kekere ,bi mi o ba foju ri oṣu emi kii gba awe.Bẹẹ naa si ni ọrọ ri ni ipari awẹ.''

Ni soki, ohun ti Jamilu n sọ pe bi ohun ko ba foju ri oṣu,ohun kii dawọ awẹ gbigba duro.

Ramadan
Àkọlé àwòrán, Yusha'u Abdulhamid

Iriwisi ti Yusha'u Abdulhamid tun fẹ lagbara diẹ

O ni idi ti ohun kii ba awọn Musulumi to ku gba awẹ ni pe ''ohun ti ọkan oun ba sọ nikan loun ma n tẹle''

''Oṣu Ramadan to ba yọ,awa musulumi ta wa ni Kano gbọdọ ri,bẹẹ lo si yẹ ko ri fawọn ti ipinl mii.Mo pe awọn rẹ mi ni Yobe ati Maiduguri wọn si pe an ko tifoju ri oṣu''

''Emi o ṣarifin Sultan amọ ilana ti mo n lo lati gbawe leleyi ti awọn obi mi ati olukọ mi fi mọ mi''

Ramadan
Àkọlé àwòrán, Sani Musa

Sani Musa naa wa lara awọn ti kii bẹrẹ awẹ lai foju r'oṣu.

Ohun ti igbesẹ Sani,Yushau,Jamilu ati awọn miiran bi ti wọn n ṣe ni pe lọjọ ti awọn musulumi yoku ba n dawọ idunu itunu awẹ awọn ko ni ti dawọ awẹ gbigba duro.

Ni nnkan bi ọjọ kan tabi meji lyin ti gbogbo janmọ yoku ba pari awẹ lawọn yoo ṣọdun tiwọn.

Ọna wo ni wọn n gba ri oṣu?

Aworan ẹni to n wa oṣu

Oríṣun àwòrán, Anadolu Agency

Àkọlé àwòrán, Awọn irinse bayi ni wọn ma fi n wa oṣu

Ni Naijiria ati ni awọn orileede miran ti musulumi wa to fi d'ori Saudi, awọn olori musulumi a ma gbe eto oṣu wiwa le awọn igbimọ kan lọwọ.

Awọn igbimọ yi ni yoo wa jabọ fawọn olri nipa ibi ti wọn ba ti ri oṣu tuntun.

Ki eeyan to le foju ri oṣu yi nigba ti o ba jade,awọn ọmọ igbimọ a ma lo irinṣẹ igbalode lati mọ ni pato pe oṣu naa jade.

Oṣu riri ṣe pataki nitori ohun ni yoo ṣe atọna igba ti awẹ yoo bẹrẹ ati igba ti yoo pari.

Ninu sin Islam, wọn a ma fi yiyọ oṣu tuntun mọ igba ti awọn ọdun pataki bi ọdun awẹ ati ileya yoo waye.

Ọjọ mọkandinlọgbọn abi ọgbọn ni wn fi n ka ọjọ osupa.Ti wn ko ba ri oṣu lọjọ kọkandinlọgbọn, a jẹ wi pe ọgbọn ọjọ ni oṣu naa de.Fun idi eyi,awẹ yoo bẹrẹ lọjọ kini oṣu tuntun.

Onimọ ẹsin Islam kan,Sheikh Garangamawa to ba BBC sọrọ ṣalaye pe kii ṣe awọn ọmọ igbimọ to n wa oṣu nikan lo le wa oṣu bi kii ṣe pe iwọ gbogbo musulumi ni.

Ninu ọrọ ti rẹ, Imaamu agba mọsalaṣi Kano,Abdullahi Idris ni awọn to n duro de ki wọn ri oṣu fun ara wọn ko ṣe ohun to tọ.

O ni ''Awẹ ti Ọlọrun mọ, ti yoo si tẹwọgba ni eleyi ti gbogbo eeyan jijọ gba ni ilana pẹlu aṣẹ olri wọn.Awọn to yapa lori rọ yi ko ni awijare tofẹsẹ mulẹ. nitori pe wọn ko ni agbọye ẹsin daada.''

''Nitori eleyi,wọn gbọdọ gba awẹ kafara lati fi wa itanran ohun ti wọn ṣe. Koda bi o ba ṣe asikọ Umar Ibn Khattab to jẹ saabe agba ni wọn wu iru iwa yi, afaimọ ki wọn ma da sẹria ẹgba fun wọn''