Ramadan Fast: wo àwọn orílẹ̀èdè tí wákàtí ààwẹ̀ wọn gùn ju ti Nàìjíríà lọ àti àwọn èèwọ̀ oúnjẹ lásìkò ààwẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ramadan ti bẹrẹ ni pẹrẹu, bi ààwẹ̀ gbigba ṣe pọn dandan bẹẹ naa ni awọn ounjẹ ti ẹnikẹni to ba n gbawẹ nilo akiyesi.
Onimọ̀ nipa ounjẹ jijẹ, Oyedeji oluwatobi jẹ ko di mimọ wi pe nigbakuugba ti eeyan ba n gba awẹ, awọn irinṣẹ ara yoo ti paju de to ba maa fi to akoko iṣinu.
Oluwatobi ni ko boju mu lati maa lo ohun to lee pa ara lati fi ṣinu dipo awọn eroja to lee bẹrẹ si ni ṣi awọn irinṣẹ ara naa pada eyi to ti pa oju de.
" A ni lati fun un ni nkan ti yoo maa jẹ ko ṣi diẹ diẹ to jẹ wi pe a tun ṣe awọn eroja ara lokun pada titi ara yoo ṣe le gba awọn". O ni kii ṣe bi awọn okele nla nla ti a da bii okuta".
Nkan bii ounjẹ to lomi dara lati kọkọ fi ṣinu lati le pese inu silẹ fun ounjẹ miiran. Lẹ́yìn eleyii gan, o ṣi yẹ ki wọn mu nkan bii miliiki ki wọn to wa jẹ iru ounjẹ ti wọn maa n jẹ tẹlẹ.
To ba ṣe eso, yoo jẹ ki ounjẹ wu eniyan jẹ kìí ṣe ti ka sare kọ ounjẹgelete siwaju ki a wa pa taarọ, ọsan ati talẹ pọ lẹẹkan.
Onimọ nipa ounjẹ tun tẹnu mọọ pe kii ṣe awn eso ti wn ti da kẹmika pọ mọ lo yẹ bi ko ṣe eyi to ṣẹ wa lati oko.
Fun awọn to ni aisan ọgb inu, Oluwatobi ni awọn eso to ni oro ninu ko dara fun wọn lati fi ṣinu tori naa, o yẹ ki wọn ri onimọ nipa ounjẹ ti yoo ya atẹ ounjẹ fun wọn ki wọn to maa yan ounjẹ ti wọn yoo fi ṣinu ati iye akoko to yẹ ki wọn fi gbawẹ.
Ma ṣe jẹ
Onimọ nipa ounjẹ Oluwatobi kilọ pe ki ẹni to ba n gbawẹ ṣọra fun ounjẹ lile gẹgẹ bi ohun akọkọ lati fi ṣinu aawẹ.
Bakan naa, o ṣe apẹrẹ awọn nkan dindin gẹgẹ bi ohun ti ko yẹ keeyan kọkọ fi ṣinu.
Ohun ti o le jẹ
- Eso olomi
- Ogi agbado
- Ewebẹ
- Anọmọ
- Iṣu to rọ ati bẹẹ bẹẹ lọ ṣaaju ounjẹ to le.













